Nitori owo ọkọ ayọkẹlẹ ti ko fun wọn, awọn kansẹlọ binu si Gomina Ahmed

Spread the love

Agbarijọpọ awọn kansẹlọ nipinlẹ Kwara ti fẹdun ọkan wọn han tako bijọba ṣe kọ lati fun wọn ni ẹyawo lati ra ọkọ ayọkẹlẹ, ati bi nnkan ko ṣe lọ deede lagbegbe wọn latigba ti wọn de ori ipo.

ALAROYE hu u gbọ pe nibi ipade idakọnkọ pẹlu Gomina Abdulfatah Ahmed to waye l’Ọjọruu, (Wẹsidee), ọsẹ to kọja yii, ni wọn ti binu sijọba.

Ọkan ninu wọn ni o ṣoro fawọn gẹgẹ bii kansẹlọ laduugbo lati bọ mọlẹbi ati lati ṣe ojuṣe awọn fun araalu.

Esi ti wọn ni Gomina Ahmed fun wọn ni pe ko sibi toun ti fẹẹ ri owo fun wọn, bẹẹ loun ko le fọwọ si ẹyawo Kankan, paapaa julọ, pẹlu eto idibo to n bọ ti ko sẹni to mọ ibi to maa ja si.

O ni ki wọn lọọ mura siṣẹ daadaa lati ri i pe PDP jawe olubori idibo ọdun to n bọ. Eleyii lo le mu wọn tubọ jẹ anfaani ti wọn n wa. O ni bi APC ba le gbajọba, ko si bi wọn ṣe le da owo ti wọn ba ya lati ra ọkọ pada.

Idahun yii ni wọn lo bọ sapo ibinu awọn eeyan naa. Nigba to di ọjọ keji ni wọn gba ile ẹgbẹ PDP lọ, nibi ti ireti wa pe wọn yoo ti ba awọn adari ẹgbẹ ati oludije funpo Gomina, Abdulrasak Atunwa, sọrọ.

Ṣugbọn si iyalẹnu wọn, Atunwa kọ lati yọju sibi ipade naa, ṣe lo ran aṣoju sibẹ. Bi wọn ṣe ni awọn ọnarebu ọhun tun fabinu yọ niyẹn, ti wọn si n ke fatafata, wọn ni oludije gomina naa foju di awọn ni ko ṣe wa sibi ipade ọhun.

Wọn ni gbogbo ohun tawọn se tile fi jo ati bijọba ṣe n fa ori ijọba ibilẹ lawọn yoo tu saye. Bijọba ba si kọ lati dahun ibeere awọn, o ṣee ṣe kawọn fẹgbẹ PDP silẹ.

Asiko yii ni wọn ni awọn oloye ẹgbẹ to wa nibẹ bẹrẹ si i pẹtu si wọn ninu. Wọn ni ki wọn ni suuru ki alaga ẹgbẹ, Kọla Shittu, de lati Abuja. Nibẹ ni wọn ti pe e lori foonu, tiyẹn naa si n bẹ wọn lati jẹburẹ.

Ṣugbọn alaga agbarijọpọ awọn abẹnuga ile-igbimọ aṣofin ijọba ibilẹ, Ọnarebu Habeeb Ọlalere Quadri, ti tako ahesọ naa. O nirọ patapata niroyin pe awọn kansẹlọ ọhun n gbero lati darapọ mọ APC.

O lọrọ ti wọn ni Gomina Ahmed sọ ko ri bẹẹ rara, ko si bo ṣe le sọ iru nnkan bẹẹ. O lawọn alatako ti wọn jẹ ọta ijọba lo wa nidii ọrọ yii.

O ni alaga naa ti gbọ ẹbẹ awọn kansẹlọ ọhun, o si ti n gbe igbesẹ lori gbogbo ibeere wọn.

Ọlalere ni gbogbo awọn kansẹlọ to wa nipinlẹ Kwara ni wọn jẹ alatilẹyin Saraki, ko sohun to le mu iyapa waye laarin wọn.

 

 

 

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.