Nitori idibo abele: Minisita ati gomina ipinlẹ Ọyọ bẹrẹ ija tuntun, Akala, Makinde paapaa ti da si i

Spread the love

Pẹlu bi anfaani lati gba fọọmu idije dupo gbogbo lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC ninu idibo ọdun 2019 ti ṣe wa sopin lọjọ Aje, Mọnde ana, minisita fun eto ibanisọrọ lorileede yii, Amofin Adebayọ Shittu, ati Ọtunba Adebayọ Alao-Akala to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Ọyọ ti pinnu lati koju ara wọn ninu ija oṣelu lati dupo gomina ipinlẹ Ọyọ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Igbesẹ yii ni yoo mu ki gomina ipinlẹ Ọyọ ati minisita ijọba apapọ lati ipinlẹ yii bẹrẹ ija wọn lakọtun pẹlu bo ṣe jẹ pe igun meji ọtọọtọ ti wọn da bii ata ati oju ti ki i ṣọrẹ ara wọn lawọn mejeeji wa ninu ẹgbẹ oṣelu wọn.

Ẹẹmeji ọtọọtọ ni Shittu ati Ajimọbi ti koju ara wọn ninu idije dupo gomina ipinlẹ Ọyọ, ṣugbọn ti Ajimọbi fagba han an lẹẹmejeeji. Akọkọ waye lọdun 2011, nigba ti Shittu dije lorukọ ẹgbẹ oṣelu CPC, ti Ajimọbi wọle ibo naa lorukọ ẹgbẹ ACN. Lọdun 2015, awọn mejeeji ba ara wọn inu ẹgbẹ oṣelu kan naa (APC), igba naa gan-an lọta awọn mejeeji tubọ gbona si i pẹlu bi wọn ṣe tun jọ dupo gomina gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, ṣugbọn Ajimọbi, ẹni to dupo ọhun lati ṣe saa keji nipo ọhun tun fẹyin Shittu janlẹ ninu idibo abẹle ẹgbẹ wọn.

Ni kete ti ibo ọhun pari ni Shitu gba kootu lọ, o ni ki wọn le Ajimọbi kuro nipo gomina, ki wọn gbe ipo naa fun oun, nitori idibo ti ẹgbẹ APC fi fa a kalẹ lọwọ kan ojooro ninu. Lẹyin ti Ajimọbi si papa di gomina fun saa keji lẹyin to ti fagba han awọn oludije yooku ninu idibo gomina ọdun naa, Shittu ko jawọ ninu ẹjọ ọhun, afi lẹyin ọpọlọpọ oṣu, nigba ti ọkunrin naa ti di minisita ninu ijọba apapọ ilẹ yii.

Gomina paapaa ko fara pamọ ba minisita ṣọta, nigba ti alakooso orileede yii, Aarẹ Muhammadu Buhari, fi Shittu jẹ minisita, gbogbo ara ni Ajimobi fi tako o, gbogbo ọna to si mọ pata lo gba lati ri i pe Buhari gba ipo naa lọwọ Shittu fun ẹlomi-in ko too di pe awọn eekan nidii oṣelu ba gomina naa sọrọ lati fi minisita tuntun naa lọrun silẹ.

Shittu ko fi bò rara pe oun tun fẹẹ dupo gomina ninu idibo ọdun 2019, bẹẹ l’Ajimọbi paapaa ko fi bò pe oun ko fẹ ẹ nipo naa, bi yoo ba tilẹ ṣe gomina, ki i ṣe minisita yii loun yoo gbe ijọba fun lẹyin ti oun ba pari saa keji oun lori aleefa.

Lọjọ kọkandinlogun, oṣu karun-un, ọdun yii (2018), ti awọn APC dibo yan awọn ti yoo maa ṣakoso ẹgbẹ wọn kaakiri ipinlẹ gbogbo nilẹ yii, ọna meji ni wọn ti dibo ọhun ni ipinlẹ Ọyọ, Gomina Ajimọbi ṣe tiẹ nibi kan, Shittu atawọn eeyan ẹ naa ṣe tiwọn nibomi-in ṣugbọn ibo awọn Shittu ko ja mọ nnkan kan nitori awọn oloye ti awọn Ajimọbi dibo yan sipo nikan lawọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ APC ni Abuja fara mọ gẹgẹ bii oloye ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Ọyọ. Eyi ni gomina fi gba ẹgbẹ mọ minisita atawọn eeyan ẹ lọwọ.

