Nitori gbese owo Lapo to je, Mary gbẹbọ lọsan-an gangan l’Ondo

Spread the love

Ni ti Abilekọ Mary Akinkuotu, ko jọ pe ẹbọ to gbe lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii fin rara, debi ti yoo da, nitori ni ikorita to ti n gbe ẹbọ naa silẹ ni awọn eeyan ka a mọ, ti wọn si sọ fun un ko gbe ẹbọ rẹ pada sibi to ti n gbe e bọ.

Adugbo Akinjagunla, niluu Ondo, ni Mary, ẹni ọdun mẹrindinlogoji, n gbe.Ṣugbọn, lọsan-an ọjọ yii, niṣe lo gbe ẹbọ kanka ti i ka igun laya lọ si adugbo Adesuper, nigba to de oju odo nla kan laduugbo yii lo bọra sihooho.

Awọn araadugbo ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye fun akọroyin wa pe inu aṣọ funfun kan ni obinrin yii gbẹbọ naa si, to si mu ẹyin adiẹ ibilẹ kan lọwọ. Nigba to de inu odo naa lo bọra sihooho, to si bẹrẹ si i wẹ.

Ko too di pe ọmọbinrin yii wẹ iwẹ rẹ tan, awọn araadugbo yii ti wọn ti ṣakiyesi rẹ tẹlẹ ti pejọ, ti wọn si bẹrẹ si i pariwo le e lori pe laelae, awọn ko ni i gba ko gbe ẹbọ naa kalẹ si oju odo yii. Obinrin kan ti ile rẹ ko jinna si ibi odo yii, Ọladunni Akinbọlawa, ẹni to ba akọroyin wa sọrọ, ṣalaye pe ṣadeede loun ri Mary nihooho, to si bẹrẹ si i pe ọfọ lẹnu. Igbesẹ yii lo mu oun pariwo, eyi to ta awọn araadugbo naa lolobo nnkan to n ṣẹlẹ.

Ko too di i pe awọn eeyan yoo de ibi iṣẹlẹ naa, Mary ti wọ aṣọ rẹ pada, niṣe lo si bẹrẹ si i bẹ awọn eeyan naa pe ki wọn ma foya, ẹbọ naa ki i ṣe ẹbọ to le pa wọn lara.

Mary ṣalaye pe iṣẹ awọn to n ta oogun oyinbo, iyẹn kẹmiisiti, loun n ṣe, bẹẹ awọn mọlẹbi oun to wa niluu oyinbo si tun fi owo ran oun lọwọ, ṣugbọn, niṣe ni gbogbo rẹ run.

O ni ọna mẹta loun ti jẹ gbese owo Lapo, to si jẹ pe nigba mi-in, ọja maa n pọ ninu ṣọọbu oun, nigba mi-in, niṣe ni ṣọọbu oun yoo furo.

O ni gbogbo iṣẹlẹ yii lo mu oun jade sọrọ oun, awọn to si ba oun yẹ ọrọ naa wo sọ pe ẹgbẹ ọrun lo n da oun laamu. O ni awọn eeyan yii lo ni o di dandan ki oun ṣe etutu fun awọn ẹgbẹ naa, ki wọn baa le yọnu si oun.

Ṣugbọn, awọn araadugbo naa ko gba ọrọ yii gbọ rara, wọn ni niṣe ni ko gbe ẹbọ naa pada si ibi to ba ti n gbe e bọ.

Awọn ọdọ naa paṣẹ fun un pe ko tu aṣọ funfun to fi de ẹbọ naa, nigba to si tu u ni wọn ri i pe awọn nnkan bii ireke, aadun, ẹwa sise ati agbado lo wa ninu rẹ.

(31)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.