Nitori owo Paris, Akeredolu atawon osise ipinlẹ Ondo fẹẹ gbena woju ara won

Spread the love

Nitori bi Gomina ipinle naa, Rotimi Akeredolu, ṣe kọ lati san ajẹsilẹ owo-oṣu mẹrin ti ijọba jẹ wọn lẹyin to ti gba owo idoola ti wọn n pe ni Paris Fund, ti ijọba apapọ fun wọn, ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Ondo ti fi aidunnu wọn han.

Lọsẹ bii meji sẹyin ni awọn to jẹ aṣaaju ẹgbẹ yii ṣepade pẹlu Olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi gomina, Ọgbẹni Toyin Akinkuotu, nibi ti wọn ti fun Akeredolu di ọjọ kejila, oṣu yii, pe ko fi san owo ajẹmọnu ọdun 2017 to jẹ wọn, tabi ki wọn berẹ iyanṣẹlodi.

Lẹyin ipade ti wọn ṣe yii ni gomina yii ṣeleri fun wọn pe oun ti ṣetan lati san owo ajẹmọnu wọn ti ọdun to kọja, leyii to mu ki awọn oṣiṣẹ naa sinmi lori erongba wọn lati yanṣẹ lodi.

Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, ni aṣaaju awọn oṣiṣẹ tun kede pe wọn ti gbọ pe ijọba apapọ ti san biliọnu lọna ogun ati aadọrun-un miliọnu Naira (#20.9b), sinu asunwọn ijọba ipinlẹ Ondo gẹgẹ bii owo Paris ti wọn n reti lati fi san awọn ajẹsilẹ owo-oṣu.

Lẹsẹkẹsẹ ni awọn aṣaaju oṣiṣẹ naa ti kede pe ki gbogbo awọn oṣiṣẹ pade lọfiisi gomina to wa ni Alagbaka, laaarọ ọjọ keji ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun, ki wọn le fẹhonu han tako bi ijọba ṣe dakẹ, ti ko fọhun lori ọrọ owo ti wọn ṣẹṣẹ gba.

Awọn oṣiṣẹ ni awọn ti gbọ pe Akeredolu ti gbimọ-pọ pẹlu oluṣiro owo agba nipinlẹ Ondo lati gbe owo Pariisi to gba pamọ sile ifowopamọ ko le baa mu ele wa.

Ọkan-o-jọkan orin eebu ati owe lawọn oṣiṣẹ naa kọ la ti fi tabuku gomina lasiko ifẹhonu han, bo tilẹ jẹ pe ọkunrin yii wa nipinlẹ Ekiti, nibi ti wọn ti n bura fun Gomina Kayọde Fayẹmi.

Toyin Akinkuotu to gbẹnu rẹ sọrọ ni ko si ootọ ninu ẹsun ti awọn oṣiṣẹ naa fi kan gomina. Olori awọn oṣiṣẹ yii jẹ ko di mimọ pe loootọ ni wọn ti kọkọ sanwo naa si asunwọn ijọba ipinlẹ Ondo, ṣugbọn wọn tun ti gba owo naa pada ninu asunwọn ti wọn san an si.

Ọjọbọ, Tọside, ọsẹ to kọja ni gomina ṣepade pẹlu awọn adari oṣiṣẹ lọfiisi rẹ niluu Akurẹ, ṣugbọn ija ni wọn fi tuka nibi ipade naa. Ṣa, adari awọn oṣiṣẹ naa ti ni awọn yoo ṣepade mi-in, ki awọn le baa mọ igbesẹ to kan lati gbe.

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.