Nitori ija ojoojumọ, Alia fẹẹ kọ ọkọ rẹ ni Ṣaki

Spread the love

Kootu kọkọ-kọkọ to wa laduugbo Sango, niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, ti bẹrẹ igbẹjọ lori ẹsun ti Abilekọ Adulwahab Alia, ẹni ogun ọdun, mu wa si ile-ẹjọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, nibi to ti rọ wọn pe ki wọn tu ibaṣepọ ọlọdun mẹrin to wa laarin oun pẹlu ọkọ oun, Moroof Almisky, ka, o loun ko nifẹẹ rẹ mọ.
Alia ṣalaye ni kootu sọ pe ọmọ bibi ilu Ṣaki
lawọn obi oun, ṣugbọn ilu Kamba, nipinlẹ Zamfara, ni wọn bi oun si. O ṣalaye pe ọdun mẹta sẹyin toun pada wa si Ṣaki loun pade Moroof nipasẹ aburo baba oun to n jẹ Aolat. Obinrin naa sọ pe latigba naa ni ko ti si alaafia laarin awọn, ojoojumọ lawọn maa n ja. O ni koun ma baa ku iku ojiji loun fi ko diẹ ninu ẹru oun kuro nile ọkọ oun.

Ṣaaju ni ile-ẹjọ ti kọkọ fun Moroof ni iwe-ipẹjọ, ṣugbọn ọmọkunrin naa kọ lati yọju. Adajọ kootu naa, Oloye Muritala Ọladipupọ, paṣẹ pe ki obinrin to ṣe alarina laarin Alia ati Moroof, iyẹn Aolat Abdullahi, yọju si kootu lọsẹ yii. O ni lẹyin naa loun yoo too gbe idajọ kalẹ.

 

 

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.