Nitori ere “Yoruba Ronu”, Ijọba Akintọla fi ofin de Ogunde pe ko gbọdọ ṣere mọ

Spread the love

Ẹni to ba ni ki la o ṣe la a ṣe e fun ni ọrọ Oloye Ladoke Akintọla ati ijọba rẹ ni Western Region lati ibẹrẹ oṣu kẹta, ọdun 1964, ti wọn ti da ẹgbẹ Dẹmọ silẹ. Gbogbo ẹni to ba ti ni oun ko gba ti ẹgbẹ oṣelu naa, tabi ti ọkunrin Prẹmia naa, tabi ti igbakeji rẹ, ipo yoowu to ba wa, kia ni wọn yoo gba a lọwọ rẹ, tabi ki wọn le e danu si ẹgbẹ kan. Bi ọmọde ba si de ibi ẹru, ẹru yoo ba a, jinnijinni da bo ọpọ awọn eeyan agbegbe naa, afi awọn ti wọn ba n ba Akintọla ṣe nikan ni ọkan wọn balẹ, ẹni to ba loun ko gba, egele ni yoo gbe e. Nidii eyi, o loju ẹni to le duro ni West ko loun ko ṣe ti ijọba naa, nitori bii ẹni to n ranṣẹ pe wahala, ẹjọ, ati ijangbọn loriṣiiriṣii sọrun ara rẹ ni. Iyẹn lo fa a ti kaluku fi n lọọ fi tipatipa forukọ silẹ ninu ẹgbẹ Dẹmọ, awọn ti wọn ko si le forukọ silẹ n ranṣẹ pe awọn faramọ ẹgbẹ naa, koda titi dori awọn ọba alaye.

Nigba ti gbogbo ijọba ibilẹ ti n sọ pe awọn fẹ ti ẹgbẹ naa, ti Dẹmọ lawọn yoo ṣe, ijọba ibilẹ kan wa to fariga, bo si tilẹ jẹ pe wọn ko fi ọrọ naa ṣe ariwo, Akintọla ati Fani-Kayọde mọ pe alagidi ni wọn nibẹ, wọn ko si gba tawọn. Ijọba ibilẹ Muṣin ni. Alagidi ni wọn nibẹ loootọ, wọn ko si fi bo pe awọn ko faramọ gbogbo ohun ti Akintọla ati igbakeji rẹ yii n ṣe. Ṣe nigba ti ogun le gan-an, ti ọpọ eeyan n sa nigba ti awọn NCNC n ba AG fa wahala ni West, ko sẹnikan ti yoo gbe saara rẹ kọja mọṣalaṣi de Muṣin, wọn yọnda wọn jẹẹ ni, wọn fi wọn silẹ, nitori awọn naa mọ pe ẹni ba n wa wahala ni yoo lọọ tọ wọn nija ni Muṣin. Awọn Akintọla naa mọ pe wọn buru nibẹ, nitori ẹ ni wọn ko si ṣe meni, ti wọn ko ṣe meji, wọn tu ijọba ibilẹ ibẹ ka lẹsẹkẹsẹ, Fani-Kayọde paṣẹ pe awọn ko fẹ ijọba ibilẹ kankan ni Muṣin.

Nibi ijọba ibilẹ ni agbara awọn oloṣelu wa julọ, nitori ko si ijọba ibilẹ ti ko ni awọn oloṣelu ti wọn fi ara ti i lẹgbẹẹ, aṣẹ ti wọn ba si pa tabi eto ti wọn ba n ṣe ni ijọba ibilẹ kan ni yoo fun awọn oloṣelu ibẹ lagbara. Bi awọn ijọba ibilẹ yii ṣe waa lagbara to nigba naa, gbogbo awọn ijọba ibilẹ ti wọn wa ni Western Region, abẹ Fani-Kayọde ni wọn wa, nitori oun ni minisita to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ nile-loko, bo tilẹ jẹ pe oun naa ni igbakeji Prẹmia, iyẹn igbakeji Akintọla. Ohun tawọn mejeeji yii mọ daadaa ni, nigba to jẹ awọn naa ti pẹ nidii oṣelu, wọn mọ pe ijọba ibilẹ ni agbara awọn oloṣelu wa, oloṣelu to ba ni ijọba ibilẹ to pọ naa ni yoo le ṣe akoso odidi ipinlẹ kan. Iyẹn ni wọn ṣe n fẹ ki gbogbo ijọba ibilẹ gba tiwọn, nigba ti awọn ti Muṣin si n ṣe kan-n-ta kan-n-ta ni wọn ṣe gba wọn danu, wọn tu wọn ka.

