Nitori idibo piramari: Wọn da alaga ẹgbẹ APC duro l’Ọṣun

Spread the love

Pẹlu bi idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun ṣe ku ọjọ meji bayii, ara o rokun, ara o rọ adiyẹ lọrọ da laarin awọn aṣaaju ẹgbẹ naa pẹlu awọn alaga ijọba ibilẹ, to fi mọ awọn ọmọ ẹgbẹ kaakiri. Ohun to n fa wahala naa o ṣẹyin bi wọn ṣe fi ẹsun kan alaga ẹgbẹ naa, Ọmọọba Gboyega Famọdun, pe o sọ ara rẹ di ọlọrun-kekere ninu iwa ati iṣe rẹ. Laaarọ ana, Mọnde, ni mọkanla ninu awọn mẹrindinlogun ti wọn jẹ igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọṣun kede pe ki Famọdun ati akọwe rẹ, Alhaji Rasaki Salinsile, lọọ rọọkun nile.

Ninu atẹjade kan ti oludamọran lori ọrọ ofin fun ẹgbẹ naa, Barista Goke Ogunsọla, ka fawọn oniroyin ni wọn ti fi oriṣiiriṣii ẹsun kan Famọdun. Wọn ni alaga yii lo da kọ lẹta si awọn igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ l’Abuja pe ilana eto elero pipọ (delegates) lawọn yoo lo fun idibo piramari lọjọ Tọsidee, ọsẹ yii. Ogunṣọla ni ko sibi kankan tigbimọ alaṣẹ ẹgbẹ ti jokoo ṣepade pọ lori lẹta naa, eleyii to tumọ si pe iwa magomago kan wa ti Famọdun atawọn aṣaaju kan ninu ẹgbẹ naa fẹ hu.

O ni ilana eto ninu eyi ti awọn aṣoju yoo ti dibo fun oludije ti wọn ba fẹ ni wọn ṣe nipinlẹ Ondo, Ekiti, Edo ati bẹẹ bẹẹ lọ, ki lo wa n ba Famọdun lẹru bi ki i baa ṣe pe ẹbọ wa lẹru ẹ. Kia ni wọn kede igbakeji alaga, Alhaji Issa Azeez Adesiji, gẹgẹ bii adele alaga ati igbakeji akọwe, Rasheed Bakare Idẹra gẹgẹ bii adele akọwe bayii, wọn ni awọn ko nigbagbọ ninu Famọdun ati akọwe rẹ mọ.

Bakan naa ni alaga awọn alaga ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Rufus Awotidoye, sọ fun Alaroye pe iwa ailoootọ lo n koba awọn aṣaaju ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọṣun, o ni onilu ko ni i fẹ ko tu, idi niyẹn tawọn ko fi ni i faaye gba ẹnikẹni lati ba ẹgbẹ APC jẹ fawọn.

Latari idi eyi, Awotidoye ni mẹẹẹdọgbọn ninu awọn mọkanlelọgbọn ti wọn jẹ alaga kansu l’Ọṣun ti fi iwe ẹhonu sọwọ si Abuja lati le jẹ ki awọn alaṣẹ mọ pe adabọwọ ni nnkan ti Famọdun ṣe, ati pe ko bun ẹnikankan gbọ to fi n buwọ luwe lorukọ awọn igbimọ ẹgbẹ.

O ni Famọdun ti mọ pe awọn aṣoju ti wọn ba wa lati Abuja fun idibo naa ko ni i lanfaani lati de gbogbo wọọdu to le ni ọọdunrun to wa nipinlẹ Ọṣun, idi niyẹn to fi sọ pe ilana idibo yẹn loun fẹ lati le ṣegbe lẹyin oludije kan to ni lọkan.

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.