Nitori ibo Gomina Ọṣun, awọn tọọgi pa Babatunde si Bọlọrunduro

Spread the love

Lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja lọ lọhun-un, ti kọmiṣanna ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọṣun, Oluṣẹgun Agbaje, kede esi ibo gomina ti wọn di lọjọ naa pe ko ti i sẹni to jawe olubori ni awọn tọọgi ti wọn ti n reti esi idibo yii kọlu ara wọn laduugbo Bọlọrunduro, niluu Ileṣa, bẹẹ ni iro ibọn n dun lakọlakọ lẹyin ikede ajọ eleto idibo yii. Nibi ija ọhun ni ẹni ọgbọn ọdun kan, Babatunde Adeyẹri, ku si.

Ẹni to fi ọrọ naa to akọroyin wa leti to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ṣalaye pe awọn janduku ti wọn ṣiṣẹ buruku naa foju jọ awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun, gbogbo wọn si ni wọn ti dihamọra ogun pẹlu awọn ohun ija oloro oriṣiiriṣii ti wọn fẹẹ fi ṣe ara wọn nijamba. Ni kete ti wọn si kede pe ẹnikan ko bori idibo naa ni awọn janduku ti bẹrẹ si i yọ ohun ija oloro ti wọn ti di mọra tẹlẹ, ti wọn si bẹrẹ si i ṣe awọn olodi wọn nijamba gidi.

Lẹnu ẹni ti ọrọ ṣoju ẹ yii la ti ri i gbọ pe o to wakati mẹfa gbako ti ija yii ti bẹrẹ ki awọn ọlọpaa too de, wọn ti pa Adeyẹri lasiko yii, koda, wọn ti gbe oku rẹ lọ ki awọn agbofinro too de.

Alaroye ba ọkan ninu awọn ọga ọlọpaa adugbo yii sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, amọ agbofinro to ni ka forukọ bo oun laṣiiri naa ni awọn gbiyanju gbogbo ipa awọn lati ri i daju pe eto aabo ko mẹhẹ lasiko idibo gomina, tori gbogbo awọn ọlọpaa ipinlẹ naa lawọn jade lati ran awọn ṣọja ti wọn ko wa sipinlẹ awọn lọwọ lori eto aabo. Awọn to ku lagọọ awọn gan-an ko to nnkan lasiko naa.

(89)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.