Nnkan kan ko gbọdọ ṣe Lemọmu Yoruba ilu Ilọrin o

Spread the love

Ki gbogbo awọn ọlọpaa, ati awọn oloṣelu, ati awọn ọmọ oye ilu Ilọrin ti wọn n wa ẹmi Lemọmu Yoruba ilu naa, Sheikh Abdul-Raheem Aduranigba, kiri ṣe mẹdọ, ki wọn sinmi ara wọn jẹẹ, ki wọn ma fa wahala ti ko ni i tan sọrun ara wọn. O ti pẹ ti Shehu yii ti n pariwo, bẹẹ lo n ba wọn fa a, ko si sohun meji to n bi wọn ninu ju pe ko gba pe Fulani nikan ni yoo maa jẹ ọba ilu Ilọrin. Bi ko ba jẹ ole n pa awọn naa ku, ṣebi wọn fẹtan ati jamba gba ilu lọwọ awọn ọmọ oniluu ni. Ka tilẹ waa sọ pe iyẹn ti pẹ, o ti lọ, gbogbo Ilọrin si ti di ọkan naa, ko sohun to le mu iṣọkan wa niluu naa ju ki ati Yoruba ati Fulani maa jẹ ọba ibẹ lọ. Bi Fulani ba jẹ tan, ki Yoruba naa tun jẹ. Ọjọ ti wọn ba ti ṣe bẹẹ ni alaafia ti o ni i tan laye yoo wọ ilu naa wa. Ṣugbọn gbogbo eyi ti wọn n ṣe, lati maa fi agidi, ọlọpaa ati awọn ṣọja halẹ mọ ẹni yoowu to ba ti sọ pe Yoruba loun, tabi pe oun ni aṣaaju Yoruba nibẹ kiri ko le ṣiṣẹ, lọjọ kan, gbogbo rẹ yoo fọ loju, ẹni ti ko ra paapaa yoo si san. Bi wọn ṣe ṣe bii ere bii ere ti wọn pa Lawal niyẹn, ti wọn pa Adisa naa danu, gbogbo ẹni to ba ti fẹẹ jẹ aṣaaju Yoruba ni wọn n fọna ọrun han, nitori pe wọn ni Fulani lo n’Ilọrin, wọn si mọ pe ki i ṣe bẹẹ, irọ ni wọn n pa funra awọn. Fulani ati Yoruba lo ni ilu Ilọrin, awọn naa si mọ. Bi wọn ba mọ, ti wọn si gba bẹẹ, kin ni wọn n sọ pe Yoruba ko ni i deeyan nla n’Ilọrin si. Kin ni wọn n sọ pe Yoruba ko ni i jọba ilu Ilọrin si? Bi apa awọn ti wọn wa nibẹ loni-in ko ba ka a, awọn mi-in n bọ lọla ti yoo beere, iru ẹ naa lo si n ṣẹlẹ yii o. Wọn ni Lemọmu Yoruba sọrọ sinu fidio pe ki ọmọ Yoruba tootọ pa orukọ ajoji ti ki wọn maa jẹ orukọ ilẹ baba wọn. Ki waa lo buru ninu iyẹn. Nigba ti awọn ọmọọba Ilọrin ti wọn n jẹ orukọ Yoruba tẹlẹ pa a ti nitori wọn ko fẹ ki wọn mọ pe Yoruba lawọn, ta lo mu wọn si i, tabi bakan naa kọ ni Kọlapọ Gambari ṣe yọ Kọlapọ kuro ninu orukọ tirẹ, to jẹ Ibrahim nikan la n gbọ. Ta lo si mu un si i nigba to ṣe bẹẹ. Ki waa lawọn ọlọpaa n tori eleyii le Lemọmu Yoruba Ilọrin kiri si. Kinni kan ko gbọdọ ṣe e o, bi ẹ ko ba fẹ wahala to ju wahala lọ, kinni kan ko gbọdọ ṣe e. Aye ijọsi ti yatọ gan-an si tasiko yii, bi eeyan ba dan palapala wo, ohun ti oju oun naa yoo ri ko ni i le sọ. Ẹ fi Lemọmu Yoruba Ilọrin silẹ, ko de ọdọ yin o.

(50)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.