Nitori ọmọ kan ṣoṣo ti wọn n fa mọ ara wọn lọwọ, adajọ ni kawọn ọkunrin mẹta lọọ ṣayẹwo ẹjẹ

Spread the love

Ṣe lọrọ ọhun da bii ere ori itage ninu kootu kọkọ-kọkọ to wa niluu Ọwọ, nibi tawọn ọkunrin mẹta ọtọọtọ ti n ba ara wọn jiyan lori ẹni to jẹ baba ọmọkunrin kekere kan ti iya rẹ, Abilekọ Iyabọ Oloye, ṣi n gbe lọwọ.

 

Ọgbẹni Oloye Adelẹyẹ ti Abilekọ Iyabọ wa nile rẹ lọwọlọwọ gẹgẹ bii iyawo lo mu ẹjọ wa si kootu naa, to si n rawọ ẹbẹ pe oun fẹẹ mọ ẹni to jẹ ojulowo baba fun ọmọ ti awọn n jiyan le lori ọhun.

 

Olupẹjọ ni lati kekere loun ti n tọju ọmọ naa bọ, o ni ohun ti oun n fẹ ni ki kootu ọhun ba awọn fopin si awuyewuye to n waye laarin oun pẹlu awọn meji mi-in, Ọgbẹni Olu Dokita ati Fẹmi Ogunoye lori ọrọ ọmọ ọdun kan aabọ ọhun.

 

Aburo olupẹjọ kan, Aisida Abiọdun, jẹrii ni kootu pe o da oun loju pe ẹgbọn oun kọ lo lọmọ ti wọn n sọrọ rẹ naa.

 

Olu Dokita sọ ni tiẹ pe loootọ loun n yan Iyabọ to jẹ iya ọmọ naa lale, o ni ireti oun ni pe obinrin ọhun gbọdọ bimọ foun lọjọ iwaju.

 

Iyawo Dokita, Abilekọ Wule, sọ ni tiẹ pe abule awọn loun wa lọjọ kan nigba ti ọkọ oun mu Iyabọ de, to si ṣafihan rẹ gẹgẹ bii iyawo tuntun.

 

O ni oun beere bọrọ ọmọ kekere to gbe wa sabule ṣe jẹ, ṣugbọn ọkọ oun sẹ kanle pe oun kọ loun lọmọ ọwọ rẹ.

 

Lẹyin eyi lo ni Dokita paṣẹ fun oun lati pada siluu Ọwọ to si jẹ pe oun pẹlu iyawo tuntun ni wọn jọ n gbe labule lati igba naa.

 

Amofin G.O Awojori to waa gbẹnusọ fun Ọgbẹni Dokita ninu ọrọ tirẹ ni ko si ẹri kankan to fidi rẹ mulẹ pe onibaara oun lo lọmọ ti wọn n ja le lori naa.

 

Agbejọro ọhun ni ọwọ Ọgbẹni Fẹmi Ogunoye lo yẹ ki wọn ti beere bọrọ ọmọ ṣe jẹ, ọkunrin ọhun lo ni ko fi bo fawọn eeyan pe oun loun lọmọ.

 

Nigba ti wọn pe e siwaju lati waa sọ ohun to mọ nipa ọrọ ọmọ, Ogunoye ni iya ọmọ naa ko sọ ọ leti oun ri pe oun kọ loun lọmọ ọwọ rẹ.

 

O ni oju ala loun wa nigba ti wọn darukọ ‘Iyanu’ ti ọmọ naa n jẹ foun, laipẹ yii lo ni oun ati Iyabọ si jọ ni ajọsepọ, eyi to fihan pe ibaṣepọ to danmọran ṣi wa laarin awọn mejeeji.

 

Iyabọ to jẹ iya ọmọ fidi rẹ mulẹ pe Oloye Adelẹyẹ lo lọmọ, o ni ki i ṣe Dokita toun wa lọdọ rẹ gẹgẹ bii iyawo, bakan naa lo sẹ kanlẹ pe ko si ajọṣepọ kankan laarin oun ati Ogunoye to ni oun loun lọmọ.

 

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Aarẹ kootu ọhun, Alagba Dapọ Adebayọ, ni kawọn mẹtẹẹta da owo jọ lati lọọ sayẹwo ẹjẹ ti yoo fi ojulowo baba ọmọ han.

 

Ẹni ti ayẹwo ba fidi rẹ mulẹ pe oun lo lọmọ lo ni o gbọdọ da gbogbo owo ti wọn ba na pada.

 

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun yii, ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.

 

 

(21)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.