Nitori wahala awọn ajinigbe, ẹgbẹ ajijagbara Yoruba fimọ ṣọkan lati koju wọn

Spread the love

Ọgọọrọ awọn ẹgbẹ ajijagbara Yoruba ni wọn ti fimọ ṣọkan lati koju awọn Fulani to n fojoojumọ ji awọn eeyan gbe kaakiri ipinlẹ Ondo.

 

Olori awọn ajijagbara ọhun, Ọgbẹni Adegboyega Victor, ẹni tawọn eeyan mọ si Arigidi, fidi ẹ mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita pe awọn ẹgbẹ bii mọkanla ni wọn ti ko ara wọn jọ pọ lati wa ọna abayọ sọrọ awọn ajinigbe naa.

 

Awọn ẹgbẹ bii, Agbẹkọya, Awọn ọdẹ ibilẹ, Fijilante, ẹgbẹ ọmọ Yoruba, OPC atawọn mi-in lo ni wọn ti ṣetan lati di ọkan ṣoṣo nitori ọrọ awọn oniṣẹẹbi ọhun.

 

Ọkan-o-jọkan iwa ijinigbe, ipaniyan, idigunjale, atawọn iwa ọdaran gbogbo to n waye kaakiri ipinlẹ Ondo lasiko ta a wa yii lo juwe bii eyi to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ naa ninu jẹ, to si tun n da ibẹru nla sọkan awọn eeyan.

 

Gbogbo ẹgbẹ ajijagbara to wa nipinlẹ naa lo ni wọn ti gbagbe ede-ai-yede ati iyapa to wa laarin wọn, ti wọn si ti pinnu lati ṣiṣẹ pọ doju kọ awọn ipenija eto aabo tawọn eeyan n foju wina rẹ lọwọ.

 

Arigidi beere fun iranlọwọ ati atilẹyin ijọba ipinlẹ Ondo, ki erongba ati ipinnu awọn lati pese aabo fawọn araalu le seso rere.

 

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.