Nitori oṣelu ni Akintọla ṣe da iwe iroyin Sketch silẹ, iwe naa lo si gba a lọwọ awọn Tribune

Spread the love

Olori ijọba Western Region, Oloye Samuel Ladoke Akintọla ṣe kinni kan funra rẹ, ohun ti awọn ọjọgbọn n pe ni agbayanu ni. Iwe iroyin kan ṣoṣo lo ṣaaju ni gbogboWest, iwe iroyin Tribune ni, gbogbo aye lo si mọ pe iwe naa, iwe Action Group ni. Ṣe Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ lo ti da a silẹ tipẹtipẹ, ko si si ohun meji ti iwe naa n ṣe ju ọrọ oṣelu lọ, oṣelu Awolọwọ ati awọn ọmọ ẹyin rẹ ni. Nigba ti Awolọwọ n ṣejọba, bi eeyan ko de ile ijọba rara, koda bi eeyan wa ni ilẹ okeere, bo ba ti ni iwe iroyin Tribune lọwọ, yoo mọ gbogbo ohun to n lọ, awọn iṣẹ ti Awolọwọ n ṣe, awọn ọta to ni, awọn ọrẹ rẹ, ati bi ẹgbẹ oṣelu wọn ṣe n fi ojoojumọ dagba si i, iwe naa ko ni i jade bi ko ba jẹ o gbe iroyin ohun ti Awolọwọ n ṣe nile ijọba. Eleyii ran ijọba ati oṣelu Awolọwọ funra rẹ lọwọ pupọ, nitori ko si ibi ti wọn ko ti mọ ọn jakejado Naijiria.

Awọn iwe iroyin mi-in wa o, ṣugbọn nitori gbogbo wọn naa lo mọ orukọ Awolọwọ ati iṣẹ rẹ, ko sẹni to n lodi si i, bẹẹ ni wọn ki i lodi si ẹgbẹ oṣelu AG naa, bii igba pe awọn naa n ṣiṣẹ fun wọn ni. Nidii eyi, ko si iwe iroyin tabi ileeṣẹ iroyin kan ti i lodi si Action Group tabi Awolọwọ nigba ti ọkunrin naa fi n ṣe olori ẹgbẹ oṣelu rẹ, to si jẹ olori ijọba Western Region lati bii ọdun 1952 titi di ọdun 1959. Nigba naa, awọn oloṣelu mi-in ninu ẹgbẹ wọn tilẹ dabaa pe o ma yẹ ki awọn naa ni iwe iroyin kan ti yoo maa ja fun ẹgbẹ tiwọn nikan, gẹgẹ bi Nnamdi Azikiwe ti ni Pilot to jẹ oun ati ẹgbẹ rẹ lo n ja fun, ti awọn Ahamdu Bello naa si ni Gasikiya lọdọ wọn. Ṣugbọn kia lawọn mi-in ti dide, pe ko si ohun ti iwe iroyin kan fẹẹ ṣe fawọn, Tribune ti awọn ni yii naa ti to, iṣẹ to n ṣe fawọn ko kere, ti gbogbo ẹgbẹ si tun ni.

Ṣugbọn nnkan yipada biri nigba ti Akintọla gbajọba. Ki i ṣe loju ẹsẹ naa lo yipada o, wọn kọkọ n ṣe daadaa sira wọn nigba ti nnkan n lọ daadaa. Nigba ti Akintọla n ṣejọba, to si n foribalẹ lọdọ Awolọwọ, to jẹ ko ni i ṣe kinni kan bi ọga rẹ ko ba faṣẹ si i, awọn iwe iroyin naa ti fun un lorukọ Baba kekere, pe aṣoju ati adele Awolọwọ ni, oun larole, ohun gbogbo to ba n ṣe ni i jẹ daradara. Nigba naa, bi ijọba oun naa ba so pẹnrẹn, aa jade ninu Tribune, wọn yoo si maa ki wọn pe ijọba Action Group lo n ṣe daadaa julọ, ati pe ko si ipinlẹ kan to tun da bii Western Region ni gbogbo Naijiria. Ohun gbogbo lọ bẹẹ fun bii ọdun kan, lati Disẹmba, ọdun 1959, titi di Disẹmba, ọdun 1960. Lati ibẹrẹ ọdun 1961, nnkan bẹrẹ si i daru diẹdiẹ laarin Awolọwọ pẹlu ọmọọṣẹ rẹ, ọrọ Awolọwọ yii ti fẹẹ su Akintọla, o si ti n wa awọn ọrẹ tuntun mi-in lati maa ba ṣe.

