Nitori ti Modupẹ ko fẹ ki a fiya jẹ ọkọ rẹ la ṣe yinbọn pa a- Mustapha

Spread the love

Iku ifẹ ni iyaale ile kan, Catherine Modupẹ Akinbi, ku lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun to kọja. Idi ni pe ṣe ni obinrin yii n rababa niwaju awọn ẹlẹgiri to ba wọn lalejo tipatipa naa pe ki wọn dakun, ki wọn ma ṣe ọkọ oun, Joseph, nijamba, arọwa yii lo bọ sodi lara awọn ole naa ti wọn fi gbebọn fun ẹni to n pẹtu si wọn ninu.

 

Ọkan ninu awọn adigunjale ọhun, Azeez Mustapha, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ ‘School Boy’, lo ṣalaye bẹẹ fawọn ọlọpaa. Awọn ikọ adigunjale naa, eyi ti Mustapha lewaju wọn lo lọọ ka awọn lọkọ-laya naa mọle wọn to wa ni Iju, awọn ni wọn si yinbọn pa Abilekọ Akinbi. Idi ti wọn fi ṣe bẹẹ gẹgẹ bii alaye Mustapha ni pe iyaale ile naa sọ pe ara ọkọ oun ko ya, ki wọn ma yinbọn fun un. O ni alagidi ni ọkọ Modupẹ, niṣe lo si mu ọkan ninu awọn ọmọ toun ko lẹyin lọọ ṣiṣẹ nile rẹ silẹ, to n gbiyanju lati lọ ibọn gba mọ ọn lọwọ.

Mustapha ni ibinu naa loun fi fẹẹ yinbọn lu u, ṣugbọn iyawo rẹ lo sọrẹnda ara rẹ fawọn, o ni ki wọn fi ẹmi oun rọpo ẹmi rẹ.

Ọga ọlọpaa, Imohimi Edgal, ṣalaye pe ọwọ ti kọkọ tẹ meji lara awọn to ṣiṣẹ naa tẹlẹ, iyẹn Isa Shobayọ ati Ọlalekan Ogundimu. Inu otẹẹli kan to wa ni Dọpẹmu, l’Agege, ni wọn ti pada waa ri Azeez, ẹni ọdun mẹrinlelogun ati ekeji rẹ, Rasaq Orisunmade, ẹni ọdun mejilelogun, mu, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja.

 

 

 

 

 

 

(29)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.