Nitori esun ijaagboro, awon meta dero ile-ejo n’Ife

Spread the love

Adebayọ Funkẹ, ẹni ọdun mejilelogoji, Hammed Yusuf, ẹni ọdun mejilelogoji ati Adebayọ Adebolu, toun jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogoji ti foju bale-ẹjọ   Majisreeti kan niluu Ileefẹ, lori ẹsun ija jija ati dida omi alaafia agbegbe ru.

Awọn olujẹjọ mẹtẹẹta yii nileeṣẹ ọlọpaa fẹsun kan pe wọn da wahala silẹ ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ aarọ lagbegbe Abewela, niluu Ileefẹ, lọjọ kẹjọ, oṣu kọkanla, ọdun yii.

Gẹgẹ bi Kọpura ọlọpaa to wa nidii ẹsun naa, Ọlawale Oduṣina, ṣe sọ funle-ẹjọ, o ni ṣe lawọn mẹtẹẹta dawọ na Alẹgbẹlẹyẹ Ọlaolu pẹlu awọn nnkan ija, wọn si da ọpọlọpọ apa si i loju lọjọ yii.

Bakan naa ni wọn fẹsun kan wọn pe wọn dawọ jọ na Alẹgbẹlẹyẹ Yetunde, to si jẹ pe awọn ti wọn wa nitosi ni wọn gba a lọwọ wọn ti wọn ko fi ṣe e leṣe laaarọ ọjọ naa.

Oduṣina fi kun ọrọ rẹ pe iwa awọn olujẹjọ yii lodi si abala ọtalelọọọdunrun o din mẹsan-am ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ọṣun ti ọdun 2002, bẹẹ lo si ni ijiya labẹ ofin.

Lẹyin ti awọn olujẹjọ sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ni agbẹjọro wọn,  Ọgbẹni Leke Dada bẹbẹ fun beeli wọn pẹlu ileri pe igbakuugba tile-ẹjọ ba ti nilo wọn ni wọn aa maa yọju.

Adajọ Majisreeti naa, Adejumọkẹ Ademọla-Olowolagba, gba beeli ọkọọkan olujẹjọ pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira ati oniduuro kan ni iye kan naa.

O ni oniduuro yẹn gbọdọ jẹ mọlẹbi olujẹjọ, bẹẹ lo gbọdọ ni adirẹẹsi teeyan le wa a.

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.