Nitori oro ilẹ, Iyalọja Ọbada-Oko ati Kabiyesi kọju ija sira wọn.

Spread the love

Ija naa ko ṣẹṣẹ bẹrẹ, wọn ti wa lẹnu ẹ to ọdun meloo kan. Iyẹn ija agba to n lọ laarin Iyalọja Ọja Ọbada-Oko, nijọba ibilẹ Ewekoro, nipinlẹ Ogun, Alaaja Ganiyat Akankẹ, ati Kabiyesi ilu naa, Ọba Olufẹmi Abiọdun Afẹjanlajiyan Kin-in-ni. Ṣugbọn ibi ti ọrọ naa de duro bayii ti kuro ni wasa, nitori Iyalọja loun ko ni i gba, ọba alaye naa si ni tọba laṣẹ.
Gẹgẹ bi alaye ti Iyalọja ṣe fun ALAROYE lọjọ Satide ijẹrin ati lanaa, Mọnde yii, ti i ṣẹ ọjọ ọja Ọbada-Oko, o ni l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹrin, to kọja yii, Kabiyesi Ọba Olufẹmi ko awọn fijilante wọnu ọja, o ni ki wọn maa le awọn Parakoyi (Awọn alakooso ọja ) kuro, ki ẹnikẹni ma si ṣe naja lori ilẹ ọja naa mọ.
Iyalọja yii sọ pe ko sohun to mu Ọba Ṣolaja paṣẹ yii ju pe o fẹẹ ta ilẹ ọja naa lọ. O ni talẹ-talẹ ni k0abiyesi, o si fẹ kawọn jọ maa ta ilẹ naa ni, ṣugbọn nigba toun ko gba a laaye iru ẹ, toun sọ fun un pe ijọba lo nilẹ, ni ọba naa ti koriira oun. Latigba naa lo si ti sọ oun di ọta rẹ, to n daamu oun atawọn eeyan ọja, ti wọn tun fi waa da ọja awọn eeyan nu lọjọ ọja to kọja naa, ti ko si ṣeni to fẹdọ lori oronro.
Bi ko ba si ti alaga kansu ijọba ibilẹ Ewekoro to da si ọrọ naa ni, ti wọn ko awọn ọlọpaa SARS waa fi le awọn fijilante naa lọ, Iyalọja Ọbada sọ pe wahala ọjọ naa ko ba kọja bẹẹ. Ṣugbọn awọn ko roju-raaye naja ọhun mọ, inu-fuu-aya-fuu lawọn fi n taja.
Obinrin yii sọ pe ilẹ ti kabiyesi n ja si yii, ilẹ ijọba ni, o ni ṣugbọn ọba yii ko fẹẹ gba bẹẹ.
O loun ti lọọ fi ẹjọ rẹ sun Alake paapaa lori ọrọ ilẹ ọja yii, bẹẹ awọn ki i ṣọta ara awọn tẹlẹ, igba to fẹ kawọn jọ maa talẹ pẹlu baalẹ kan ti wọn n pe ni Saubana Ojodu, Baalẹ abule Ṣorobi, l’Ọbada kan naa toun ko gba fun un lo bẹrẹ si i gbogun ti oun.
Iyalọja yii ni ki wọn ba oun bẹ Ọlọbada ko yee daamu oun lori ipo toun wa, ko si ma fọwọ kan ilẹ ọja oun.
ALAROYE de ọja Ọbada-Oko lanaA ode yii lati fọrọ wa awọn eeyan lẹnuwo lori ohun to ṣẹlẹ naa, ọpọ awọn ti a ba sọrọ sọ pe bẹẹ lọrọ ri loootọ, wọn ni wọn da ọja awọn nu, awọn ko si fi ifọkanbalẹ taja awọn.
A ba Kabiyesi Ọlọbada sọrọ, Ọba Afẹjanlajiyan naa ṣalaye tiẹ pe oun ko tiẹ mọ pe Iyalọja wa lọja, nitori iya to n fẹjọ sun yii ki i ṣe iyalọja mọ, ijọba ti fofin de e fungba diẹ na, oun atawọn oloye rẹ to yan.
Ọba sọ pe bi Akankẹ ṣe n pera ẹ ni Iyalọja lasiko yii lodi sofin patapata, oun ko si ni i gba fun un.
Lori pe kabiyesi ran awọn fijilante lọ sọja lati da ọja ru lọsẹ to kọja, ọba yii sọ pe nitori awọn iwakiwa, iwa ajẹbanu ti Iyalọja yii n hu loun ṣe gbe igbesẹ naa. O ni Iyalọja ko ni isọ ninu ọja naa latọdun karun-un to ti loun n joye naa, ṣugbọn yoo jokoo sibi kan, awọn to yan ni parakoyi yoo waa maa ko ọja lori awọn ọlọja, wọn yoo ko o waa fun Akankẹ, bo ti n di iṣu lọ sile ni wọn yoo maa ru elubọ tẹle e.
Ọlọbada sọ pe iya yii lo tun n fi ṣọọbu rẹnti ninu ọja naa, to n gbowo nla lọwọ wọn. Gbogbo nnkan bẹẹ loun ko fẹ mọ, toun si sọ fun Ganiya pe ko yẹ ko ri bẹẹ, to fi di pe Iyalọja naa n kọyin soun.
A beere pe ṣe loootọ ni Kabiyesi fẹẹ talẹ ọja, Ọlọbada loun ko talẹ mi-in ju ilẹ abule baba oun lọ, oun ko mọwọ de ibi ilẹ ọja rara. O ni loootọ ni Iyalọja ti lọọ sọrọ oun fun Alake ilẹ Ẹgba, ti baba naa si ti da si i lẹẹmẹta, ṣugbọn oun ko ni i yi ipinnu toun pada lori awọn parakoyi to n jale, ti Akankẹ si n gbe lẹyin wọn.

(50)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.