Lati bii ibẹrẹ ọdun 1961 ni nnkan ti bẹrẹ si i wọ wa laarin Awolọwọ ati igbakeji rẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn aye ko tete mọ nnkan kan. Ṣugbọn lati igba naa ni ikilọ keekeeke ti bẹrẹ si i jade fun ijọba Akintọla ninu iwe Tribune. Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ni i kilọ fun Akintọla tabi ki wọn darukọ rẹ si i, wọn yoo maa kilọ fun ijọba rẹ pe ki ijọba ma ṣe eyi to fẹẹ ṣe, tabi ko ṣe bayii, tabi pe eyi ti wọn ṣe yii ko dara. Olowe mọ owe, afi ti tọhun ko ba ni i dahun nikan. Ati pe ẹni ti wọn n ba sọrọ yii, iyẹn Akintọla funra rẹ, ọga awọn oniroyin ni, olootu iwe iroyin Daily Service fun ọjọ pipẹ, to si jẹ iṣẹ iroyin naa lo ba lọ si ilu oyinbo lati kawe si i ko too ya sidii iṣẹ lọọya, ko si ọgbọn ti wọn da sinu iroyin, tabi ọna ti wọn fi kọ kinni naa ti ko ye e. Oun naa mọ pe awọn Tribune n ta soun, ṣugbọn ko dahun, o mọ pe nnkan yoo yipada to ba ya

Ṣugbọn nnkan ko yipada, nitori bi nnkan ṣe n bajẹ si i laarin oun ati Awolọwọ, bẹẹ naa ni nnkan n bajẹ si i laarin oun ati Tribune, ti iroyin lile ati ọrọ lile si bẹrẹ si i jade ninu iwe naa si i. Awọn ọrọ bii, “Iru iwa wo ree!” “Ṣe awọn ti wọn n ṣejọba yii ko lọgbọn lori ni!” “Ijọba yii yoo ma fi ọwọ ara rẹ ṣe ara rẹ o!” “Ṣe ijọba yii fẹẹ ba ti ẹgbẹ Action Group jẹ ni Western Region ni!” ati awọn ọrọ lile mi-in bẹẹ lọ. Nigba to fi waa di ọdun 1962, ohun gbogbo ti bajẹ pata, agaga nigba ti ẹgbẹ Action Group gbiyanju lati yọ Akintọla ti tọhun taku, ti ọrọ si di ohun ti wọn n fọ aga mọ ara wọn lori nile-igbimọ, titi ti wọn fi da ẹgbẹ AG ru, tawọn Akintọla fi da ẹgbẹ tiwọn silẹ, ti wọn si pada sile ijọba lẹyin ti wọn ti ditẹ ju Awolọwọ sẹwọn, to si wa lẹwọn naa ti ko le jade. Ikanra ati ibinu Tribune ru soke si Akintọla, wọn si mura lati ti ijọba rẹ ṣubu.

