Nitori Keresi ati ọdun tuntun, awọn ọlọpaa ya bo oju popo nipinlẹ Ogun

Spread the love

Ọdun Keresimesi to ku ọla yii, ati ọdun tuntun to ku ọjọ diẹ ko waye ti mu ki ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun da awọn agbofinro sita lati dena awọn ẹni ibi ti wọn ba fẹẹ lo asiko naa lati da wahala silẹ, wọn ni ẹni tọwọ ba tẹ pẹlu iwa arufin ko ni i ṣọdun naa ni gbangba.

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Iliyasu Ahmed, to da awọn ọlọpaa sita ṣalaye ninu atẹjade ẹ pe awọn iwa ọdaran bii ijinigbe, ole jija, idaluru pẹlu wahala awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn fẹẹ kapa ẹ. O ni nitori asiko tawọn eeyan n ṣe pọpọṣinṣin ọdun lawọn oniṣẹ ibi maa n yọju lairo tẹlẹ.

Bo ṣe jẹ pe gbogbo ile ijọsin ni wọn ni ibudo ipagọ nipinlẹ Ogun, to jẹ awọn Ridiimu, Deeper Life, Mountain of Fire, Nasfat atawọn Sẹlẹ to n lọ si Imẹkọ yoo wa nipinlẹ Ogun lasiko yii lati gbadura ọdun, ọga ọlọpaa sọ pe aabo to peye gbọdọ wa fun ẹmi ati dukia wọn.

Bi ẹnikẹni ba waa fẹẹ lo akoko naa lati huwa arufin, wọn ni awọn ti ṣetan lati palẹ tọhun mọ, to jẹ ko ni i foju ba ode fọjọ gbọọrọ. Bakan naa ni wọn rọ awọn araalu naa pe ki wọn ma dakẹ, bi wọn ba kofiri iwa to mu ifura dani lagbegbe wọn, ki wọn tete fi to teṣan ọlọpaa to ba wa nitosi leti, iyẹn yoo ran iṣẹ aabo lọwọ lasiko, ijamba to ba fẹẹ ṣẹlẹ yoo si ṣee dena.

 

 

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.