Nitori ija awọn Musulumi ati awọn Ẹlẹsin ibilẹ, Asẹyin fẹẹ gbe igbimọ kalẹ

Spread the love

Aṣẹyin tilu Iṣẹyin, Ọba AbdulGaniyu Adekunle Salau, ti ṣeleri lati gbe igbimọ kan dide ti yoo wa ojutuu si ija ẹsin to maa n saaba waye laarin awọn ẹlẹsin Musulumi atawọn ẹlẹsin Ibilẹ ni agbegbe naa.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, ni Asẹyin sọ eleyii lasiko ayẹyẹ ajọdun idasilẹ Ẹbẹdi Iṣẹyin, eyi to waye nileewe ẹkọṣẹ to wa niluu naa.
Ayẹyẹ naa ti i ṣe ẹlẹẹkejidinlọgbọn iru rẹ ni Ọba naa ti ni oun yoo gbe igbesẹ lori ileri ti oun ṣe yii. O ni ko si ẹsin kankan to faaye gba wahala, bẹẹ ko si bi idagbasoke ṣe le wa niluu ti ko ba si alaafia.
Lasiko ọdun oro to waye laipẹ yii ni awọn kan kọlu awọn ẹlẹsin Musulumi nibi ti wọn ti n ṣe waasi, ti awọn eeyan si farapa yannayanna nibi iṣẹlẹ naa.

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.