Gbogbo ohun yoowu ti Akintọla ba ṣe, odi ni i bọ si lọdọ Tribune, koda ko jẹ nnkan daadaa ni. Irin yoowu ti Akintọla ba rin, tabi ti ẹgbẹ Dẹmọ ba rin, tabi ti awọn bii Akinloye, Rosiji, Kotoye, Okunọwọ, Akinjide, Fani-Kayọde, Ọba Akran, ati awọn bẹẹ bẹẹ ti wọn jẹ aṣaaju ati alatilẹyin fun Akintọla ba rin, yoo gbodi lara Tribune, ojumọ, kan eebu kan si ni. Ati pe nitori ti ohun ti Akintọla funra rẹ ṣe buru loju ọpọlọpọ awọn ọmọ Yoruba, to jẹ wọn gba lọkan ara wọn pe Akintọla dalẹ Awolọwọ ni, aṣekupani ọrẹ ni, iwe Tribune yii ni ọrẹ gbogbo mẹkunnu ilẹ Yoruba to mọwe, oun ni wọn n ka, ọrọ to ba si sọ ni wọn yoo gbagbọ lati oke delẹ, koda ko jẹ irọ tabi ahesọ pọnnbele ni. Gbogbo ikoriira to wa fun Akintọla nigba naa, agaga laarin awọn alakọwe, eyi ti iwe iroyin Tribune da si i lọrun ni i joun.

 

Ohun to tun waa ṣẹlẹ ni pe iwe iroyin naa funra rẹ ni awọn onigege-lile ti wọn n kọwe sinu rẹ, awọn ara yunifasiti ti wọn ti kawe-gboye lo pọ ninu awọn ti wọn n ba wọn kọwe, awọn ọrọ ti wọn ba si sọ, gbankọgbii ni. Meloo leeyan fẹẹ ka ninu awọn akọwe yii, wọn yoo bu Akintọla bii ẹni to layin ni, tabi ki wọn tu aṣiri nla ti ẹnikan ko ti i gbọ ri. Ijọba Akintọla funra rẹ lo tubọ wa n fun iwe naa ni orukọ rẹpẹtẹ si i, iwe naa si n gbajumọ laarin awọn ọmọ Yoruba ju bi iba ti ṣe ri lọ. Ọna to fi n fun un lorukọ ni pe ọsẹ kan tabi meji ko ni i lọ ki wọn too ri ẹni kan mu ninu awọn akọroyin Tribune yii, wọn yoo si wọ tọhun lọ sile-ẹjọ. Ko si ohun to n fa a naa ju pe wọn yoo ni tọhun kọ kinni kan sinu iwe Tribune, irọ pọnnbele ni, tabi pe ọrọ ibanilorukọjẹ gbaa ni. Bi iroyin naa ba si ti jade lawọn ọlọpaa yoo gbe ẹni to kọ ọ timọle.

Nibi ti wọn ko ba ti ri ẹni to kọ ọ, tabi ti iroyin naa ba le pupọ pupọ, olootu funra rẹ ni wọn yoo le ti wọn yoo si mu un, wọn yoo si ti i mọle, ki wọn too gbe e lọ sile-ẹjọ. Gbogbo igba ti wọn fi n le awọn oniroyin yii ati olootu Tribune kiri lati mu wọn yii, ati gbogbo igba ti wọn mu wọn ti wọn ti wọn mọle ki wọn too gbe wọn dele ẹjọ, ati gbogbo igba ti wọn gbe wọn dele ẹjọ ti wọn n fa ọrọ naa, niṣe ni orukọ iwe naa yoo maa fo soke si i, ti tita rẹ yoo maa pọ si i lojoojumọ, ti awọn ti wọn n tẹ iwe naa yoo si sa lọ pata ti ijọba tabi ọlọpaa ko ni i ri wọn. Okiki nla ti Tribune n ni nidii ija ti wọn n ba Akintọla ja yii jẹ ki iwe naa da bii bibeli fawọn oloṣelu atawọn ọmọlẹyin Awolọwọ ni West, bi ẹlomi-in ko si ri iwe naa ko ni i jẹun, wọn aa maa wa a kiri titi ti wọn yoo fi ri i ni. Iwe naa o ni i dojuti wọn, iroyin gbigbona ni yoo kun inu ẹ bii kinla.