Awọn oloṣelu ti wọn fẹẹ kọkọ maa ṣe akọ tẹlẹ, nigba ti wọn ti ri ohun to ṣẹlẹ si Kọla Balogun, ti wọn le e danu nile igbimọ, kia lawọn naa jokoo jẹ. Abi, abuku ọna meji ni wọn fi kan ọgbẹni naa, bo si tilẹ jẹ pe awọn eeyan mọ pe ọrọ oṣelu ni, sibẹ, ko sẹni to fẹ ki iru rẹ ṣẹlẹ si oun. Wọn yọ ọ kuro ni oye ilu rẹ nibi ti wọn ti bi i, bẹẹ ibẹ ni wọn ti fi i jẹ Jagun tẹlẹ, nigba ti wọn si ti gba oye ilu kuro lọwọ ẹ ni wọn ti yọ ọ kuro nile igbimọ awọn ọba ni West. Bẹẹ, ohun to fa iṣoro fun Kọla Balogun ni Ọtan Ayegbaju ni pe ọmọ ilu naa ni iyawo Akintọla funra rẹ, iyẹn Arabinirin Faderẹra, ibẹ ni wọn ti wa si Ogbomọṣọ, igbagbọ si ni pe nibi ti Akintọla ba n lọ, iru awọn eeyan bii Kọla Balogun gbọdọ tẹle e nitori ana rẹ ni. Amọ ọkan ninu awọn aṣaaju NCNC ni Balogun, iyẹn ni ko ṣe ba Akintọla ṣe, iyẹn naa ni wọn si fi le e.

Ohun to ṣẹlẹ si Balogun yii mu ọpọ awọn oloṣelu kori bọle, kaluku sa pamọ sinu ile rẹ, wọn ko fẹ ki wọn gba igba oyin lọwọ awọn. Eyi to si ya ọpọ awọn eeyan lẹnu ju ni ti awọn ọba alaye, pupọ ninu wọn ni ko le sọrọ, awọn ti wọn si sọrọ naa ko wi kinni kan gidi ju pe ibi ti Akintọla ba n lọ lawọn n lọ. Ni gbogbo igba yii, Awolọwọ ti wa lẹwọn, awọn eeyan si ti n ro pe awọn ọba yii yẹ ki wọn dide fun un. Ṣugbọn awọn ọba ko dide, pupọ ninu wọn gbagbe Awo sibi to wa, wọn si di ọrẹ Akintọla. Loootọ awọn mi-in ko fi tinu-tinu lọ o, to jẹ ki i ṣe inu didun wọn ni wọn fi n ba Akintọla ati ẹgbẹ Dẹmọ rẹ ṣe, ṣugbọn awọn mi-in ninu wọn lọ pẹlu erongba lati ri nnkan gidi jẹ ninu ijọba Akintọla ni, wọn mọ pe bi awọn ba ti n pọn Akintọla le, ti awọn si fun un laaye lati ṣe ohun to ba fẹẹ ṣe, tiwọn naa yoo dara lasiko naa.

