Nitori ibo abẹle, ija n bọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC

Spread the love

Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ ki wahala mi-in ma bẹ silẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC laarin awọn ọmọ ẹgbẹ kan atawọn oloye ẹgbẹ lapapọ. Bi wọn ko ba si feegun otolo to ọrọ naa, ko si ki awọn gomina ẹgbẹ yii kan atawọn mi-in pẹlu awọn aṣaaju ẹgbẹ yii ma jọ mu nnkan nilẹ.

Idi ni pe ọrọ ilana ti wọn fẹẹ fi ṣeto idibo abẹle wọn ti fẹẹ da wahala silẹ. Bi awọn kan ṣe faramọ ilana ti awọn oloye ẹgbẹ lapapọ la kalẹ lawọn mi-in ni ko bawọn lara mu.

Ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni awọn oloye naa ṣepade pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ kan, nibi ti awọn alaga ẹgbẹ kaakiri ipinlẹ atawọn gomina wa. Nibi ipade yii ni wọn ti fẹnuko pe ọna mẹta ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa le gba ṣe idibo abẹle nipinlẹ wọn.

Ohun ti wọn sọ ni pe eto idibo gbangba-laṣa-a-ta lawọn yoo lo fun ibo abẹle ti aarẹ, leyii to tumọ si pe awọn ọmọ ẹgbẹ yoo to si ẹyin oludije to ba wu wọn, wọn yoo si ka iye awọn to wa nibẹ.

Ṣugbọn ni ti awọn yooku, wọn le lo ilana gbangba laṣa-a-ta yii, tabi ki wọn lo eto idibo ti awọn ti wọn ba yan lati wọọdu, ijọba ibilẹ ati ipinlẹ yoo ti dibo ni bonkẹlẹ, ti ko si ni i sẹni to mọ ẹni ti wọn dibo fun. Ọna kẹta ti wọn ni wọn tun le gba dibo yan aṣoju wọn ni ki gbogbo wọn fẹnuko lati fa ẹni kan kalẹ, ti ko si ni i ni atako latọdọ ẹnikẹni.

Nigba ti gomina ipinlẹ Plateau, Simon Lalong, ati ojugba rẹ lati ipinlẹ Kogi, Ọgbẹni Yahya Bello, n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade naa lọsẹ to kọja, wọn sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ le lo ọna kan ninu mẹtẹẹta yii, ki wọn ṣa ri i pe wọn ko ṣe lodi si eyi to ba ofin ẹgbẹ mu.

Afi bo ṣe di irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii kan naa, iyẹn lọjọ keji ti wọn ti kọkọ gbe iroyin takọkọ jade ti alukoro ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Yekini Nabena, sọ pe ilana gbangba-laṣa-a-ta lawọn yoo lo fun gbogbo eto idibo abẹle naa patapata. O ni ki awọn ọmọ ẹgbẹ ma ṣe tẹle atẹjade to ti kọkọ waye tẹlẹ to fi aaye silẹ fun onikaluku lati yan eyi to fẹ gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ofin ẹgbẹ.

Eyi gan-an lo jọ bii ẹni pe o fẹẹ da wahala silẹ nitori ọrọ naa ko dun mọ awọn kan ninu, paapaa awọn gomina ẹgbẹ naa to jẹ pe eto idibo bonkẹlẹ ni wọn fẹẹ lo. ALAROYE gbọ pe awọn gomina yii lo maa n fẹẹ yan awọn ti yoo ba dije sawọn ipo, eyi lo fi jẹ pe awọn alatilẹyin wọn ni wọn yoo yan lati dibo pamari, ti ẹni ti wọn ba fẹ yoo si wọle. Eyi ṣee ṣe fun wọn nitori owo wa lọwọ wọn, eto aabo ati ohun gbogbo ti wọn nilo lati kọju esi idibo naa sibi to ba wu wọn wa lọwọ wọn. Wọn si mọ pe bi awọn ko ba fi ri eleyii ṣe, ohun ti yoo ṣẹlẹ ni pe ẹni to ba ni ọmọ ẹyin to pọ ju ni yoo wọle lasiko ibo abẹle naa, niwọn igba to jẹ pe onikaluku ni yoo to si ẹyin oludije to ba fẹ, ko si si eru tabi awuruju kankan nibẹ.

Ṣugbọn eyi ko dun mọ awọn aṣofin rara. Idi ni pe ọpọ awọn aṣofin to fẹẹ pada lọ atawọn mi-in ti wọn ṣẹṣẹ fẹẹ dupo, ti wọn si ni awọn alatilẹyin to le dibo abẹle ti yoo gbe wọn wọle ni igbesẹ idibo bonkẹlẹ awọn gomina ki i fun ni anfaani. Eyi lo fi jẹ pe ibo gbangba-laṣa-a-ta yii lawọn naa faramọ. Erongba wọn ni pe ẹnikẹni to ba wọle ninu gbogbo idibo abẹle naa yoo mọ pe awọn araalu lo dibo yan oun, nitori yoo nira lati fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lowo lati yi ipinnu wọn pada gẹgẹ bo ṣe maa n ṣẹlẹ to ba jẹ awọn dẹligeeti lo dibo.

