Nitori eto idibo ti yoo waye lọsẹ yii, ileeṣẹ ọlọpaa da awọn ọlọpaa sita l’Ekoo

Spread the love

Zubairu Muazu to jẹ kọmisanna ọlọpaa tuntun nipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki awọn oṣiṣẹ rẹ bẹrẹ si i ṣọde kaakiri ipinlẹ Eko, nipalẹmọ fun eto idibo ti yoo waye lọsẹ yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Chike Oti, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi ṣọwọ si awọn oniroyin lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.

O ni kọmisanna naa ti ni ki awọn olugbe ipinlẹ Eko maa ṣiṣẹ wọn lọ lai foya tabi bẹru ẹnikẹni. Bakan naa ni Muazu dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ naa fun ifọwọsowọpọ ti wọn ni pẹlu ileeṣẹ naa, o si ṣeleri pe awọn ko ni i ja igbagbọ awọn eeyan naa kulẹ rara.

Bakan naa lo ṣekilọ fun awọn to ba ni i lọkan lati dabaru eto idibo ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii, lati tete sa kuro nipinlẹ Eko, nitori awọn ko ni i faaye gba wọn rara.

O waa fi awọn nọmba ipe ti awọn oludibo le pe si ti wọn ba kẹẹfin wahala layiika wọn lasiko idibo sita. Awọn nọmba naa ni:

Control 1: 08127155132 and 07035068242, Control 2: 08127155150 and 08065154338, Control 3: 08127155071 and 08063299264.

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.