Akintọla waa mọ, awọn ti wọn si yi i ka naa mọ, pe pẹlu iwe iroyin Tribune yii niluu Ibadan, yoo ṣoro gan-an foun lati le wọle ibo ti wọn fẹẹ di lọdun 1964, nitori iwe naa yoo ti ba tawọn jẹ kọja ilaji, debii pe ti awọn eeyan ba ri oun, tabi ti wọn ba gbọ orukọ ẹgbẹ awọn nibi kan, wọn yoo maa ju awọn loko, tabi ki wọn maa ṣepe fawọn ni. Nigba to si jẹ oniroyin loun naa tẹlẹ ko too di lọọya ati oloṣelu, lati da iwe iroyin silẹ ko le, lẹsẹkẹsẹ ni wọn si ti bẹrẹ si i ronu eyi ti wọn yoo ṣe. Ohun ti wọn fi da iwe iroyin Sketch silẹ niluu Ibadan niyẹn. Ṣugbọn ki i ṣe Ibadan ni wọn ti bẹrẹ rẹ, Eko ni wọn ti kọkọ bẹrẹ, ninu oṣu kẹta, ọdun 1964 ni wọn bẹrẹ si i tẹ ẹ jade ninu ile nla to jẹ ti ijọba West, iyẹn Investment House. Eko ni ile naa wa, ọfiisi kekere kan ni wọn si fun wọn nibẹ ti wọn fi n gbe iwe iroyin naa jade.

Bawọn oloṣelu West ti ri i ni ọrọ di wahala, wọn binu, koda iwe iroyin Tribune naa faraya, wọn ni owo ijọba ni Akintọla fẹẹ fi da beba silẹ. Ṣugbọn Akintọla naa ko kuku sọ pe ki i ṣe owo ijọba, nigba ti ko pe ileeṣẹ naa ni tirẹ, ileeṣẹ ijọba West ni, ijọba West lo fẹẹ ni iwe iroyin tiwọn, ki i ṣe iwe iroyin Akintọla. Ṣugbọn ẹni to ni ẹlẹdẹ naa lo labule, ko sẹni ti ko mọ pe ohun to ba jẹ ti ijọba West, ti Akintọla naa ni, nigba to jẹ oun lolori ijọba, yoo si ṣoro fun iwe iroyin ti wọn fi owo ijọba da silẹ lati maa ṣọta ijọba gẹgẹ bi Tribune ṣe n ṣe. Awọn ọmọ ẹgbẹ AG ti wọn jẹ aṣofin tiẹ binu, wọn gbe ọrọ naa lọ sile-igbimọ, wọn ni ki Akintọla ma na iru owo bẹẹ, ṣugbọn ọkunrin naa ni fun idagbasoke ipinlẹ awọn ni, oriire lo jẹ lati ni iwe iroyin ni West, nitori yoo pese iṣẹ fawọn eeyan, yoo si tun jẹ ki gbogbo aye maa gbọ ohun to ba n lọ lọdọ awọn.

Bi iwe iroyin yii ti bẹrẹ iṣẹ ni kaluku ti mọ ibi to n lọ loootọ, wọn si ti mọ pe olugbeja Akintọla de ni, ohun ti ọgbẹni naa si ṣe funra rẹ to jẹ nnkan agbayanu niyẹn. Lati igba ti iwe naa ti bẹrẹ si i jade ninu oṣu kẹta, ọdun 1964 yii, ni nnkan ti yipada fun Akintọla, nitori nigba ti Tribune ba bu ijọba rẹ, Sketch ni yoo da wọn lohun, bi wọn ba si purọ kan mọ Akintọla, Sketch ni yoo ja a, tabi bo ba jẹ Akintọla funra rẹ lo ni irọ nla kan ti yoo ju lulẹ, inu Sketch yii ni yoo ju kinni naa si, ko si sẹni ti yoo le ja a bọrọ. Owo gidi wa lọwọ ileeṣẹ naa, nigba to jẹ ileeṣẹ ijọba ni, eyi jẹ ki awọn oṣiṣẹ pọ lọdọ wọn, awọn oniroyin pọ nibẹ ju ti Tribune, bẹẹ ni atẹjade iwe wọn naa mọlẹ nitori ẹrọ igbalode ni wọn fi n tẹ kinni naa jade. Eleyii jẹ ki iwe naa di ọrẹ awọn eeyan ijọba, awọn ọrẹ Akintọla nilẹ Hausa si fẹran rẹ si i.

