Ọṣun 2018: Ibo gomina ku si dẹdẹ Ajọ INEC lawọn ti ṣetan PDP n dira ogun Ṣugbọn ọrọ ko ti i loju ninu ẹgbẹ oṣelu APC

Spread the love

Pẹlu bo ṣe ku ọjọ marunlelogoje bayii ti eto idibo gomina yoo waye nipinlẹ Ọṣun, ajọ eleto idibo lorileeede yii, INEC, ti sọ pe digbi lawọn wa fun idibo naa, ati pe ohun gbogbo to yẹ kawọn ṣe nimurasilẹ lo ti n lọ lẹsẹẹsẹ.
Bakan naa niwadii fi han ninu ẹgbẹ oṣelu PDP pe lẹyin wahala to mi ẹgbẹ naa logbologbo nipinlẹ Ọṣun, o le ni oludije mẹẹẹdogun ti wọn ti lọọ fi ifẹ han fun ẹgbẹ naa pe awọn yoo dupo gomina, ti gbogbo wọn si n leri pe awọn yoo ṣi Arẹgbẹṣọla ati ẹgbẹ oṣelu APC nidii patapata l’Ọṣun.
Bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu Gomina Rauf Arẹgbẹṣọla pẹlu awọn adari ẹgbẹ APC l’Ọṣun ko ti i mọ odo ti wọn yoo da ọrunla si latari ahesọ to n lọ lọwọ pe wọn ti gba ‘aṣẹ’ latilu Eko pe olori awọn osiṣẹ lọfiisi gomina, Alhaji Gboyega Oyetọla, ni ki wọn ṣa gbogbo ipa lati ri i pe o bọ sipo naa lẹyin Arẹgbẹṣọla.
Bẹẹ lawọn ẹgbẹ oṣelu to ku bii Accord Party, Social Democractic Party, Restoration Party, Kowa Party, National Conscience Party, Alliance for Democracy, Labour Party ati bẹẹ bẹẹ lọ naa n sọ pe awọn yoo ba Arẹgbẹṣọla mu nnkan nilẹ lọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ti idibo naa yoo waye.
Nibi ipade kan ti kọmisanna ajọ INEC nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Oluṣẹgun Agbaje, ba awọn oniroyin ṣe lọsẹ to kọja lo ti ni awọn ẹgbẹ oṣelu to ba fẹẹ kopa ninu eto idibo gomina naa le bẹrẹ ipolongo lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa, ọdun yii, nigba ti ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu kẹfa wa fun gbigba fọọmu lolu ileeṣẹ ajọ INEC niluu Abuja.
Agbaje ni laarin ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa, si ọjọ kẹtalelogun, oṣu keje, lawọn ẹgbẹ oṣelu lanfaani lati ṣeto idibo abẹle wọn, nigba ti ajọ INEC yoo gbe orukọ awọn oludije jade lọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii.
Ogunjọ, oṣu kẹṣan-an ni ipolongo ibo yoo wa sopin, idibo yoo si waye lọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.
O fi kun ọrọ rẹ pe miliọnu kan o le ẹgbẹrun lọna irinwo eeyan ni wọn forukọsilẹ fun idibo l’Ọṣun, ṣugbọn miliọnu kan o din diẹ lo ti gba kaadi idibo alalopẹ wọn, nigba ti eeyan to le ni irinwo ko ti i gba tiwọn kaakiri ijọba ibilẹ ọgbọn to wa nipinlẹ Ọṣun gẹgẹ bii akọsilẹ ajọ INEC.
Amọ ṣa, lara ọrọ to n lọ kaakiri ni pe iha Iwọ-Oorun Ọṣun lo yẹ ki gomina ti yoo gbapo lọwọ Arẹgbẹṣọla ti wa, lai fi ti ẹgbẹ oṣelu to wa ṣe. Wọn ni ọdun meje ataabọ ni Gomina Adebisi Akande ati Gomina Oyinlọla ti wọn wa lati Aarin-Gbungbun Ọṣun lo, nigba ti Gomina Arẹgbẹṣọla to wa lati ẹkun iha Ila-Oorun Ọṣun ti fẹẹ lo ọdun mẹjọ rẹ pe bayii.
