Nitori ọgọrun-un Naira, ọlọkada na ọga rẹ daku l’Ondo

Spread the love

Ọlọkada kan, Akinṣọwọn Fẹmi, lo lu ọga rẹ ninu ẹgbẹ ọlọkada niluu Ondo, Akinsanmi Ṣootọ, titi ti ori ọkunrin naa fi bẹjẹ. Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye fun wa pe ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lagbegbe Idi-Ishin, niluu naa. Wọn ni lilu ti Fẹmi lu Ṣootọ yii loo mu ki ọkunrin naa daku lọ rangbọndan, koda, o gba awọn eeyan lọpọ wakati ki wọn too ji i saye pada.

Fẹmi la gbọ pe o n gun ọkada rẹ bọ lati agbegbe Suruulere, niluu naa, to si gbe obinrin kan lẹyin. Nigba to de ikorita Idi-Ishin ni wọn ni oṣiṣẹ yuniọọnu yii, Ṣootọ, da a duro, to si ni afi ko mu owo tikẹẹti wa ko too le maa lọ.

Wọn ni Fẹmi ṣalaye pe oun ti ja tikẹẹti naa lọdọ ẹlomi-in, ṣugbọn wọn ri i pe irọ lo n pa. Ṣootọ sọ fun ọkunrin naa ko mu tikẹẹti to gba naa jade koun ri i, ṣugbọn ọkunrin naa fariga, eyi lo si fa wahala laarin wọn. Wọn ni lẹsẹkẹsẹ ni Ṣootọ fọ eti Fẹmi, ti iyẹn naa ko si besu-bẹgba to fi bẹrẹ si i lu ọga yuniọnu naa, koda, o lu u ti gbogbo ori ati ẹnu rẹ fi bẹjẹ. Ko pẹ si asiko yii ni Ṣootọ daku lọ rangbọndan, to si jẹ pe o gba awọn eeyan lọpọ wakati ki wọn too ji i pada saye.

Awọn eeyan ko mọ igba ti awọn ọlọpaa meji kan ti ko wọṣọ de ibi iṣẹlẹ yii, ti wọn si mu Fẹmi lọ si teṣan wọn laduugbo Yaba, niluu Ondo. Awọn ọlọpaa yii kan naa lo duro ti Ṣootọ to fi ji pada, lẹyin naa ni wọn gbe oun pẹlu lọ si agọ wọn, nibi ti wọn ti gba ọrọ silẹ lẹnu oun naa.

(16)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.