Shittu ja fita fita lati jẹ ki awọn alaṣe ẹgbẹ ni Abuja gba ẹgbẹ APC kuro lọwọ Ajimọbi ni ipinlẹ Ọyọ, ṣugbọn ti awọn yẹn ko tilẹ tẹti gbọ awijare ẹ rara, lẹyin naa lara rọ ọkunrin naa pẹsẹ, ẹnikan ko si gburoo ẹ lori akitiyan ati dupo gomina mọ latigba naa, ibi ti ọrọ naa ja si ti ye e, o mọ pe awọn oloye ẹgbẹ ti Ajimọbi fa kalẹ yii, awọn apapọ ẹgbẹ ni Abuja nikan lo lagbara lati ṣeto idibo lati yan ẹnikẹni ti yoo ba du ipo gomina ati ipo yoowu lorukọ ẹgbẹ naa.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, atilẹyin aarẹ ni Shittu n duro de. Lẹyin ti nnkan ko ṣenuure fun un lati gba akoso ẹgbẹ oṣelu ẹ ni ipinlẹ rẹ, o kọ lẹta si Aarẹ Buhari gẹgẹ bii ọkan ninu awọn minisita to n ba a ṣejọba pe oun fẹẹ dupo gomina ipinlẹ oun, iyẹn si fun un lesi pe ko buru, oun fi adua ran an lọwọ pe ki Ọlọrun wa pẹlu ẹ.

Bi awọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ APC nilẹ yii ṣe kede iye owo ti ẹni ba n dupo ni lati fi gba fọọmu gege bii oludije fun ipo naa lorukọ ẹgbẹ wọn ni Shittu ti ko miliọnu mẹẹẹdọgbọn (N25m) Naira kalẹ, to si gba fọọmu idije dupo gomina.

Miliọnu mejilelogun ataabọ (N22.5m)  gan-an lowo fọọmu fun ọmọ ẹgbẹ APC to ba fẹẹ dupo gomina, ṣugbọn iru ẹni bẹẹ gbọdọ kọkọ fi miliọnu meji aabọ naira (N2.5) gba fọọmu kekere kan na lati kọkọ sọ fun awọn alaṣẹ ẹgbẹ ni ipinlẹ rẹ pe oun nifẹẹ lati dupo gomina, ko too waa ṣẹṣẹ lọọ gba ojulowo fọọmu gan-an ni olu ile ẹgbẹ wọn niluu Abuja. Apapọ owo mejeeji lo jẹ miliọnu mẹẹẹdọgbọn Naira.

Awọn to n gbero lati dupo gomina ipinlẹ Ọyọ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC le lọgbọn (30). Ajimọbi si ṣepade pẹlu wọn lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, o loun fẹẹ din wọn ku si mẹrin pere, ko ma baa di pe ọpọ ninu wọn ni yoo kan fowo ṣofo lasan.

Niwọn igba ti Ajimọbi ko ti fi ibi kankan fẹ Ṣhittu nipo gomina, ko si ọkunrin naa ninu awọn to ranṣẹ pe fun ipade ọhun, Shittu paapaa ko si yọju sibẹ. ALAROYE gbọ pe orileede South Afrika lo tiẹ wa lọjọ naa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii. Ọkunrin naa si ti mura lati ba Ajimọbi ati gbogbo ẹni to ba fa kalẹ lati ba a dupo gomina na an tan bii owo.

Lara awọn ti minisita yii yoo ba figa gbaga ninu idije naa ni Ọtunba Adebayọ Alao-Akala ti i ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri. Ọkan ninu awọn ti Ajimọbi n ti lẹyin lati dupo loun.

Lọpin ọsẹ to kọja yii loun paapaa lọọ gba fọọmu lati dupo gomina ninu idibo ọdun 2019. Wọn lawọn alatilẹyin ẹ ni wọn dawo jọ gba fọọmu fun un.

Awọn mi-in to ti foju han bayii pe wọn yoo figa gbaga ninu pẹlu Shittu ati Akala ninu idibo gomina lọdun to n bọ ti wọn ti gba fọọmu bayii ni Ẹnjinia Ṣeyi Makinde (PDP), Sẹnitọ Fẹmi Lanlẹhin (ADC) ati bẹẹ bẹẹ lọ.

(73)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.