Iyẹn ni Dauda Adegbenro ṣe kilọ fun wọn, ṣe Adegbenro ni olori awọn ọmọ ẹgbẹ Action Group bayii, oun lo ku to jẹ aṣaaju, nigba ti gbogbo awọn ẹlẹgbẹ rẹ to ku ti ba Akintọla lọ. Adegbenro lo n sare sọtun-un, to n sare si osi, oun naa lo si n ṣe eto gbogbo lati ri i pe ẹgbẹ AG ko ku pata, ati pe wọn ko gbagbe Awo sẹwọn, nitori gbogbo ohun to n lọ lo n lọ sọdọ rẹ lati lọọ sọ fun un. Awọn ọba ati awọn oloṣelu kan ti n kin in lẹyin tẹlẹ, iyẹn ni pe wọn n ti i lẹyin lati ṣe gbogbo ohun to n ṣe, afi lẹẹkan naa ti gbogbo wọn sa pada sẹyin, nigba ti wọn ri i pe gbogbo agbara pata ti wa lọwọ Akintọla. Adegbenro wo ijo buruku ti awọn ọba n jo bẹẹ, o wo awọn ọba ti wọn ti n sare tẹle Awolọwọ lẹyin tẹlẹ, ti wọn waa n sa iru ere kan naa lẹyin Akintọla, n lo ba jade si gbangba lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹta, 1964, o si kilọ fun wọn.

Adegbenro ni lati ọjọ naa lọ o, gbogbo ọba yoowu ti wọn ba ri to n sare kiri lẹyin Akintọla ati ẹgbẹ Dẹmọ rẹ, awọn ko ni i ka a si ọba mọ, awọn yoo ka a si oloṣelu gidi, awọn yoo si maa ṣe e bi awọn ṣe n ṣe awọn oloṣelu ni, awọn ko ni i wo o ni iwo ọba mọ, bẹẹ lawọn ko si ni i pe e bẹẹ. O ni bi awọn ba ti waa ri ọba kan bẹẹ, gbogbo agbara ẹgbẹ AG pata lawọn yoo gbe jade lati lo lori iru ọba naa, ti yoo si mọ pe agbo to tadi mẹyin ni, agbara gidi lo lọọ mu wa, ẹgbẹ AG ko ti i ku, ohun to n ṣẹlẹ lo n ṣẹlẹ, bo ba ya, ẹgbẹ naa yoo ji dide. Adegbenro ni oun ko fẹ ki wọn gbagbe ọrọ ti oun fẹẹ sọ fun wọn yii o, iyẹn lohun ko ṣe sọ ọ lẹnu lasan, to jẹ niṣe loun kọ ọ niwee, ti oun si fẹ ki gbogbo wọn gba a, ki wọn ka a ko ye wọn, ki wọn waa tọju rẹ fun ọjọ iranti. O ni awọn ọba kan n kọja aaye ara wọn o, awọn yoo si ṣina fun wọn.

Adegbenro sọrọ bayii pe, “Baba gbogbo araalu ni ọba n ṣe, wọn ko si gbọdọ ba wọn nidii oṣelu. Awọn ọba wa kan ti n daamu awọn eeyan ilu wọn, ti wọn n fi tipatipa sọ fun wọn pe ẹgbẹ Dẹmọ ni ki wọn ṣe. Ohun ti wọn fẹ kawọn eeyan wọn ṣe yii ni lati maa lọọ jẹ ounjẹ lọdọ awọn ọta wọn, wọn fẹ ki wọn maa lọọ ṣe ohun ti ko ni i dun mọ wọn ninu, wọn fẹẹ fi tipatipa fun wọn ni majele jẹ. Gbogbo araalu lo lẹtọọ lati ba ẹgbẹ tabi eeyan ti wọn ba fẹ ṣe, wọn si le rin si ibi to ba wu wọn, ofin ko si fi aaye gba ọba kan lati maa waa halẹ mọ awọn eeyan, tabi lati maa paṣẹ onikumọ fun wọn pe dandan, ẹnikan ni ki wọn ba ṣe; dandan, inu ẹgbẹ kan ni ki wọn wa. Ọba to ba n ṣe eleyii yoo fi ara rẹ wọlẹ gbẹyin ni, nitori awọn eeyan rẹ yoo koriira rẹ, nigba ti ija ba si de, wọn yoo doju ija kọ ọ!”

