Nitori ẹja, Jeremiah fada ge ọmọ ọdun mọkanla lọwọ

Spread the love


Lọwọlọwọ bayii, akolo awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni baba agbalagba kan, Jeremiah Obifor, ẹni ọdun mọkanlelọgọta wa bayii, nibi to ti n ṣalaye nnkan to fẹẹ fi ọwọ ọmọdekunrin kan, Goodluck Amechi, ṣe to fi wo sunsun, to si ge ọmọ naa lọwọ. Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni nnkan bii aago mẹjọ kọja ogun iṣẹju lojule kẹfa, adugbo Ajanaku, Okoko.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, obinrin kan, Doris Isaac, lo mu ẹsun lọ si teṣan ọlọpaa to wa l’Okoko lọjọ keje, oṣu yii, pe Jeremiah fi ada ṣa ọmọ ọbakan oun (foster son), torukọ rẹ n jẹ Goodluck Amechi, ọmọ ọdun mọkanla lọwọ. Ẹsun yii lo mu ki awọn ọlọpaa lọọ mu ọkunrin agbẹ naa. Lasiko ti wọn n fi ọrọ po Jeremiah, ẹni ọdun mọkanlelọgọta, nifun pọ lo jẹwọ pe oun ri Goodluck nibi eti odo ẹja oun. Baba to n gbe lojule kẹrinla, Isha Ibrahim Street, Mechanic Bus Stop, Mebamu, Okoko, naa sọ pe ero ọkan oun ni pe ọmọkunrin yii fẹẹ ji oun lẹja ko lọ ni, idi niyẹn toun fi sare fi ada doju ija kọ ọ, toun si fi ṣa ọwọ rẹ bọ silẹ.

Ṣa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, DSP Bala Elkana, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, o ni ọdọ awọn ni Jeremiah wa bayii, awọn si n fi ọrọ wa baba naa lẹnu wo ko le jẹwọ boya o ni nnkan mi-in to fẹẹ fọwọ naa ṣe to fi ge e. O ni ti iwadii awọn ba ti pari lawọn yoo wọ ọ lọ si kootu, nibi ti yoo ti koju igbẹjọ.

(58)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.