Nitori esun agbere, Ladayo gun afesona re pa l’Akure

Spread the love

Ariwo, ‘ẹ dakun, ẹ saanu mi, mi o deede ṣeku pa afẹsọna mi, eedi lo di mi, mo ti ṣe e tan koju mi too walẹ’ ni Saliu Ladayọ ti wọn fẹsun kan pe o ṣeku pa ọrẹninrin rẹ, Confidence Nwama, fi bọnu lasiko to n b’ALAROYE sọrọ ni olu-ileeṣẹ awọn ọlọpaa to wa niluu Akurẹ.

 

Ninu alaye ti ọmọkunrin ọhun ṣe fun wa pẹlu omije loju lo ti ni oun ni ede aiyede pẹlu afẹsọna oun yii lori epe to maa n ṣẹ foun ni gbogbo igba, eyi ti ko dun mọ oun ninu.

 

Foonu to wa lọwọ oloogbe naa lo sọ pe oun fẹẹ fagbara gba lọwọ ẹ, ṣugbọn to kọ jalẹ lati fun oun. Lojiji lo sọ pe ẹmi kan ba le oun, toun si wọle lọọ mu ọbẹ, eyi toun fi gun un pa, lẹyin eyi ni oju oun walẹ.

 

Ariyanjiyan kekere kan ni wọn lo ṣẹlẹ laarin ọmọ bibi ilu Ẹpẹ ọhun ati afẹsọna rẹ, Confidence, to jẹ ọmọ Ibo to fi dohun ti wọn n gun ara wọn pa.

 

Ẹgbọn Ladayọ kan to jẹ osiṣẹ banki lọmọkunrin ọhun n gbe pẹlu rẹ ninu yara ati palọ kan to gba si ojule keji, adugbo Dele Ojo, Ọṣinlẹ, niluu Akurẹ lati bii ọdun mẹta sẹyin. Ileetura kan ta a forukọ bo laṣiiri ni Ladayọ ti n fiṣẹ kekere kan pawọ da titi tọrọ ati wọ ileewe giga rẹ yoo fi bọ si i.

 

ọ ti ṣe diẹ ti wọn sọ pe ọmọkunrin ọhun ati Confidence to doloogbe yii ti n fẹra wọn, wọn ni ọpọlọpọ igba lawọn mejeeji maa n wa ara wọn lọ sile.

 

Ni nnkan bii ọjọ diẹ ṣẹyin ni Ladayọ wa afẹṣọna rẹ lọ sile wọn, ṣugbọn o ba ọkunrin mi-in to fura si pe o jẹ ololufẹ ọrẹbinrin rẹ.

 

Niṣe lọmọkunrin naa dibọn bii ẹni pe ọrọ ọhun ko fi bẹẹ dun un, to si wọna tan ọmọbinrin ọhun wa sile ti oun ati ẹgbọn rẹ jọ n gbe lagbegbe Ọṣinlẹ, niluu Akurẹ, lẹyin to ti mọ daju pe ẹgbọn oun ko ni i si nile.

 

Lẹyin ti wọn wọnu yara tan lariyanjiyan nla bẹ silẹ laarin wọn pẹlu bi ọmọkunrin ọhun ṣe n wa gbogbo ọna lati gba foonu ọrẹbinrin rẹ, ṣugbọn ti iyẹn kọ jalẹ lati fun un.

 

Wọn ni Ladayọ ti kọkọ lu oloogbe naa lalubami lori bo ṣe kọ lati yọnda foonu rẹ fun un. Gbogbo ipa tawọn ayalegbe meji to wa nile lasiko rogbodiyan ọhun sa lati la awọn mejeeji ni wọn lo ja si pabo.

 

Lẹyin ọpọlọpọ wakati ti wọn ti wa lori wahala ọhun ni wọn lọmọkunrin naa deede binu wọnu yara, afi bii ẹni pe awọn obinrin ayalegbe meji tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn mọ ohun to fẹẹ ṣẹlẹ pẹlu bi wọn ṣe n kilọ fun ọmọbinrin naa pe ko tete maa sa lọ ki ẹni ti wọn jọ n ja too jade wa ba a.

 

Loootọ lọmọbinrin ọhun sa, ṣugbọn dipo ko sa jade ninu ọgba ile naa, ile idana ile ọhun lo sapamọ si, nibi ti ọrẹkunrin rẹ yii ti pada lọọ ba a pẹlu ọbẹ to si gun un pa.

Oju ẹṣẹ ni wọn lo ti sa jade ninu ọgba ile naa, to si fẹẹ maa sa lọ, awọn obinrin meji to wa nibi iṣẹlẹ ọhun lo fariwo ta sawọn araadugbo. Awọn eeyan yii ni wọn pada mu ọmọkunrin ọhun, ti wọn si fa a le awọn ọlọpaa ‘B Division’ to wa l’Oke Aro, niluu Akurẹ, lọwọ.

 

Wọn sare gbe Confidence lọ sileewosan ijọba to wa niluu Akurẹ, ṣugbọn awọn dokita ni ọmọbinrin ọhun ti ku ko too de ọdọ awọn.

 

Iya ọmọbinrin ọhun sọ ninu alaye to ṣe f’ALAROYE pe ṣọọbu loun wa lọsan-an ọjọ naa nigba ti wọn deede pe oun pe Ladayọ ti gun ọmọ oun lọbẹ pa, ati pe bii ala lasan lo ri loju oun nigba toun de ileewosan toun si ri i pe loootọ niṣẹlẹ naa waye.

 

Ohun kan soso to n jade lẹnu abilekọ naa nigba to n sọrọ ni teṣan ‘B Division’ ni pe idajọ ododo loun n fẹ lori iku ọmọbinrin naa.

ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe ko ti i pẹ rara ti ọmọbinrin ẹni ọdun mọkandinlogun naa ṣẹṣẹ pari idanwo oniwee mẹwaa (Wayẹẹki) ati pe esi idanwo to ṣe naa lo n duro de to fi ku lojiji.

 

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, juwe iṣẹlẹ ọhun bii eyi to buru jai, o ni o jẹ ohun ti ko ṣee gbọ leti pe ẹnikan gba ẹmi eeyan kan nitori epe ṣiṣẹ.

 

Ni kete ti iwadii ba ti pari lori ọrọ ọmọkunrin ọhun lo sọ pe yoo foju bale-ẹjọ.

(32)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.