Bi awọn ti wọn n ka Tribune ṣe le ku nitori Ọbafẹmi Awolọwọ, bẹẹ ni awọn ti wọn n ka Sketch nikan naa le ku nitori Ladoke Akintọla, ko si irọ ti eeyan ko le ba pade nibẹ, ko si si ootọ ọrọ nipa Akintọla ati ijọba rẹ ti ko ni i si nibẹ. Bi Akintọla ba ṣe kinni kan ti ko dara, awọn aa gbe e pe o daa, wọn aa si sọ idi to fi dara. Nigba tọrọ sẹnsọ n gbona ti Akintla ni sẹnsọ naa ni wọn yoo fi ṣeto idibo, iwe yii lo bẹrẹ alaye pe iṣọkan Naijiria l’Akintọla n wa, ọna kan naa ti a si fi le ni iṣọkan ni ki a gba sẹnsọ yii wọle. Iwe naa lo ṣalaye pe Akintọla mọ ohun to n ṣe, nitori bi Yoruba yoo ṣe jẹ nọmba waanu lo n ba kiri, ko si le ṣe eyi bi ko ba jẹ iṣọkan wa nilẹ Yoruba, ki Yoruba si ba awọn ẹya to ku ni Naijiria ṣe. Iwe naa ni Akintọla ko fẹẹ ba awọn Ibo ṣe mọ nitori tara wọn nikan ni wọn mọ, iyẹn lo ṣe fẹran awọn Hausa.

O si fẹran wọn loootọ o, nitori ko fi bo rara pe ti Sardauna lawọn n ṣe. Bi Sardauna ba rin irin kan, inu iwe Sketch yii ni ẹ o ti kọkọ ri i. Ijọba ibilẹ l’Akurẹ nigba kan ja pẹlu ijọba Akintọla, ijọba si ni awọn yoo pa ijọba ibilẹ naa rẹ, n lawọn onijọba ibilẹ ba sare lọ si kootu, wọn ni ki wọn ma gba Akintọla laaye ko pa ijọba ibilẹ awọn rẹ, nitori nibẹ ni awọn ti n ri idagbasoke awọn. Ile-ẹjọ naa ṣi n ba ọrọ naa lọ, wọn ko ti i dajọ, nigba ti awọn ẹgbẹ Action Group kọwe si Balewa pe ko ma jẹ ki Akintọla ṣe bo ṣe fẹẹ ṣe, awọn bẹ ẹ ko da si ọrọ naa, nitori bi Akintọla ba ṣe bo ṣe fẹẹ ṣe yii, yoo ba nnkan jẹ ni o, ijaagboro ati wahala ti yoo mu ẹmi awọn eeyan lọ si le tori ọrọ naa bẹ. Wọn ni iyẹn lawọn ṣe n sọ fun Balewa o, nitori oun lolori ijọba Naijiria lapapọ, aṣẹ to ba pa lagba, ko tete ba awọn da si i.

