Nitori wahala to sele nibi ipade IEDPU ni Kwara, won ni ki aare won fipo sile

Spread the love

Nitori wahala to ṣẹlẹ nibi ipade awọn ọmọ bibi ilu Ilọrin, ‘Ilọrin Emirate Descendant Progressive Union’, (IEDPU),  lọsẹ to kọja, wọn ti ni ki aarẹ ẹgbẹ ọhun, Sheikh-Usman AbdulAzeez, kọwe fipo rẹ silẹ.

Lọsẹ to kọja ni ipade naa waye l’Ọjọruu,Wẹsidee, niluu Afọn, ṣugbọn niṣe lawọn ọmọ ẹgbẹ APC ati PDP sọ kinni ọhun di  oṣelu, ti wọn si bẹrẹ si i ho lera wọn lori.

ALAROYE gbọ pe awọn janduku kan ti wọn fura si pe wọn n ṣiṣẹ fun PDP ati Bukọla Saraki lo sokunfa bi kinni naa ṣe daru. Akọroyin wa gbọ pe nibi ti kinni naa le de, niṣe wọn kan an nipa fun aarẹ IEPDU, Sheikh-Usman AbdulAzeez, lati kọwe fipo rẹ silẹ, ti wọn si fi Alhaji Yahaya Ahmed rọpo rẹ gẹgẹ bii adele.

Ṣe ni wọn ho le oludije gomina ẹgbẹ All Progressives Congress, (APC), Alhaji Abdulrahman Abdulrazaq, lori  nigba ti wọn pe e ko waa sọrọ. Oludije naa ni wọn fiwe pe lati ṣefilọlẹ kalẹnda ọdun 2019 tẹgbẹ IEDPU gbe jade.

Ṣe lati bii ọsẹ meloo kan sẹyin ni akori ipolongo Abdulrahman, “O to gẹẹ!” ti n da awuyewuye silẹ. Eyi lo mu kawọn janduku ọhun maa wa gbogbo ọna lati soko ọrọ si ọkunrin naa.

Lasiko ti wọn pe oludije ọhun lati kede iye to maa gbe kalẹ lati ṣatilẹyin fun ẹgbẹ naa, iyalẹnu lo jẹ fawọn ọmọ ẹgbẹ PDP pe wọn le gba iru eeyan bẹẹ lalejo niru ipade yii.

Afi bii igba to jẹ pe oun gan-an ni wọn n duro de ni. Bi wọn ṣe bẹrẹ si i ho le e lori niyẹn, bẹẹ lawọn ti Abdulrahman naa n da wọn lọhun, ti wọn n sọ pe “O to gẹẹ, o to gẹẹ! oju wa ti la ni Kwara, ẹnikan ko le maa fi burẹdi ko wa lomi-ọbẹ jẹ mọ”, bi gbogbo agbo naa ṣe daru niyẹn.

Ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu PDP ti ni oludije APC lo da ipade naa ru, ki i ṣe Saraki tabi awọn ọmọ ẹgbẹ awọn bi wọn ṣe n gbe e kiri.

Ẹgbẹ PDP tako iṣẹlẹ naa, wọn ni ohun itiju gbaa ni. Wọn nipade naa ti n lọ wọọrọwọ ko too di pe Abdulrahman atawọn eeyan rẹ  gbiyanju lati sọ ọ di agbo ipolongo ibo.

Ọgbẹni Tunde Ashaolu to jẹ alukoro PDP ṣalaye pe nigba ti wọn pe ọkunrin naa lati waa sọ iye to maa gbe kalẹ lawọn alatilẹyin APC bẹrẹ si i pariwo “O to gẹẹ”, eyi ni wọn lo bi awọn eeyan to wa nibẹ ninu.

 

 

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.