Nitori eto idibo, awọn kọsitọọmu ṣedanilẹkọọ fawọn awakọ l’Oke-Ogun

Spread the love

Ileeṣẹ Kọsitọọmu orileede yii, ẹka ti agbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ, ti gba awọn awakọ nimọran, paapaa awọn oniṣowo ati awọn araalu lati joye oju-lalakan-fi-n-ṣori ki eto idibo too bẹrẹ, lakooko ati lẹyin idibo, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ naa nitori pe awọn ti ṣetan lati maa ṣayẹwo to gbona fawọn ọkọ to ba n kọja lagbegbe naa, paapaa lati ilu Igbẹti, kọja si ipinlẹ mi-in lati le dena kiko nnkan ijagun wọle si orileede yii lakooko eto idibo to n bọ.

Ọga agba ajọ naa, Ọgbẹni Adeṣiyan John Amusan, lo parọwa yii lakooko idanilẹkọọ to ṣe fawọn awakọ ni olu-ileeṣẹ wọn niluu naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.
Gẹgẹ bo ṣe wi, gbogbo ọna ni awọn oloṣelu atawọn ọta orileede yii
n gba lati dabaru eto idibo to n bọ lọna pẹlu bii iroyin ṣe n gba ilu pe
oriṣiiriṣii nnkan ijagun n wọle si orileede yii lati aala ẹnu bode, eyi
ti ko yọ agbegbe naa silẹ.
O waa parọwa sawọn araalu lati ma ṣe ri igbesẹ ayẹwo ọkọ naa gẹgẹ bii ọna lati di wọn lọwọ iṣẹ oojọ wọn.

Lara awọn to kopa nibi idanilẹkọọ ọhun la ti ri aṣoju Ọba ilu Igbẹti,
Oloye Ayọdele Adediran, Seriki ilu Igbẹti, ẹgbẹ awakọ ero (NURTW),
RTEAN, ẹgbẹ ọlọkada, iyalọja ati babalọja pẹlu awọn oniṣowo gbogbo.

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.