Nitori oju ọna wọn ti ko dara, awọn araalu fẹhonu han n’Iwarọ Akoko

Spread the love

Lori  bi ijọba ko ṣe tun awọn ọna wọn to ti bajẹ ṣe, awọn olugbe ilu Iwarọ-Ọka Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Akoko, fẹhonu han l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.

Oriṣiiriṣii akọle bii, ‘Iwarọ-Akoko ti di igbo Sambisa, nibi tọpọ ẹmi ti n ṣofo, ijọba apapọ gbọdọ ṣe ifilọlẹ ọpuresan Lafiya Dole.’ ‘Awa ko ni i gba ọkọ ajagbe laaye lọna wa mọ, a ti ṣetan lati ṣedajọ lọwọ ara wa’, ‘ẹ dakun ẹ gba wa, ojoojumọ la n ku bii adiẹ’, ati awọn akọle mi-in ni awọn eeyan naa gbe lọwọ.

Ṣe tẹlẹ ni ọkọ ajagbe ti ṣe oriṣiiriṣii ọṣẹ lagbegbe naa, koda, ko pẹ ti iru ọkọ yii pa awọn eeyan rẹpẹtẹ lagbegbe ọhun.

Ọkan ninu awọn araalu ọhun to gbẹnu awọn eeyan sọrọ, Ọtunba Dele Ọlọgbẹsẹ, sọ pe, ọpọ ẹmi awọn araalu lo ti ṣofo nitori ọna ti ko daa ti awọn ọkọ ajagbe tun n gba yii. O ni awọn araalu naa ti gbaradi lati ba ijọba fa wahala lori ọrọ yii. O ni awọn ọkọ ajagbe to maa n fi gbogbo igba gba ọna yii lo n fa ijamba ọkọ to n waye yii.Ọkunrin yii ni ọpọ awọn ọkọ naa lo maa n ṣoro fun lati ko ijanu wọn lasiko ti wọn ba n sọkalẹ lori oke nla to ti ilu Iwarọ lọ si Ọka-Akoko yii. O ni o ti le ni ogun ọdun ti ọna ọhun ti bajẹ, to si jẹ pe ọpọ awọn ọmọ ilu naa lo ti ba oriṣiiriṣii iṣẹlẹ ijamba to n ṣẹlẹ lọna yii rin. O waa rọ ijọba apapọ lati pa ọna marosẹ to gba aarin ilu Iwarọ Ọka kọja ti na, ki wọn si gbiyanju lati ṣe atunṣe si ọna Ipele si Idoani ati Isua, eyi to ti bajẹ kọja bẹẹ.

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.