Oṣu mejilelogun pere ni Oloogbe Sẹnẹtọ Isiaka Adetunji Adeleke to wa lati ẹkun Iwọ-Oorun Ọṣun lanfaani lati lo tawọn ologun fi gbajọba nigba naa. Idi niyi to fi da bii ẹni pe iha Iwọ-Oorun Ọṣun lọpọlọpọ ẹgbẹ oṣelu n foju si bayii lati mu oludije wọn.
Bi ẹgbẹ oṣelu PDP l’Ọṣun ṣe n pariwo pe o di dandan kawọn gba ile ijọba to wa l’Oke-Fia lọwọ Arẹgbẹṣọla naa lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC n leri pe atari ajanaku ni ọrọ idibo to n bọ naa, ko sẹni to le tẹri si i, o si di dandan kawọn wọle pada.

Lara awọn ti wọn ti fifẹ han ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lati dije fun ipo gomina ni akọwe agba fun ijọba ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Alhaji Fatai Akinbade, Oluọmọ Gbenga Owolabi, Akọgun Lere Oyewumi, Amofin Nathaniel Ọkẹ, Enjinia Jide Adeniji, Ọnọrebu Adejare Bello, Sẹnẹtọ Felix Ogunwale, Ọnọrebu Albert Adeogun, Sẹnẹtọ Ọlasunkanmi Akinlabi, Ọgbẹni Ọlawale Rasheed.
Bakan naa ni Sẹnẹtọ Ademọla Adeleke to n ṣoju awọn eeyan ilu ẹkun Iwọ-Oorun Ọṣun, to tun jẹ aburo Oloogbe Sẹnẹtọ Isiaka Adetunji Adeleke naa ni lẹyin toun pẹlu idile oun gbaawẹ ati adura ologoji ọjọ ni Ọlọrun dari oun lati gba awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lọwọo laluri oniruuru tijọba Arẹgbẹṣọla ti ko wọn si.
Amofin Kayọde Oduoye lo da bii ẹni pe o kere ju ninu awọn ti wọn jade ninu ẹgbẹ PDP, ohun ti ọkọ ọkan ninu awọn oṣere tiata ilẹ wa, Mosun Filani, si n tẹnumọ ni pe ko bojumu bi ọmọ alaṣọ ṣe n wọ akisa nipinlẹ Ọṣun, o ni gbogbo gbese tijọba Arẹgbẹṣọla kọrun bọ loun yoo wadii, bẹẹ loun yoo gbe igbesẹ to tọ lori gbogbo rẹ.
Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun, Ọnọrebu Sọji Adagunodo, ni tiẹ rọ komisanna ajọ INEC lati ma ṣe faaye gba ẹnikẹni, bo ti wu ko lagbara to, lati lo o tako ifẹ awọn araalu, nitori pe asiko to lewu, to si ṣe pataki julọ ninu itan ipinlẹ Ọṣun ni wọn gbe e wa yii.
Ni ti ẹgbẹ oṣelu APC, ireti ọpọlọpọ eeyan, paapa awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ni pe awọn alaṣẹ ẹgbẹ yoo ti ṣilẹkun fun ẹnikẹni to ba nifẹẹ lati dupo gomina ninu ẹgbẹ naa, ti ohun gbogbo yoo si ti bẹrẹ si i lọ bo ṣe yẹ, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe ko si nnkan to jọ ọ.
Ahesọ to n lọ kaakiri ni pe ṣe ni Gomina Arẹgbẹṣọla atawon alaṣẹ ẹgbẹ labẹ alaga wọn, Ọmọọba Gboyega Famọọdun, mọ-ọn-mọ mu awọn oludije yii lọwọ silẹ nitori pe ipolongo ti n lọ labẹnu fun ẹni to da bii ayanfẹ Aṣiwaju Bọla Tinubu l’Ọṣun, iyen Alhaji Gboyega Oyetọla, ti ọrọ ipolongo rẹ n jẹ Ileri Oluwa.
