Nitori patako ipolongo ibo, awọn janduku kọlu awọn alatilẹyin PDP

Spread the love

Lasiko ti wọn n fi pataki ipolongo lọlẹ lagbegbe Fate, niluu Ilọrin, lawọn janduku kan ti ko niye ya bo awọn alatilẹyin ẹgbẹ PDP kan labẹ asia, Kwara Youth Mobilisation for Good Governance (KWYMGG), ti wọn si lu wọn lalubami.

Patako ipolongo ọhun ni aworan olori ile-igbimọ aṣofin agba, Dokita Bukọla Saraki, oludije gomina, Rasak Atunwa, ati oludije ile aṣoju-ṣofin fun ẹkun ***Ilorin East/ Ilorin South, Abdulwahab Ọladimeji Issa wa.

Nibi tawọn eeyan ọhun ti pe jọ lati ṣepade ranpẹ lẹyin ti wọn ṣi patako ipolongo naa lawọn janduku kan ṣadeede jade si wọn pẹlu ada ati ibọn. Nise ni onikaluku bẹrẹ si i sa kijokijo bi iro ibọn ṣe gba gbogbo agbegbe naa kan.

Lara awọn alatilẹyin PDP naa farapa nibi iṣẹlẹ ọhun.

Ko ti i ṣeni to mọ ẹni to ran awọn janduku naa tabi ẹgbẹ oṣelu ti wọn n ṣiṣẹ fun. Ṣugbọn ẹgbẹ KWYMGG fẹsun kan APC.

Laipẹ yii lẹgbẹ APC fẹdun ọkan wọn han si bawọn eeyan kan ṣe ba awọn patako ipolongo wọn kaakiri ipinlẹ Kwara jẹ. Wọn ni o ṣee ṣe ko jẹ ọna lati gbẹsan ni akọlu ọsẹ to kọja yii.

 

 

 

(24)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.