Nitori ibo aarẹ 2019: TINUBU TI LỌỌ BA BUHARI NI LONDON O

Spread the love

Lati ọsẹ to kọja ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti kede pe oun yoo du ipo aarẹ Naijiria lọdun 2019 ni ere ti tun bẹrẹ, awọn ti wọn mọ nipa bi baba naa ti wọle ni ọdun 2015 ti tun bẹrẹ iṣẹ, wọn si sọ pe iru idan ti awọn pa ni ọdun 2015 lawọn yoo tun pa ni 2019, ko si si ẹni ti yoo ba Buhari du ipo aarẹ. Ni asiko ti Buhari kede pe oun fẹẹ du ipo naa, ki i ṣe pe o ti mura rẹ tẹlẹ, awọn aṣaaju ẹgbẹ APC ti wọn wa nidii ọrọ idibo rẹ ni wọn sọ pe asiko ti to to gbọdọ ṣe bẹẹ, nitori awọn kan ti n sare kiri ni abẹlẹ, ti wọn n ro pe ko fẹẹ du ipo naa, bi awọn yii ba si ti kede sita, yoo ṣoro lati fa wọn pada sẹyin, iyẹn ni Buhari ṣe sare kede pe oun yoo du ipo yii. Buhari sọrọ ọhun fun Biṣọọbu Agba ilẹ England, Bishop Justin Welby. O ni nitori ti oun ko fẹ ki awọn oloṣelu atawọn ọmọ Naijiria daamu loun ṣe tete kede ipinnu oun.

Bi ẹnikẹni ba waa ro pe aṣaaju ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, yoo pada lẹyin Buhari lasiko yii, onitọhun n tan ara rẹ jẹ ni. Bi nnkan ti ri bayii, ọrẹ ti awọn mejeeji jọ n ṣe ti tun pada si tatijọ, koda, ọrẹ ọhun lagbara ju ti atẹyinwa lọ. Ohun to ṣẹlẹ bayii ni pe olori awọn oloṣelu ilẹ Yoruba naa ti leri pe gbogbo ọna pata loun yoo gba lati ri i pe ko si ẹni to gba ipo lọwọ Buhari lọdun 2019, pe bi ọkunrin naa dagba to darugbo ju bẹẹ lọ, oun nikan loun gba pe o le ṣe ijọba Naijiria daadaa, ti yoo si mu orilẹ-ede naa de ilẹ ileri. Ṣe awọn kan ti n sọ kiri pe Tinubu ko ni i ba Buhari ṣe lasiko yii nitori awọn ohun ti wọn fi oju rẹ ri lẹyin ti wọn dibo tan ni ọdun 2015 ti Buhari si wọle, to waa jẹ awọn ti wọn ko mọ bo ṣe wọle lo ku to yi i ka, ti wọn si ta Tinubu nu, ti wọn fi i wọlẹ daadaa.

Alaroye gbọ pe Tinubu ti sọ fawọn to n ronu bayii pe gbogbo ohun to ṣẹlẹ ki i ṣe ọwọ Buhari lo ti wa, awọn ti wọn yi i ka ni, awọn ni wọn fẹẹ ba ọrẹ awọn jẹ, ṣugbọn Ọlọrun ti ju wọn lọ. Nidii eyi, awọn ti wọn sun mọ Tinubu sọ pe ọkunrin naa ti ni ko si bi oun yoo ti ṣe fi Buhari silẹ, amọ nnkan yoo yatọ si tatijọ, nipa pe oun ko ni i gba awọn alaimọkan kan laaye lati tun sun mọ Buhari, oun funra oun loun yoo maa tọ ọ sọna lori ohun ti yoo ṣe. Eleyii lo jọ pe o gbe Tinubu lọ si London, oun naa ti wa niluu naa lati ọsẹ to kọja ti Buhari ti wa nibẹ, wọn si ti rira daadaa, wọn ti ṣepade lọpọ igba ki awọn eeyan too mọ pe Jagaban ti wa lọhun-un pẹlu Aarẹ. Yatọ si pe awọn ọmọlẹyin ẹ n ba iṣẹ lọ ni Naijiria nibi, gbogbo ohun to n lọ ni Tinubu funra ẹ n fi to Buhari leti niluu oyinbo nibẹ, ti wọn si jọ n gbero lori ohun ti wọn yoo ṣe.

Ṣe lati ọjọ Aje to kọja ni Buhari ti wa ni London, iroyin to si gbilẹ nigba to fẹẹ jade ni pe ipade awọn olori orilẹ-ede gbogbo kan yoo waye nibẹ lọsẹ yii, ti Buhari funra rẹ si gbọdọ kopa nibẹ. Ṣugbọn ko too di igba naa, Aarẹ yoo ri awọn ọrẹ rẹ kan, ti wọn yoo si jọ sọrọ. Bo tilẹ jẹ pe awọn akede ijọba ko sọ eyi, awọn kan ta Alaroye lolobo pe Aarẹ yoo fi asiko naa de ọsibitu, nibi ti yoo ti ṣe ayẹwo ara rẹ, ti yoo si mọ bi ara oun ti ṣe ri lẹyin itọju ti oun ti gba lọjọsi. Bi Buhari si ti de London loootọ, awọn ohun to fẹẹ ṣe wọnyi lo n mu ṣe, ko si ti i si igba kan ti wọn sọ pe o sun kalẹ, tabi tawọn eeyan ko ri i. Ṣugbọn kinni naa ko rọgbọ bẹẹ, nitori bo ti de London lawọn ọmọ Naijiria kan ti sare ṣa ara wọn jọ, wọn si ṣe iwọde yi agbegbe ile ijọba ati Ẹmbasi Naijiria ka, ti wọn n pariwo pe Buhari ko lojuti lo ṣe tun fẹẹ du ipo aarẹ lẹẹkeji.