Awọn ọba kan gbọ ikilọ naa, wọn si gbiyanju lati fi ori ara wọn pamọ. Ṣugbọn awọn mi-in ko gbọ naa, wọn ti mu omi agbara lọdọ awọn aṣaaju ẹgbẹ Dẹmọ, kaluku wọn si ti gbagbọ pe ko si ohun ti ẹnikẹni le ṣe fawọn. Eto ti wọn ti ṣe tẹlẹ ni pe ilu Abẹokuta ni wọn yoo gbe olu ile Ẹgbẹ Ọmọ Ọlọfin si. Ṣe loootọ, ẹgbẹ gbogbo Yoruba ni, ṣugbọn awọn Ẹgba ni aṣaaju rẹ. Moses Adekoyejọ Majẹkodunmi ati Adajọ Adetokunbọ Ademọla mọ nipa rẹ daadaa, awọn ni wọn si da bii adari wọn, bo tilẹ jẹ pe wọn yan awọn oloye tuntun. Ṣugbọn lẹyin ti wọn ti da ẹgbẹ naa silẹ, ẹgbẹ ọhun ko ri nnkan gidi kan ṣe mọ, bẹẹ ni ko niyi laarin awọn Yoruba, eeyan ko si le fi i we Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa. Iyẹn ni ko ṣe si ẹni to fẹẹ gba a si ilu tirẹ pe ki wọn waa gbe e sibẹ, wọn ko si fẹẹ gbe e si Eko, ni wọn ba ni ki wọn gbe e lọ si Abẹokuta.

Nigba ti wọn ti n gbe kinni naa gẹgẹ pe wọn n gbe e lọ si Abẹokuta ni Adegbenro ti gbọ, n lo ba sare jade pe ki wọn ma gbe igbekugbe wa si ilu Ẹgba, nitori awọn ti wọn n gbe ẹgbẹ naa bọ nibẹ ki i gbe Abẹokuta, Eko ni wọn wa, wọn kan fẹẹ waa fi kinni naa da wahala sọrun awọn ara ilu naa ni. Adegbenro ni oun bẹ Alake Ademọla ko ma gba o, ko ma jẹ ki wọn gbe ẹru ẹlẹru waa ka Ẹgba mọle, nitori awọn ọmọ Ẹgba ẹyin-odi lo fẹẹ waa sọ ina sinu ile wọn, bi wọn ba si ti ju ina naa silẹ ni wọn yoo sa lọ si ibi ti awọn n gbe. Adegbenro ni ko si ohun to n jẹ Ẹgbẹ Ọmọ Ọlọfin, Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa ni gbogbo Yoruba mọ, awọn ọdalẹ lo n pe ara wọn lọmọ Ẹgbẹ Ọlọfin. Boya Alake lo ba wọn sọ ọ ni o, boya awọn aṣaaju ẹgbẹ naa ni wọn si da kinni naa ro funra wọn, wọn o sa gbe olu ile Ẹgbẹ Ọmọ Ọlọfin wa si Abẹokuta mọ.

Ṣugbọn boya ni ki i ṣe ohun to bi awọn Akintọla ninu si Hubert Ogunde to n ṣe ere tiata niyi o. Ogunde ti ni orukọ nla funra rẹ nilẹ yii ati ni oke-okun, gbogbo aye si ti mọ ọn gẹgẹ bii elere nla. Ṣugbọn nigba ti wọn da Ẹgbẹ Ọmọ Ọlọfin silẹ, oun ni wọn pe ko waa ṣere fun wọn, wọn ni ere rẹ yoo ba awọn agbaagba Yoruba naa mu. Nigba ti wọn de ibi ere naa ṣaa, ohun ti wọn ro kọ ni wọn tọ wo. Ere nla ti Ogunde kọ wa, to si gbe waa fi han wọn, ere kan to pe ni “Yoruba Ronu” ni. Itan ọba nla kan ti igbakeji rẹ dalẹ rẹ ni. Ọba alagbara kan to n ṣe daadaa fun awọn araalu, ti igbakeji rẹ waa lẹdi apo pọ pẹlu awọn ọta rẹ, ti wọn si le e kuro lori oye, ti wọn sọ ọ sinu tubu, ti wọn si gba ilu rẹ lọwọ rẹ, ti igbakeji rẹ wa n jaye kiri ilu, to n sọ pe ko si ewu kan mọ, to si n jẹ aye alabata kaakiri.

