Nitori ti ko ya a ni foonu lati fi pe, Usman fẹẹ gun ọrẹ rẹ pa l’Ekoo

Spread the love

Usman Yunisa, ẹni ọdun mọkanlelogun, ni wọn ti wọ lọ si kootu Majisreeti to wa ni Ikẹja, niluu Eko, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja. Ẹsun igbiyanju lati paayan ni Agbefọba, Sajẹnti Kenrich Nomayo, fi kan an.

Gẹgẹ bi alaye ti ileeṣẹ ọlọpaa ṣe fun Adajọ T. A Ojo, wọn ni ṣe ni ọkunrin to n gbe laduugbo Bolade Oshodi, niluu Eko yii, gbiyanju lati paayan, bẹẹ lo si tun tabuku ẹnikan lọjọ kejila, oṣu to kọja, laduugbo Agege Motor Road, Bọlade Oshodi. Nomayo ni ṣe ni Usman fẹẹ gun ọrẹ rẹ kan, Idris Bala, pa pẹlu bo ṣe gun un lọbẹ nikun nigba ti Idris kọ lati fun un ni foonu rẹ lati fi pe eeyan.

Ibinu foonu ti Bala ko fun un lo fa a ti Usman fi mu ọbẹ to fi n ta eso ‘water melon’, to si fi gun un.

Awọn ẹsun naa tako awọn abala kan ninu ofin to de iwa ọdaran ti ipinlẹ Eko n ṣamulo rẹ, tọdun 2015 gẹgẹ bi ile-ẹjọ ṣe sọ.

Adajọ Ojo faaye beeli ẹgbẹrun lọna irinwo Naira (400,000.00),  ati oniduuro meji ti wọn ba ni iru owo bẹẹ nikaawọ silẹ fun un.

Ọjọ kẹwaa, oṣu to n bọ, nigbẹjọ mi-in.

 

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.