Nitori isele idigunjale to gbemi eeyan repete l’Offa Ọkan awọn araalu ko ti i bale

Spread the love

Titi di ba a ṣe n sọ yii, jinnijinni iṣẹlẹ to ṣẹlẹ niluu Ọffa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, nibi tawọn adigunjale ti ya wọ ilu naa, ti wọn si da ọpọlọpọ ẹmi legbodo lasiko ti wọn fẹẹ digun ja awọn banki nla nla kan niluu naa ko ti i kuro lara tọmọde tagba ilu ọhun. Inu ọfọ nla si ni mọlẹbi ọpọ awọn to faragba nibẹ ṣi wa di ba a ṣe n sọ yii.

Ko sẹni to fura pe iru nnkan bẹẹ yoo ṣẹlẹ niluu ọhun ti onikaluku fi gba ibi iṣẹ oojọ rẹ lọ, bẹẹ ni awọn to ku yii naa dagbere fun awọn ẹbi wọn pẹlu ireti ati pada wale waa ba wọn lẹyin iṣẹ oojọ wọn, ṣugbọn ọrọ ko ri bi wọn ṣe ro o, nitori ọpọ ninu wọn lo ti oko iwajẹ wọn dero ọrun, awọn mi-in rin arinfẹsẹsi ni wọn fi dẹni to n ku iku ibọn.

Ni nnkan bii aago maarun kọja ogun iṣẹju irọlẹ niṣẹlẹ aburu yii ṣẹlẹ, ti awọn adigunjale ya bo ilu naa, ti wọn si morile awọn banki bii marun-un to wa nitosi ara wọn laduugbo ọja Owode, niluu naa. Awọn banki naa ni Union Bank, Zenith Bank, Guaranty Trust Bank Eco Bank ati Ibolo Micro finace Bank.

(32)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.