Ibinu ọrọ yii lawọn gomina kan atawọn alaga ipinlẹ fi pepade siluu Abuja ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lati ṣepade lori ohun ti wọn le ṣe lati yi erongba yii.

Ki ipade yii too waye ni alukoro ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Yekini Nebana, ti kọkọ gbe atẹjade kan sita pe awọn kan n gbero lati ṣe ipade kan lọjọ Aiku ọsẹ yii lati yi ipinnu ẹgbẹ pada lori eto idibo abẹle ti awọn ti fẹnuko pe gbangba-laṣa-a-ta lawọn maa lo si gbogbo rẹ. O ni ipade yoowu ti wọn le ṣe ko ni atilẹyin ẹgbẹ ninu, ki ẹnikẹni ma si ṣe ba wọn lọwọ si i, tabi ko gba aba naa wọle. O ni awọn mọ awọn to wa nidii ipade yii, ko si si nnkan mi-in ju pe wọn fẹẹ ba gbogbo akitiyan alaga ẹgbẹ ọhun, Adams Oshiomhole, lati mu ẹgbẹ yii pada bọ sipo jẹ ni.

O fi kun un pe bi gbogbo awọn to lọwọ ninu igbesẹ yii ba kọ lati jawọ, ẹgbẹ yoo fi iya to tọ jẹ wọn labẹ ofin. O waa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn ba ni ikunsinu kan tabi omi-in lori igbesẹ ti awọn oloye ẹgbẹ gbe pe ki wọn lo ọna to tọ labẹ ofin ẹgbẹ lati fi ẹhonu wọn han.

 

Gẹgẹ bi ohun to ti sọ ṣaaju, awọn eeyan naa, ninu eyi ti awọn gomina ati awọn alaga ẹgbẹ oṣelu APC kaakiri ipinlẹ atawọn oloye ẹgbẹ mi-in pejọ lati ṣepade lori igbesẹ ti ẹgbẹ fẹẹ gbe ọhun ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii. ALAROYE gbọ pe ileetura Transcorp Hillton, to wa niluu Abuja, ni wọn ti fi ipade naa si ni deedee aago meji ọsan gẹgẹ bi Yekini ti sọ tẹlẹ, ṣugbọn nigba ti wọn gbọ pe awọn kan ti lọọ ṣofoofo ipade naa fun awọn oloye ẹgbẹ ni wọn gbe e kuro ni Hilton, ti wọn si gba ileetura kan ti wọn n pe ni Barcelona, niluu Abuja yii kan naa lọ, nibi ti ipade ọhun ti waye.

Ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe awọn alaga ẹgbẹ naa kaakiri ipinlẹ ati awọn gomina ni wọn wa nidii ọrọ naa. Bakan naa la gbọ pe inu awọn oludije kan ko dun si owo gọbọi ti wọn ni wọn yoo fi gba fọọmu lati dije, eyi si wa lara nnkan ti awọn to ṣepade ọhun gbe yẹwo.

Wọn ni wọn fẹẹ fi owo gọbọi ti wọn n beere fun yii ja awọn ti wọn nifẹẹ lati dupo, ṣugbọn ti wọn ko niru owo bẹẹ lọwọ ni. Miliọnu marundinlọgọta (55m), ni oludije to ba nifẹẹ si ipo aarẹ yoo fi gba fọọmu. Ẹni to ba fẹẹ dupo gomina gbọdọ ni miliọnu mejilelogun ataabọ (22.5m), lọwọ. Miliọnu mẹjọ ataabọ (8.5m), ni wọ yoo ta fọọmu ọmọ ile igbimọ aṣofin agba, nigba ti fọọmu ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin jẹ miliọnu mẹta ati ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira (3.3m). Ẹni to ba fẹẹ dupo ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ gbọdọ ni miliọnu kan Naira (1m), lọwọ. Eyi wa lara ohun ti wọn tori ẹ ṣepade pe afi dandan ki wọn din owo naa ku.

Awọn eeyan naa ni awọn ko ti i fẹnuko sibi kan lori ipade yii, eyi ni ko ti i jẹ ki awọn pe ipade awọn oniroyin lati fi ero ọkan wọn to gbogbo aye leti.

Ohun ti awọn to n woye bi nnkan ṣe n lọ n sọ ni pe bi awọn aṣaaju ẹgbẹ APC atawọn alẹnulọrọ gbogbo ko ba tete fi eegun otolo to ọrọ naa, ki wọn si tete yanju rẹ, afaimọ ko ma ṣakoba fun ẹgbẹ naa pẹlu bi awọn kan ṣe n halẹ bayii pe awọn yoo fi ẹgbẹ naa silẹ bi wọn ba ni dandan, ibo gbangba-laṣa-a-ta yii ni ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ lo.

Ko ti i sẹni to mọ ibi ti ọrọ naa yoo ja si bayii.

(60)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.