Nitori fiimu to maa n lọọ wo nile keji, ọkọ lu iyawo ẹ daku ni Saki

Spread the love

Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun 

Ileewosan aladaaani kan to wa lọna to lọ siluu Ogboorọ, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ṣaki, ni Abilekọ Nuratu Shittu wa lọwọlọwọ, nibi to ti n gba itọju latari bi ọkọ rẹ, Ọgbẹni Tijani Shittu, ṣe din dundu iya fun un nitori bo ṣe lọọ wo fiimu ni yara awọn alajọgbe wọn lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, laduugbo Oke Ṣebe, niluu naa.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Abilekọ Nuratu fẹran lati maa wo fiimu agbelewo ni yara to doju kọ yara wọn tọkọ rẹ ba ti lọ sibi iṣẹ, ti ọkọ rẹ si ti kilọ fun un pe oun ko nifẹẹ si aṣa tojubọle naa.

Ninu iwadii ti ALAROYE ṣe, a gbọ pe iṣẹ mẹkaniiki ni baale naa n ṣe niluu yii, to si jẹ pe irọlẹ patapata tabi alẹ lo maa n wọle lẹyin to ba ṣiwọ iṣẹ oojọ rẹ.

 Ṣugbọn lọjọ ti iṣẹlẹ yii waye, niṣe ni Abilekọ Nuratu tun lọọ wo fiimu gẹgẹ bo ṣe maa n ṣe, to si gbagbe sun lọ si yara to ti n wo fidio lai fura pe ọkọ oun ti de, bẹẹ ni ko ranti tilẹkun yara wọn. Eyi lo mu ki Ọgbẹni Tijani maa wa iyawo rẹ kiri adugbo lai mọ pe yara keji lo wa, nibi to gbagbe sun si.

Ọrọ yii la gbọ pe o bi ọkunrin naa ninu to fi bẹrẹ si i ko igbati igbamu funyawo rẹ titi tiyẹn fi daku, ni wọn ba gbe e digbadigba lọ sileewosan kan ti ko fi bẹẹ jinna saduugbo wọn.

Nigba ti akọroyin wa fọrọ wa Ọgbẹni Tijani lẹnu wo, o ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe o ti to ọdun mẹta tawọn ti ṣegbeyawo, ti ko si ti i si ọmọ laarin awọn, sibẹ, awọn ni ẹrọ fidio to jẹ tawọn ninu yara, o si ya oun lẹnu pe eyi tawọn ni yii ko tẹ iyawo oun lọrun, afi to ba lọ si yara ayalegbe wọn lọọ wo fidio.

O fi kun un pe ohun to bi oun ninu pupọ ninu ọrọ naa ni pe yara apọn ti ko niyawo sile ni iyawo oun ti n wo fidio ni gbogbo igba, toun si ti kilọ fun un, ṣugbọn to jẹ pe ẹyin eti rẹ ni ikilọ oun n bọ si, o ni boya o fẹẹ maa yan ale ni, ko kuku sọ foun ki oun le yọnda rẹ.

Awọn aladuugbo tọrọ naa ṣoju rẹ sọ fun ALAROYE pe ọpọ igba ni ọkọ naa ti n kilọ aṣa buruku naa fun iyawo rẹ, ati pe o ru eeyan loju bi obinrin naa ṣe taku ti ko jawọ.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.