Nitori owo ajẹmọnu wọn tijoba ko san, awọn alakooso kansu ana fẹẹ fi ẹgbẹ PDP silẹ

Spread the love

Lẹyin ọsẹ kan tawọn kansẹlọ nipinlẹ Kwara, fẹdun ọkan wọn han sijọba, awọn to ṣakoso kansu laarin ọdun 2013 si 2016 naa ti n gbaradi lati fẹgbẹ PDP silẹ pẹlu awọn alatilẹyin wọn nitori bi ijọba ṣe kọ lati san ajẹmọnu wọn.

Awọn eeyan ọhun ti wọn kora wọn jọ lati gbogbo ijọba ibilẹ mẹrindinlogun nipinlẹ Kwara, lỌjọbọ, Tọsidee, to kọja ni wọn fi erongba wọn han lẹyin ipade to waye niluu Ilọrin.

Lara awọn tọrọ naa kan ni awọn kansẹlọ ọgọrun-un kan le mẹrindinlaaadọrin (166), awọn alaamojuto kansu ọgọrin, awọn akọwe kansu mẹrindinlogun, atawọn igbakeji alaga kansu.

Ọkan lara awọn kansẹlọ to tun jẹ alukoro gbogbogboo, Ọnarebu Bisi Oloyede, ni oriṣiiriṣii igbesẹ lawọn ti gbe lati ri i pe ijọba da awọn lohun, ṣugbọn pabo lo n ja si.

O ni Gomina Abdulfatah Ahmed ti ṣeleri lọpọlọpọ igba lati yanju ọrọ naa, ṣugbọn ileri lasan lawọn kan n ri, ijọba ko mu un ṣẹ.

“Bẹẹ gẹlẹ ni olori ile-igbimọ aṣofin agba, Sẹnetọ Bukọla Saraki, to tun jẹ adari ẹgbẹ ṣeleri fun wa lati yanju ẹ, bakan naa lọmọ ṣori. Ko si nnkan kan ta a ri.

Awọn eeyan ọhun to da bii ẹni pe ọrọ naa ko fẹẹ ye wọn mọ lawọn kabaamọ pe awọn ṣatilẹyin fẹgbẹ PDP ati Saraki. Wọn lawọn yoo tẹsiwaju lati ja fẹtọọ awọn ni gbogbo ọna.

Wọn ke si ijọba lati gbe igbesẹ to ba yẹ lori ọrọ naa, ki wọn si san gbogbo ajẹmọnu ti wọn jẹ awọn lai fi akoko ṣofo. Eleyii nikan ni wọn lo le mu ki awọn ṣi duro si ẹgbẹ PDP.

“A jọ gbe ẹgbẹ PDP yii duro ni. A ṣi nifẹẹ ẹgbẹ wa, ṣugbọn o jẹ ohun to ba wa lọkan jẹ pe wọn da wa nu bii eepo ẹpa ti ko wulo mọ, nitori bi wọn ṣe kọ lati san ẹtọ wa fun wa”.

 

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.