Nitori esun ole jija, Aliyu atawọn yooku rẹ foju ba kootu

Spread the love

Kootu Ọgba, ni awọn ọlọpaa wọ awọn afurasi adigunjale mẹta kan; Ayọmide Jacob, ẹni ọdun mẹrinlelogun, Aliyu Ọladapọ, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, ati Hassan Nuru, ẹni ọdun mẹtalelogun, lọ, nibi ti wọn ti fi ẹsun igbimọ-pọ huwa ọdaran ati ole jija kan wọn.
Micheal Unah, ẹni to n gbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni kootu, sọ pe awọn mẹtẹẹta gbimọ-pọ lati jale ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu to kọja, nitosi ọfiisi awọn LASTMA to wa ni Oshodi-Apapa. O ni ṣe ni wọn ji baagi dudu kan ti Ẹgbẹrun mẹta Dọla wa ninu rẹ atawọn dukia mi-in ti apapọ iye owo rẹ jẹ miliọnu meji o le diẹ Naira, eyi ti i ṣe ti Ọgbẹni David Broha.
Awọn olujẹjọ naa ni awọn ko jẹbi ẹsun yii. Adajọ A.A Fashọla, faaye beeli silẹ fun wọn pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (500, 000.00), ati oniduuro meji niye kan naa. Ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, ni o sun igbẹjọ wọn si.

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.