ALAROYE gbọ pe ọmọ ẹgbọn Aṣiwaju Tinubu lobinrin ni Alhaji Gboyega to wa lati ilu Iragbiji, bẹẹ ni iwa ati iṣe Arẹgbẹṣọla n farajọ pe oloṣelu to fi ọpọlọpọ ọdun ba Aṣiwaju Tinubu ṣakoso awọn ileeṣẹ rẹ l’Ekoo yii ni wọn fẹẹ lo, ṣugbọn o da bii ẹni pe ọrọ naa le lati sọ sita.
Ohun to fa wahala ni pe iha Aarin-Gbungbun Ọṣun ni Oyetọla ti wa, bẹẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn wa l’Ọṣun n fapa janu pe awọn ara Eko ni wọn janfaani iṣejọba Arẹgbẹṣọla lọdun mẹjẹẹjọ to lo, awọn ko si ṣetan lati tun ṣe ẹru awọn ara Eko mọ, wọn ni Tinubu ko tun gbọdọ yan le awọn lọwọ mọ bo ṣe ṣe fawọn lasiko Arẹgbẹṣọla.
Yatọ si eyi, gbogbo awọn agbaagba ẹgbẹ l’Ọṣun, to fi mọ awọn ori-ade lati iha Iwọ-Oorun Ọṣun ni wọn n sọ pe lai ni i si iyanjẹ tabi ede-aiyede, ẹkun Iwọ-Oorun lo yẹ ki gomina ti yoo gbapo lọwọ Arẹgbẹṣọla ti wa.
Lara awọn to ṣee ṣe ki wọn tun jade dupo latinu ẹgbẹ oṣelu APC ni akọwe agba fun ijọba ipinlẹ Ọṣun lọwọlọwọ bayii, Alhaji Moshood Adeoti, igbakeji abẹnugan ileegbimọ aṣofin apapọ orileede yii, Ọnọrebu Lasun Yussuff, alaga ajọ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ, Alagba Peter Adebayọ Babalọla, abẹnugan ileegbimọ aṣofin Ọṣun, Ọnọrebu Najeem Salam, Alhaji Adelere Oriolowo, Alhaji Ọlabamiji, Ọnọrebu Babatunde Taiwo, Amofin Kunle Adegoke, Oluọmọ Sunday Akere, kọmisanna feto iṣuna, Bọla Oyebamiji ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Obinrin ni oludije ti ẹgbẹ oṣelu Restoration Party gbe silẹ ni tiwọn, Mercy Ayodele ni wọn pe e, oun naa si fi da awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun loju pe gbogbo omije ti iṣejọba ẹgbẹ oṣelu APC ti fi soju wọn loun ṣetan lati nu kuro ti wọn ba le fi ibo wọn gbe oun wọle. Obinrin yii ni oun nigbagbọ pe asiko ti to fun obinrin lati di ipo gomina mu l’Ọṣun, o ni ẹlẹyinju aanu lobinrin, iyatọ si maa n ba iṣejọba ti wọn ba dari.
Bi ọpọlọpọ ṣe gbagbọ pe o ṣee ṣe ko jẹ ẹgbẹ oṣelu SDP ni Ọtunba Iyiọla Omiṣore n lọ leyin toun atawọn ọmọlẹyin rẹ binu kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ko ti i si arigbamu iroyin kankan to fidi eleyii mulẹ, bi awọn alatilẹyin rẹ bii Sunday Ojo Williams ati Falade ṣe n sọ pe awọn ko ti i ni ẹgbẹ kankan lọkan ni pato ni Omiṣore naa n sọ pe oun yoo sọ ẹgbẹ toun n lọ nigba ti asiko ba to.
Ju gbogbo rẹ lọ, igbagbọ awọn onwoye oṣelu l’Ọṣun bayii ni pe nigba ti yoo ba fi di iwoyi oṣu to n bọ, imọlẹ aa ti bẹrẹ si i tan sibi ti igi oṣelu yoo wo si nipinlẹ naa.

(121)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.