Nitori ijamba ọkọ, FRSC gbena woju awọn awakọ to n ru ofin

Spread the love

Ajọ ẹṣọ oju popo ilẹ yii ti kede pe ko ni i si aaye fawọn awakọ to n ru ofin mọ pẹlu bi awọn yoo ṣe maa fọwọ lile mu wọn. Nibi eto ti wọn pe ni ‘Safe Driving Saves Lifes’ ti wọn fi polongo bi ijamba ọkọ yoo ṣe dinku ni ọga-agba ajọ naa, Bọboye Oyeyẹmi, ti sọ ọ di mimọ niluu Ado-Ekiti lopin ọsẹ to kọja. O ni gbogbo ọna lawọn yoo gba lati din ijamba ọkọ ipari ọdun ku.
Iwadii ALAROYE fi han pe laarin oṣu kẹsan-an si oṣu kẹwaa, ọdun to kọja, ijamba ọkọ to sun mọ ẹgbẹrun mẹta (2,805), lo waye kaakiri ilẹ yii, awọn to si padanu ẹmi wọn le ni ẹgbẹrun kan aabọ (1, 602). Bakan naa lo jẹ pe awọn ti ijamba naa kan le ni ẹgbẹrun lọna ogun (20, 196), mọto to si fara gba le ni ẹgbẹrun mẹrin (4, 503).
Eyi lo jẹ ki Bọboye paṣẹ pe ki ajọ yii bẹrẹ ayẹwo oju fawọn dẹrẹba, ki wọn le mọ awọn ti oju wọn ko ṣe deede fun ọkọ wiwa, bẹẹ lo beere fun ifọwọsowọpọ gbogbo awọn ti ọrọ kan.
‘’Awọn eeyan maa n sọ pe gbogbo oṣu ba-ba nijamba maa n waye nitori awọn ẹmi buruku to maa n jade soju popo, ṣugbọn ko si nnkan to jọ bẹẹ, afọwọfa ni ijamba.
‘’Bi ọpọ ṣe n rin irin-ajo lati lọọ ba awọn eeyan wọn lawọn dẹrẹba naa fẹẹ ṣiṣẹ karakara lati pa owo sapo, eyi ti ki i jẹ ki wọn sinmi daadaa. Eyi ati aibikita lo maa n saaba fa ijamba.
‘’ Bakan naa ni ikọ ‘Operation Cobra’ yoo tun ṣiṣẹ takuntakun si i lati dẹkun awọn to n ru ofin irinna nipa mimu ọti, lilo foonu atawọn iwa ọdaran mi-in.’’

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.