Nitori ibo ọdun to n bọ, Orji Kalu ati Fayoṣe kọju ija sira wọn

Spread the love

 

Bi ibo ipinlẹ Ekiti ṣe n sunmọle, ija oṣelu tun ti gbọna mi-in yọ laarin ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ati All Progressives Congress (APC). Niluu Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, nija naa ti waye lọjọ Aiku, Sannde, ijẹta, nigba ti Orji Uzor Kalu to jẹ agba-ọjẹ APC sọrọ si Gomina Ayọdele Fayoṣe lẹyin ọjọ kan ti gomina ọhun sọko ọrọ si i.

Ṣe ṣaaju ni Ọgbẹni Lere Ọlayinka to jẹ oludamọran pataki fun Gomina Fayoṣe ti sọ pe ki Orji Uzor Kalu to jẹ alaga ikọ to n ja fun ipadabọ Aarẹ Muhammadu Buhari lẹẹkeji ma wọ ipinlẹ naa nitori ipade alaafia to n ṣe kiri ko kan Ekiti, alaafia ti n jọba tẹlẹ.

Gẹgẹ bi Lere Ọlayinka ṣe sọ, ”Abuku ni Kalu fẹẹ fi kan awa ara Ekiti nitori inira nikan la ri ninu ijọba Buhari. Ko si wahala nipinlẹ wa, ko gbe ipade ẹ lọ sibomi-in. A mọ pe nitori ẹjọ to ni pẹlu EFCC lo ṣe n wa ojurere Aarẹ Buhari kiri.”

Nigba to de siluu Ado-Ekiti lọsan-an ijẹta tilu-tifọn, ṣe ni Orji Uzor Kalu to jẹ gomina tẹlẹ nipinlẹ Abia sọrọ ṣakaṣaka si Fayoṣe. Gẹgẹ bo ṣe sọ, ”Nnkan bii oṣu mẹta ni Fayoṣe fi gbe nile mi l’Ekoo, ọrẹ la jẹ, ko to bẹẹ ko ni ki n ma wọ ipinlẹ yii. Awa la maa gba ijọba Ekiti ninu ibo ọsu keje, ọdun yii, Fayoṣe naa si mọ pe mo waa ki i pe o digbooṣe ni.”

Bakan naa ni Ọnarebu Fẹmi Bamiṣilẹ to gba oloye APC ọhun lalejo sọ pe Gomina Fayoṣe mọ pe asiko PDP ti to nipinlẹ Ekiti, idi niyi to fi n binu. O waa sọ pe oun loun kunju oṣuwọn laarin awọn oludije mẹrindinlọgbọn to ti kede erongba wọn lati dupo gomina ni APC.

Oni gan-an ni Bamiṣilẹ yoo gba fọọmu niluu Abuja pẹlu ikọ to le ni ọgọrin eeyan to ko dani.

(34)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.