Nitori igba Naira, Mayọwa gun ọrẹ rẹ pa l’Ekoo

Spread the love

Kootu majisreeti to wa ni Ebutte-Mẹta, niluu Eko, ni awọn ọlọpaa taari ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn kan, Mayọwa Ọlabiyi, si, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ẹsun ti wọn si fi kan an ni pe o ṣeku pa ọrẹ rẹ nitori igba Naira.

Ẹsun igbimọ-pọ lati huwa ọdaran, ati iṣekupaniyan ni wọn fi kan an niwaju Adajọ O.O Ọlatunji. Agbefọba to n rojọ tako o niwaju adajọ, Ọladele Adebayọ, sọ pe ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu to kọja, ni olujẹjọ huwa naa lojule kẹtalelogun, Irepọdun, Shangisha, ni Magodo.

O ni Mayọwa pẹlu awọn meji mi-in ti wọn ti fẹsẹ fẹ ẹ bayii gbimọ-pọ,  wọn si ṣa Akeem Ajilogba, ẹni ọdun mẹtalelogun pa, nibi ti wọn ti n ba a ja si igba Naira.

Ẹsun naa tako abala igba le ni mẹtalelogun ati igba le ni mẹtalelọgbọn, iwe ofin to de iwa ọdaran ti ipinlẹ Eko n ṣamulo, tọdun 2015.

Adajọ Ọlatunji ni kootu naa ko laṣẹ lati gbọ ẹbẹ Mayọwa. O ni ki wọn maa mu un lọ si ọgba ẹwọn Ikoyi, to wa niluu Eko. O ni ki wọn ṣẹda iwe ẹsun rẹ ṣọwọ si ẹka to n gba adajọ nimọran fun amọran lori ẹsun rẹ. Ọjọ kọkanla, oṣu kẹwaa, lo sun igbẹjọ mi-in si.

(18)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.