Nitori foonu, Chidi ati ọmọọṣẹ rẹ ṣeku pa Samuel l’Ẹpẹẹ

Spread the love

Yoruba bọ, wọn ni iṣẹ ki i pa ni, ayọ ni paayan, owe yii lo ba ọkunrin kan, Chidi Onweke ati ọmọọṣẹ rẹ, Onwori Emmanuel, ti wọn fẹsun kan pe wọn ṣeku pa Samuel Okuchi, nibi ti wọn ti n ṣajọyọ ikomọ niluu Ẹpẹ mu.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Chidi, Emmanuel ati Samuel ti wọn pa jẹ ọrẹ timọ-timọ, ipinlẹ Ebonyi ni wọn ti wa, ti wọn si n sisẹ oko labule Oniṣọọsi, nitosi Ẹpẹ, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ondo.
Ẹgbọn wọn kan to filu Idanre ṣebugbe lo bimọ ni nnkan bii ọsẹ mẹrin sẹyin, to si ti sọmọ naa lorukọ niluu Idanre, nibi to n gbe, lẹyin ti ọmọ naa pe ọjọ mẹjọ.
Ọsẹ kẹta lẹyin ti wọn bimọ tan ni Chidi atawọn eeyan rẹ naa tun ko ara wọn jọ labule Onisọọsi, ti wọn ti n ṣisẹ ti wọn si lawọn fẹẹ ṣajọyọ ọmọ ti ẹgbọn awọn bi.
Niṣe ni wọn fa pati naa lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja. Aarọ kutu ni wọn ti bẹrẹ eto ọhun, bẹẹ ni wọn si ṣe e titi di nnkan bii aago mẹrin irọle ko too di pe esu ba wọn lọwọ si i.
Ohun ti awọn eeyan to wa nibi iṣẹle yii ṣakiyesi ni pe ariyanjiyan kan deede bẹ silẹ laarin Chidi ati Samuel.
Foonu kan to ti sọnu latọjọ pipe ni wọn lo da ariyanjiyan ọhun silẹ laarin wọn. Chidi la gbọ pe o fẹsun kan Samuel pe oun lo ji foonu ọhun, ti Samuel si yari pe wọn parọ ole mọ oun ni.
Ko pẹ rara ti ariyanjiyan yii fi yọri si ija laarin awọn mejeeji, lẹyin ti wọn ti ku ara wọn lẹsẹẹ ni wọn tun n foju wa apola igi ti wọn le fi lu ara wọn kiri.
Ẹẹkan naa lọwọ awọn mejeeji tẹ apola igi bẹnṣi ijokoo kan to ti bajẹ, ọwọ Chidi ni wọn lo kọkọ ya ju ti Samuel lọ, nitori pe nibi ti Samuel ti n foju wo ibi to fẹẹ gba igi mọ lara Chidi, oun ti yara fọ igi mọ ọn lẹyin, leyii to mu ki Samuel ṣubu lulẹ lẹsẹkẹsẹ.
Samuel ko ti i raaye dide nibi to ṣubu si ti Emmanuel ti wọn lo jẹ ọmọọṣẹ Chidi fi tun sare gbe apola igi mi-in, to si la a mọ Samuel lọrun.
Chidi ati ọmọọsẹ rẹ la gbọ pe wọn tun ti mura ija pẹlu bi wọn ṣe n duro ki Samuel dide, ki ija naa si tun maa tẹsiwaju, ṣugbọn ọkunrin naa ti gbẹmii-mi.
Awọn ọlọpaa teṣan Fagun, to wa niluu Ondo, ni wọn fọrọ ọhun to leti, ti wọn si fi panpẹ ọba gbe Chidi ati ọmọọṣẹ rẹ, ko si pẹ rara ti wọn fi taari wọn si oluuleeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Akurẹ.
Nigba to n fidi iṣẹle ọhun mulẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, sọ pe awọn afurasi mẹrin lo ti wa nikaawọ ileeṣẹ ọlọpaa, to si ṣeleri pe laipẹ ni wọn yoo foju ba kootu lẹyin ti iwadii awọn ba pari.

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.