Njẹ o mọ pe iṣẹju mẹrin pere lo ku fun ọ laye bó ò ba fi le mí mọ

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami ▶️ to wa nisalẹ yii.

Ọkan pataki ninu awọn ọna ti wọn fi n mọ alaaye yatọ si oku ni mímí wọn. Ohun to ba fi le mu ẹda yoowu, yala ẹranko ni tabi eniyan, ma le mi mọ, onitọhun ti kuro nipo alaaye niyẹn.

Amọ gbogbo wọn naa kọ ni wọn ti kuro nipo alaaye bẹẹ, awọn mi-in wa lagbedemeji boya yoo ku tabi yoo ye ti wọn o si ni i le mí rara. Ṣugbọn bayoowu ko ri, ohun to ba fi mu eeyan ma le mí fun iṣẹju mẹrin, iwadii awọn onimọ ijinlẹ fidi ẹ mulẹ pe ko si ohun to le gba onitọhun silẹ lọwọ iku.

Oriṣiiriṣii nnkan lo le fa iṣoro ailemi mọ yii. O ṣee ṣe ko jẹ arun lati inu ara, tabi ko jẹ pe nnkan kan di ẹnu ọna atẹgun onitọhun lati ita.

Lara awọn nnkan to le di eemi lati ita ni bi eeyan ba ko somi ti omi naa si di i nimu atẹnu. Ahọn tabi kẹlẹbẹ le di ẹlomi-in lọna ọfun, ounjẹ tabi eefin to lagbara si le ṣakoba fun ile eemi eniyan ti onitọhun ko ni i le fa eemi simu daadaa.

Awọn arun to le fa keeyan ma le mi mọ pọ jaburata, ṣugbọn eyi to gbajumọ ti ọpọ eeyan mọ ni ikọ Asthma, arun inu ọkan tabi bi ọkan funra ẹ ba daṣẹ silẹ, arun jẹjẹrẹ ọna ọfun ti wọn n pe ni Lung Cancer, ikọọfe tawọn oloyinbo n pe ni Whooping Cough, ati bẹẹ bẹẹ lọ. 

Eyi to gbajumọ lọwọ yii ni arun Coronavirus tabi COVID-19 to le lọọ da iṣoro si awọn apo atẹgun to wa ninu kindinrin, bi eyi ba si ti ṣẹlẹ, yoo ṣoro gidigidi tabi ko ma tilẹ ṣee ṣe rara fun onitọhun lati fa atẹgun sinu ara.

To ba jẹ awọn arun atinu wa yii lo fa ki eeyan ma le mi, o ṣe pataki ki ẹ tete ranṣẹ si oṣiṣẹ eleto ilera to ba wa nitosi lati mojuto onitọhun tori lasiko naa gẹgẹ bi a ṣe wi, ko ni ju iṣẹju mẹrin lọ laye mọ o. Ṣugbọn bo ba jẹ pe onitọhun ko somi ni tabi nnkan kan lo di i lọna ọfun ti ko fi le mi mọ. Ẹ da a dubulẹ, ẹ ki ika ọwọ yin bọ ara wọn ki ẹ si bẹrẹ si i tẹ ẹ nigba aya. Eyi yoo ti ohun yoowu to ba n di ile atẹgun rẹ sita.

Ẹ ki ika yin bọnu ara wọn bayii

Bi o ba jẹ ahọn tabi nnkan kan lo ha onitọhun lọna ọfun ti ko fi le mi mọ, o ṣe pataki lati kọkọ yọ nnkan naa kuro loju ile atẹgun onitọhun, bi o ba ṣee yọ, ki a too bẹrẹ si i tẹ ẹ nigbaaya bi a ti ṣalaye yii.

Eyi to waa ṣe pataki julọ ni pe bi ẹ ba ṣe n tẹ ẹ nigbaaya yii ni ki ẹ maa fi ẹnu mi si i lẹnu. Ẹ ri i daju pe ẹ di imu rẹ ki ẹ too bẹrẹ eyi. Bi ẹ ṣe n mi si i lẹnu ni yoo rọpo bi o ṣe gbọdọ maa mi atẹgun sinu laarin iṣẹju mẹrin ko ma baa ṣaisi.

Fifi ẹnu mí si ẹni ti o le mí lẹnu

Ju gbogbo rẹ lọ, bi ẹ ba ṣe n ṣe awọn eto yii ni ki ẹ ti tete ranṣẹ si eleto ilera to ba wa nitosi lati fun un ni amojuto to peye pẹlu iriri tirẹ, eyi ti ẹ ba ṣe yii ni yoo gba ẹmi onitọhun la ko too di pe eleto ilera de.

Iṣoro ailemi a maa buru pupọ nigba mi-in to jẹ pe awọn eleto ilera oo ni lati maa fi awọn ẹrọ igbalode fa atẹgun si eniyan lọna ọfun nigba ti ò ba le da mi funra rẹ. Iṣoro ailemi ki i ṣe ohun ti eeyan le fi oju tẹmbẹlu wo o, bi ẹ ba ti ṣakiesi pe ẹni kan ko ribi mi daadaa ni ki ẹ ti tete ṣamojuto to yẹ fun un, ki ẹ si ranṣẹ si eleto ilera lati gba a silẹ tori iṣẹju perete bayii lo ku fun onitọhun laye bi awọn ọrẹ ati ojulumọ ko ba tete sare si i.

A o ni i ṣaarẹ o.

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.