Ọrọ naa di ibinu fun Sketch, wọn si n wadii pe kin ni idi ti awọn AG yoo fi kọwe si Balewa, wọn ni ki wọn waa ṣalaye ki awọn gbọ. Wọn ni nigba wo ni wọn di ọrẹ Balewa, pe ṣe wọn n pe araalu ni omugọ ni abi ti kin ni. Wọn kọ ọrọ naa sinu ọrọ olootu wọn ni o, wọn ni iyẹn ni pe ẹgbẹ Action Group mọ pe Balewa ni olori ijọba Naijiria, wọn ni awọn ko mọ pe ẹgbẹ naa mọ rara. Wọn ni ṣebi tẹlẹ, “Mọla Ajẹgooro” ni wọn n pe Balewa, ti wọn yoo si maa sọ pe ọkunrin naa ko mọ nnkan kan, “Kin ni mọla mọ!” Sketch waa n beere lọwọ awọn AG pe ṣe wọn ti waa gba pe mọla mọ mẹwaa bayii abi wọn o ti i gba, awọn ni wọn ṣa n lọọ dobalẹ bẹ mọla yii, ki lo tun waa ku laye wọn ti wọn n ba kiri. Ọrọ naa le ju bẹẹ lọ, nitori iwe iroyin naa sọrọ si wọn yankanyankan ni, ẹni to ba si fẹran Akintọla yoo fẹran ohun ti iwe naa n kọ.

Nigba ti yoo fi to oṣu mẹfa ti iwe naa bẹrẹ iṣẹ, iwe iroyin ọhun ti ri ẹsẹ mulẹ daadaa, bo si tilẹ jẹ pe iwe iroyin Dẹmọ ni wọn n pe e, nitori ko sẹni to pe e ni iwe iroyin Western Region, sibẹ, iwe naa ba ohun to n lọ mu, nitori o ṣiṣẹ rẹpẹtẹ fun ijọba Akintọla, o si gba Akintọla lọwọ Tribune to doju ija kọ ọ. Awọn ti wọn ba fẹ ti Awolọwọ ko ni i de ọdọ awọn Sketch, nitori wọn mọ pe inu awọn yoo bajẹ kuro nibẹ ni. Awọn iroyin ti wọn yoo ka nibẹ ko ni i ba idunnu wọn pade, bii ki wọn ni awọn kinni kan to ṣẹṣẹ bajẹ bayii, Awolọwọ lo ba a jẹ lati ẹwọn, tabi pe ko too lọ sẹwọn lo ti ba a jẹ, ati awọn irọ nla nla bẹẹ. Bi wọn ba si wadii ọrọ naa lọ ti wọn wa a bọ, bi ki i ba i ṣe Akintọla lo sọ ọ, aa jẹ ọka ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ ni. Ṣugbọn ọrọ naa yoo dun mọ awọn tiwọn ninu, nitori ohun ti wọn fẹẹ gbọ ni Sketch n gbe jade.

Ẹni to ba si fẹ ti Akintọla naa ko ni i ta si isọ Tribune o, nitori bi oun naa ba ka awọn ohun ti iwe naa yoo gbe jade, tọhun le ni ẹjẹ-riru bi ki i baa ṣe ẹni to lọkan daadaa. Wọn yoo sọ awọn owo nla nla kan ti Akintọla ati awọn eeyan rẹ bii Ọba Akran n ko jẹ, ati awọn ohun mi-in ti wọn n ṣe fun ipalara ilẹ Yoruba lapapọ. Bi awọn ti wọn si fẹ ti Awolọwọ ba ti n ka kinni naa to ni inu yo maa run wọn to, wọn yoo fẹẹ mu Akintọla ki wọn si ti i mọle, tabi ki wọn ṣe e leṣe kan. Eyi ni pe bi ogun awọn oloṣelu ti n lọ lọwọ, bẹẹ ni ogun awọn iwe iroyin meji yii bẹrẹ n’Ibadan, Sketch ati Tribune, ogun naa si le. Ṣugbọn Akintọla ni anfaani kinni naa wa fun ju, oun naa ti ni iwe iroyin bayii, ijọba rẹ ti ni agbẹnusọ, ko sẹnikan ti yoo ba a lenu mọ, tabi ẹni ti yoo gbe ọrọ to ba sọ pamọ, bi ibo si ti n sun mọ ni inu rẹ n dun, o ti mọ pe Sketch wa nibẹ ti yoo gba oun.

 

(30)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.