Nitori ọrọ hijaabu, wọn ti ileewe ISI pa n’Ibadan

Spread the love

Nitori ọrọ hijaabu to ti n fi ileewe naa logbologbo lati ọsẹ to kọja, awọn alaṣẹ ileewe girama The International School (ISI),to wa ninu ọgba Fasiti Ibadan, n’Ibadan ti ti ileewe naa pa.

Igbesẹ yii waye nitori iwọde alalaafia ti awọn obi musulumi to lọmọ nileewe ISI ṣe lọ si ẹnu ọna abawọle ileewe naa laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ana.

Bo tilẹ jẹ pe ọrọ hijaabu to fa wahala yii ko ṣẹṣẹ bẹrẹ, o pẹ ti awọn ọmọbinrin musulumi kan ti fẹ maa bori lọ sileewe,ṣugbọn tawọn ọga wọn ko gba wọn laaye, lọjọ Mọnde ọsẹ to kọja lọrọ ọhun di nnkan nla nigba ti awọn obi awọn ọmọbinrin musulumi kan lo hijaabu lọ sileewe, ti awọn obi wọn naa si tẹle wọn lọ.

Ṣugbọn awọn ọmọ to n lo hijaabu yii ko tori ẹ pa hijaabu lilo ti,eyi to tubọ run awọn alaṣẹ ileewe wọn ninu, n lọgaa ileewe naa ba ranṣẹ pe gbogbo wọn lọfiisi ẹ, lo ba ni ki wọn ko wọn lọ si yara ikawe, ni wọn ba tilẹkun mọ wọn sibẹ titi di asiko ti wọn jade ile.

Lara awọn to fara mọ atako ti awọn ọga ISI ṣe fun ọrọ hijaabu yii ni ẹgbẹ awọn akẹkọọ to ti jade nileewe ọhun sẹyin. Wọn niawọn paapaa fara mọ ki awọn alakooso ileewe yii ma fi oju ẹsin kankan wo ọrọ yii, ofin ati ilana ti wọn ba n lo nibẹ nikan ni ki wọn maa lo lọ.

Aarẹ ẹgbẹ naa, Tive Ekpere, sọ pe bi wọn ba n faaye gba ki awọn akẹkọọbinrin musulumi maa bori, bii igba ti wọn kan ba aṣa ati iṣe ti wọn ti n ṣamulo nileewe naa lati nnkan bii ọdun marundinlọgọta (55), sẹyin ti wọn ti da a silẹ jẹ ni.

Ṣugbọn ẹgbẹ awọn obi awọn akẹkọọ ti wọn jẹ musulumi nileewe ISI sọ pe ko si ibi to wa ninu iwe ofin ileewe ọhun pe akẹkọọ wọn ko gbọdọ lo hijaabu.

Ninu ipade oniroyin ti wọn ṣe lỌjọruu, Wẹsidee, to kọja, wọn ni ọpọ igba lawọn ti kọ lẹta si awọn alaṣẹ Fasiti Ibadan ati awọn alakooso ileewe ọhun gan-an funra wọn, ṣugbọn ti ko sẹni to fesi rara ninu wọn, ati pe o pẹ ti awọn alaṣẹ ileewe ọhun ti n yan awọn musulumi jẹ pẹlu bi wọn ṣe kọ lati gba olukọ imọ ẹsin Islam fun wọn, ti wọn si gba olukọ to n kọ wọn lẹkọọ Bibeli, to jẹ pe obi kan to jẹ musulumi lo gba olukọ to n kọ wọn lẹkọ imọ Kuraani, to si n sawooṣu fun un lapo ara ẹ.

Alaga ẹgbẹ awọn obi akẹkọọ musulumi ileewe ISI, Alhaji Abdulrahman Balogun, sọ pe o ṣe ni laaanu pe lọjọ ti ipade obi atawọn olukọ ISI waye lẹyin ti ọrọ onijaabu de bẹrẹ yii, niṣe lawọn kirisitẹni lọ pe ara wọn jọ rẹpẹtẹ wa sipade naa, ti gbogbo wọn si n tako iwọnba musulumi to wa nipade ọhun to bẹẹ ti wọn ko fun wọn lọrọ kankan sọ.

O ni o ya oun lẹnu pe awọn olukọ ileewe naa le ti awọn ọmọ mọle nitori pe wọn bori ara wọn, paapaa nigba to ṣe pe awọn oyinbo ti wọn mu ẹkọ iwe ati ẹsin igbagbọ wọ orileede yii paapaa faaye gba awọn obinrin ọlọpaa ati gbogbo obinrin musulumi lati maa wọ hijaabi lori aṣọ iṣẹ wọn.

Bakan naa ni akọwe agba ijọ awọn musulumu ni ipinlẹ Ọyọ, Imam Ismail Busayri, rọ ileegbimọ aṣofin apapọ nilẹ yii lati gbe igbesẹ lori ọrọ yii lọna ti ẹnikẹni ko ṣe tun ni i maa di awọn obinrin musulumi lọwọ lati maa mura ni ibamu pẹlu aṣẹ Ọlọrun wọn.

Lẹyin ti wọn ti fi ọsẹ kan fa ọrọ hijaabu yii ti ko ni iyanju, awọn obi musulumi tun ṣe iwọde alalaafia lọ si ẹnu ọna abawọle ISI ni nnkan bii aago meje aabọ aarọ ana pẹlu akọle oriṣiiriṣii lọwọ to ni i ṣe pẹlu idi to ṣe yẹ ki wọn gba awọn ọmọ wọn laaye lati maa lo hijaabu.

Eyi lo mu ki awọn alaṣẹ sukuu ọhun lẹ iwe si ẹnu abawọle ileewe naa pe awọn ti gbe ISI ti pa, wọn ni awọn yoo pe wọn nigba ti asiko ati wọle ba to.

Lẹyin iṣẹju diẹ sigba naa lawọn obi bẹrẹ si i lọ mu awọn ọmọ wọn kuro, ti ọpọ ninu awọn obi ti wọn jẹ kirisitẹni si n binu, wọn ni ki lo de ti wọn fi ọrọ ti ko kan awọn lọwọ lẹsẹ pa awọn ọmọ awọn lara.

Igbakeji ọga agba Fasiti Ibadan, Ọjọgbọn Yinka Aderintọ, lọ sibẹ lati fi awọn obi to n binu yii lọkan balẹ, o ni nitori ki ọrọ naa ma baa la itajẹsilẹ lọ lo mu ki awọn ti ileewe naa pa fun igba diẹ ati pe ọrọ naa ko ni i pẹ yanju patapata.

Ọga agba ileewe Fasiti Ibadan, Ọjọgbọn Abel Ọlayinka, paapaa lọ sibẹ lẹyin ti gbogbo ẹ ti rọlẹ tan lati mọ bi nnkan ṣe ri.

Ijọ awọn musulumi ni ipinlẹ Ọyọ ti pinnu lati gbe igbimọ alakooso ISI lọ si kootu bayii gẹgẹ bi Alhaji Balogun ti i ṣe alaga ẹgbẹ awọn obi akẹkọọ musulumi ileewe naa ṣe fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin.

(18)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.