Nitori idibo ọdun to n bọ, PDP wa iranlọwọ lọ sọdọ Ọbasanjọ

Spread the love

Lọjọ Abamẹta, Satide, ijẹrin yii, igbimọ ẹlẹni mọkanlelogun kan ṣabẹwo si Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ niluu Abẹokuta, iyẹn ninu ọgba OOPL. Awọn abẹnugan ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn n fẹ atilẹyin aarẹ tẹlẹ naa ki wọn le rọwọ mu ninu idibo ọdun to n bọ ni.

Alaga apapọ fẹgbẹ PDP lorilẹ-ede yii, Uche Secondus, lo ṣiwaju ikọ naa, bẹẹ ni alaga igbimọ olufọkantan, Walid Jibrin, naa ko gbẹyin pẹlu awọn igbimọ apapọ amuṣẹṣe(National Working Commitee).

Aforiji lawọn eeyan naa kọkọ tọrọ lọwọ Ọbasanjọ ti wọn ti jọ wa tipẹ ki baba naa too fa kaadi ẹgbẹ PDP ya lọdun 2014, to loun ko ba wọn ṣe mọ.

Alaga apapọ PDP ni awọn waa bẹ baba naa pe ko ma binu fawọn iwa ti ẹgbẹ awọn ti hu si lai daa ni.

Ohun keji ti wọn lawọn tori ẹ wa ni pe nnkan ko lọ deede lorilẹ-ede yii. Wọn tun ni ko bawọn ri si ọrọ ajọsọ to ni i ṣe pẹlu bawọn ẹgbẹ oṣelu ṣe n parapọ ti wọn n di ọkan ṣoṣo,(MOU) ( Coalition of United Political Parties.)

Ohun ti wọn fi kadii ẹ nilẹ ni pe awọn ko fẹ ki ọrọ Naijiria su u, ko ma pa a ti, niṣe ni ko maa pese awọn idanilẹkọọ ati amọran to le mu aṣeyọri wa, ti yoo si gba wa lọwọ awọn oṣelu alajẹbanu.

Agbekalẹ wọn naa ni Ọbasanjọ fesi si pe oun dupẹ bi wọn ṣe wa, o loun tun dupẹ pe wọn tọrọ aforiji lọwọ oun.

Lori ajọsọ ẹgbẹ oṣelu ti wọn n parapọ di ọkan ṣoṣo, aarẹ tẹlẹ naa ṣalaye pe ki i ṣe lati gbe ẹgbẹ kan gori awọn yooku, bi ko ṣe ifẹnuko awọn eeyan ti ero ọkan wọn papọ, ti wọn si gba lati jọ ṣiṣẹ pọ labẹ orule ẹgbẹ kan ṣoṣo.

O ni iru ẹ ni ti CNM toun da silẹ, ti wọn tẹwọ gba ADC, ẹgbẹ toun n ṣatilẹyin fun, toun si ti pinnu pe boun yoo tiẹ tun ran ẹgbẹ oṣẹlu mi-in lọwọ, ko le to ti ADC laye.

Oloyẹ Ọbasanjọ fi kun un pe oun ti pinnu lati ran ẹgbẹ to ba beere fun amọran lọwọ, ṣugbọn bakan naa loun ti ṣẹleri pe oun ko ni i darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu kankan.

Lati tun orukọ PDP to ti ni abawọn ṣe, Ọbasanjọ gba wọn niyanju lati ma ṣe tẹti si wọn ni wọn pe, o ni ki wọn yago fun ibara ẹni lorukọ jẹ ati iditẹ mọra ẹni.

Ẹbọra Owu waa fi da wọn loju pe oun ko ni i dakẹ, oun yoo maa mu imọran to le yọ Naijiria loko ẹru awọn oṣẹlu buruku wa nigba gbogbo.

Abẹwo yii lawọn to n wo ṣaakun oṣelu ti sọ pe nitori ohun meji kọ, wọn ni ẹgbẹ PDP n wa bi wọn yoo ṣe fa oju Ọbasanjọ mọra ko le tun darapọ mọ wọn ni.

(79)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.