Bi a ba fẹẹ sọ ọ loootọ, ere naa ba Akintọla wi, nitori ohun to n ṣẹlẹ ni West ni Ogunde fi kọ ere rẹ. Ohun to fa a niyi to fi jẹ nibi ere naa ti awọn ọmọ Ẹgbẹ Ọlọfin pe Ogunde si, Akintọla binu jade nibẹ ni. Ibadan ni wọn ti ṣe e, ni Mapo Hall, awọn ero si ti lọ bii omi, Akintọla wa nibẹ pẹlu awọn alagbara ninu ijọba rẹ, bẹẹ ni awọn ọba alaye loriṣiiriṣii wa nibẹ pẹlu awọn ijoye wọn, ẹsẹ awọn ọtọkulu lo pe sibi ti Ogunde ti n ṣere rẹ. Imura Akintọla paapaa yatọ lọjọ naa, nitori to ti ro pe ọjọ ẹyẹ oun ni. Afi bi Ogunde ṣe bẹrẹ ere rẹ to jẹ oun lo n fi ere naa ba wi, to jẹ gbogbo ọrọ ti wọn n sọ ninu ere, gbogbo igbesẹ ti wọn n gbe nibẹ, bii ẹni pe Akintọla ni wọn n ba wi ni. Ṣe olowe si mọ owe rẹ, bi ko ba fẹẹ sọ si i nikan ni. Akintọla mọ pe oun lọrọ n ba wi, o mọ pe Ogunde waa fi ere Yoruba ronu bu oun ni.

Iyẹn lo ṣe dide paa, n lo ba binu jade. Bo ti binu jade ni awọn minisita ati awọn eeyan nla to ku naa tẹle e, ṣugbọn Ogunde ko tori iyẹn da ere rẹ duro, o pari ere naa kẹlẹlẹ. Ogunde ro pe kinni naa ti pari bẹẹ, oun ko si mọ pe ọrọ naa ṣẹṣẹ bẹrẹ ni. Ibi to ti kọkọ mọ pe ewu wa loko Longẹ ni nigba to fẹẹ gba owo ere to ṣe, ṣe dandan ni ki ẹgbẹ naa sanwo fun un, wọn ti ṣe adehun, o si ti sọ iye ti oun yoo gba lọwọ wọn fun wọn. Igba to reti owo ti ko ri i lo pe ẹni to waa pe e lere pe owo ere oun nkọ o, niyẹn ba sọ fun un pe oun yoo ṣeto bi yoo ti ṣe ri i gba. Lo ba di ọjọ kan o, ni wọn ba ni Adajọ Adetokunbọ Ademọla ni ko waa gba owo ere rẹ to ṣe. Ikoyi ni Ademọla n gbe, Yaba ni Ogunde n gbe, Ogunde si ni ki lo waa wa nibẹ toun yoo tori owo ere lọ si Ikoyi, ki wọn kọ ṣẹẹki ki wọn fi i silẹ fun akọwe, oun aa ni ki ọmọ oun kan waa gba a.

