Nitori ti ọkọ rẹ fun ẹlomi-in loyun, Biọla dana sunle l’Ondo

Spread the love

Adugbo Mofẹrere, niluu Ondo, ni iyaale ile kan, Biọla Gboyega, ti wọn epo bẹntiroolu lu awọn dukia ọkọ rẹ, Bankọle Adefiranye, to si fi ina si i. Nnkan to fa iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, naa ni pe Biọla ni ọkọ oun fun ẹlomi-in loyun nita.

ALAROYE gbọ pe Biọla atọkọ rẹ yii ti n gbe pọ ninu ile yii latọdun mẹrin sẹyin. Niṣe ni wọn ni ọkunrin naa ṣeleri ati fẹ ẹ gẹgẹ bii iyawo, ṣugbọn lojiji lo fun ẹlomi-in loyun nita. Iṣẹlẹ yii lo fa ija laarin oun ati Bankọle, ti awọn mọlẹbi ati lanlọọdu ile ti wọn n gbe si gbiyanju lati pari aawọ naa.

Gbogbo igbiyanju wọn lati ri ọrọ ọhun yanju lo ja si pabo, nitori ṣe ni Bankọle ni ẹni toun fẹẹ fẹ gẹgẹ bii iyawo lo ti loyun foun yẹn. Ọrọ naa lo gbodi lara Biọla, o si ṣeleri pe oun yoo gbẹsan lara ọmọkunrin naa. Ọmọbinrin naa gba ile awọn obi rẹ lọ niluu Igbindo, to wa lẹbaa Ondo, o si ṣe ọsẹ meji nibẹ. Niṣe ni awọn eeyan ro pe ọrọ naa ti pari sibẹ nigba ti wọn ko gburoo Biọla mọ. Aarọ kutu Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja ni ọkada ṣadeede gbe e de, to si gbe galọọnu epo bẹntiroolu dani.

Wọn sọ pe bo ṣe n denu ile naa lo ba ọmọ kekere kan nibẹ, awọn agbaagba si ti lọ sibi iṣẹ. Ṣe lo fi epo bẹntiroolu naa wọn ayika ile yii, to si ṣana si i.

Ọkunrin kan to n kọja lọ lo ṣakiyesi pe ina n jo ninu ile naa, oun lo si pe akiyesi awọn ero to n kọja lọ si i.
Ṣugbọn si iyalẹnu awọn eeyan, niṣe ni Biọla ni ki wọn fi ina naa silẹ, o si tun fi kọkọrọ ti gbogbo ilẹkun ile yii pa.
Ọmọkunrin lanlọọdu yii to de lẹyin ti ina ti jo ile ọhun tan lo gba lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti.

Nigba ti wọn tẹle ọkunrin naa debẹ, wọn mu Biọla, wọn si gbe e lọ si teṣan ọlọpaa. Biọla ṣalaye fawọn agbofinro pe ololufẹ oun tẹlẹ ni Bankọle. O ni latọdun mẹrin sẹyin loun pẹlu rẹ ti n fẹra, ti awọn si ti jọ pinnu pe awọn aa ṣe igbeyawo ko too di pe o ṣadeede fun ẹlomi-in loyun.

O ni iṣẹlẹ yii lo dun oun toun fi sọ ina si ile rẹ, toun si fi jo awọn dukia ti oun pẹlu Bankọle jọ ra latọdun mẹrin sẹyin.

Niṣe ni Bankọle bu sẹkun nigba to n sọrọ ni teṣan, o ni gbogbo iṣẹ ti oun fi aarọ oun ṣe ni ọmọbinrin naa sọ ina si.

Ṣa, awọn ọlọpaa ti sọ fun mọlẹbi awọn mejeeji pe awọn yoo gbe ọrọ naa de kootu lẹyin iwadii awọn.

 

 

 

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.