Ohun ti awọn yii n sọ ni pe pẹlu gbogbo oku to n sun ni Naijiria lojoojumọ lati ọwọ awọn Fulani onimaaluu, ati awọn Boko Haram ti wọn n ji awọn ọmọ ọlọmọ gbe, ati eto ọrọ aje to tubọ buru si i labẹ baba yii, wọn ni Sai baba ko lẹtọọ mọ lati tun loun yoo du ipo aarẹ, iyẹn bo ba jẹ ojuti kankan wa fun un. Ọrọ naa bi awọn alukoro ijọba ninu gan-an, kia ni Garba Shehu, ọkan ninu awọn akede fun Buhari, ti gbe iwe jade, o ni ki gbogbo awọn ọmọ Naijiria wo oju awọn ti wọn n ṣe iwọde yẹn o, bi wọn ko ba jẹ awọn ole ti wọn ti sa lọ nile, yoo jẹ awọn akowojẹ ti wọn ji owo ijọba ko, ti awọn ṣẹṣẹ darukọ wọn, iyẹn ni pe bi eeyan ba wa a lọ wa a bọ, awọn ọmọ PDP ni wọn yoo wa nidii ọrọ naa, nitori yatọ si awọn nikan, gbogbo awọn ọmọ Naijiria to ku ni wọn fẹran Buhari, awọn funra wọn ni wọn si pe e pe ko tun waa ṣejọba ni 2019.

Buhari ko jẹ ki ọrọ naa bi oun ninu o, koda ko ba wọn da si i, ohun to lọọ ṣe ni London lo gbajumọ. Kia lo ti fẹsẹ ara rẹ rin lọ si ọdọ Bishop Welby. O sọ fun ọkunrin naa pe oun waa ri i ki oun le dupẹ lọwọ rẹ bo ṣe duro ti oun nigba ti ara oun ko ya ti oun wa ni London lọjọsi, ki oun si tun ṣalaye fun un pe awọn ọmọ Naijiria ti wọn mọ riri iṣẹ ti awọn n ṣe ti tun sọ pe ki oun jade lati du ipo aarẹ lọdun 2019. Aarẹ Buhari n sọ fun biṣọọbu oyinbo naa pe oun ko tilẹ ni i lọkan tẹlẹ lati tun jade mọ, ṣugbọn nigba ti ariwo awọn ọmọ Naijiria pọ ju, ti wọn ṣaa n pe oun lọ pe oun bọ, ti wọn ni ki oun ma fi awọn silẹ bayii, iyẹn loun ṣe tun da a ro, ti oun si gba lati du ipo naa, ti o si da oun loju pe ẹgbẹ awọn yoo wọle ki awọn le maa ba iṣẹ daadaa ti awọn n ṣe lọ. Inu biṣọọbu naa dun, o si gbadura fun Buhari pe yoo ṣee ṣe.

Ṣugbọn yatọ si ti biṣọọbu, awọn ti wọn n ṣeto idibo fun Buhari lẹyin odi ti wọn pe orukọ wọn ni Buhari Support Group naa ko fi Aarẹ silẹ, awọn naa ti sare lọ si ọdọ rẹ, wọn ni gbogbo bi yoo ba ti lo awọn fun ọrọ ibo yii ko tun le wọle lawọn ti ṣetan, awọn ko si ni i fi i silẹ nigba kan. Oun naa dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa, o ni bi awọn ti ṣe lọdun 2015 naa lawọn yoo tun ṣe, ki iṣẹ rere ti awọn n ṣe lọ le pari. Nigba naa ni Aṣiwaju Tinubu wọle wẹrẹ, ti ariwo si sọ laarin awọn eeyan, wọn ni bi awọn ba ti ri Tinubu lẹyin Buhari, ọrọ ti yanju. Ko ma si pe ẹni kan yoo tun ko si wọn laarin lọkunrin oloṣelu naa ṣe wa nibẹ, ko si too di pe Buhari pada de si Naijiria, wọn yoo ti pari eto ti ko ni i ku sibi kan. Aarin Buhari ati Tinubu ni koko ọrọ yoo si wa, ki wọn kan maa sọ ohun tawọn aṣaaju ẹgbẹ to ku yoo ṣe fun wọn ni.

Buhari ko ti i mura lati pada o, bẹẹ ni Tinubu paapaa ko si ti i ṣetan, ọrọ ti di oju awo lawo fi i gbọbẹ, wọn yoo jọ wa nibẹ ti ohun gbogbo yoo fi yanju pata ni.

 

(71)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.