Nitori patako ipolongo Jimi Agbaje ti wọn bajẹ, ọlọpaa ṣekilọ fawọn oloṣelu

Spread the love

Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Imohimi Edgal, ti ṣekilọ fun awọn oloṣelu lati ri i daju pe awọn tẹle gbogbo ofin ti ileeṣẹ naa la kalẹ fun eto idibo ọdun to n bọ. Edgal ṣalaye yii ninu atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Chike Oti, fi sita lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja. O ni ileeṣẹ naa ri iwe ẹhonu gba latọdọ oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Jimi Agbaje, ninu eyi to ti ṣalaye pe awọn kan lọọ wo awọn patako ipolongo oun lulẹ.

Eyi lo fa a ti kọmisanna fi paṣẹ fun ọga awọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Yaba, pe lati asiko yii lọ, niṣe ni ki wọn maa gbe ẹnikẹni ti wọn ba ri to n ya posita ipolongo ibo ẹgbẹ yoowu jẹ, tabi to n ba patako giriwo (bill board), ẹgbẹ oṣelu kankan jẹ.

Bakan naa l’Edgal ti paṣẹ pe ki wọn ranṣẹ pe gbogbo awọn alaga ẹgbẹ oṣelu patapata nipinlẹ naa, ati awọn oludije wọn pẹlu ajọ INEC, fun ipade pataki kan ti yoo waye lọla, Ọjọruu, Wẹsidee, ni ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Ikẹja.

Ni ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, ni Jimi Agbaje pariwo sita pe awọn kan ti n ya posita ipolongo oun, bẹẹ lawọn kan tun n halẹ mọ awọn to n polongo fun oun. O ni eleyii ko le da omi tutu si oun lọkan, ṣugbọn irufẹ igbesẹ ti awọn eeyan naa n gbe ko ṣẹlẹ ri niluu Eko. Ẹni ti yoo dupo igbakeji funpo gomina lorukọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Haleemat Oluwayẹmisi, naa fi aidunnu ọkan rẹ han si igbesẹ naa, o ni ko fihan pe a wa lasiko ijọba dẹmokiresi rara.

 

(20)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.