Ayọ Rosiji lo waa sọrọ naa fun un, o sa taku pe ko waa ri Ademọla. Ogunde tun ni mọto oun ko dara, ọkunrin naa ni oun yoo gbe e lọ, oun yoo gbe e bọ. Bẹẹ ni wọn ṣe lọ si ọdọ adajọ agba naa. Aṣe ọtọ ni ohun ti adajo tori ẹ pe Ogunde, oun o si mọ. Ohun ti adajọ pe e fun ni pe Ogunde fẹẹ ṣere ‘Yoruba Ronu’ ni Glover Hall lalẹ ọjọ keji, bẹẹ ni wọn si fẹẹ da ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti Awolọwọ pe lalẹ ọjọ naa, iyẹn ni Ademọla ṣe ranṣẹ pe e. Ohun to si sọ fun un ni pe ṣe bi oun ba dajọ ti oun tan ni ọsan, Ogunde yoo waa ko awọn eeyan jọ, yoo dajọ tirẹ fun wọn lalẹ. Ogunde ni ọrọ naa ko ye oun, adajọ yii ni kin ni ko ye e nibẹ, ṣebi ere ‘Yoruba Ronu’ to n ṣe kiri, ṣebi idajọ ti oun fun Awolọwọ niyẹn, ko si yatọ si idajọ ti oun adajọ agba da. O ni ko ma ṣe ere naa o, bo ba ṣe e, yoo fẹwọn jura.

Lẹyin ti adajọ Ademọla ti sọ ọrọ rẹ tan bẹẹ, Ogunde waa beere  pe owo ti wọn ni ki oun waa gba nkọ o, nigba naa ni adajọ yii sọ fun un pe oun kọ loun n sanwo ẹgbẹ, bo ba fẹẹ gba owo ere to ṣe, ko lọ sọdọ awọn ti wọn n sanwo ẹgbẹ, wọn yoo sanwo ẹ fun un, ko si eyi to kan oun ninu ẹ, ọrọ ti oun fẹẹ ba a sọ ti oun fi ni ko wa niyẹn. Eyi ja si pe ẹni to waa pe Ogunde tan an ni, o fẹ ki wọn halẹ mọ ọn, ki wọn si ri i pe ko ṣere naa lọjọ naa. Ogunde ti kọkọ ro pe oun yoo ṣere oun, ẹwọn ti wọn ba si fẹẹ sọ oun si ki wọn sọ oun sibẹ, ṣebi gbogbo aye yoo ba awọn gbọ ibi ti wọn ba ti n ro ‘ẹjọ́ọ wíwò’ ti wọn ti n jare, nigba ti ki i ṣe pe oun darukọ ẹnikankan ninu ere oun. Ṣugbọn awọn eeyan to sun mọ ọn gba a nimọran pe ko ma ṣe bẹẹ, wọn ni ko jẹ ki wọn dajọ wọn, ti wọn ba dajọ wọn tan, ko bẹrẹ si i ṣe ere rẹ kaakiri.

Ni Ogunde ba lọ sinu iwe iroyin Daily Times, o si polowo bi yoo ti ṣe ere rẹ ati awọn ibi ti yoo ti ṣe e laarin oṣu kẹta si oṣu kẹrin, ọdun 1964. Ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta, ni ikede naa jade ninu iwe iroyin Daily Times, awọn ibi ti wọn yoo ti ṣere naa ni Ile-Ifẹ, wọn ni awọn yoo lọọ bẹrẹ nibẹ nitori orirun Yoruba niyẹn. Bi wọn ba ti ṣere naa ni Ifẹ ni wọn yoo gbe e kọja lọ si Abẹokuta, o di Ileṣa, lẹyin naa ni Ibadan, Ondo Akurẹ, Ikarẹ, Ọka, Ọwọ Ado Ekiti, ti wọn yoo pada si Oṣogbo, awọn yoo si gba Ijẹbu-Ode ati Ṣagamu wa sile. Odidi oṣu kan ni wọn fẹẹ fi rin irin-ajo naa, nitori ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹrin, ni wọn yoo too ṣe ere naa ni Ṣagamu. Ere Yoruba Ronu yoo si kaakiri orilẹ Yoruba ninu oṣu naa.

Wọn ti ṣe ere naa ni Ile-Ifẹ ati Abẹokuta, ṣugbọn wọn ko jẹ ki wọn ṣe e ni Ileṣa, nitori ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 1964, ijọba Akintọla fi ofin de ẹgbẹ elere Ogunde, wọn ni wọn ko gbọdọ ṣe ere wọn nibi kankan ni Western Region mọ o.

 

 

(158)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.