Nitori ẹgbẹrun kan Naira, Eegun na Isaac daku l’Ondo

Spread the love

Kayeefi ni iṣẹlẹ to ṣẹlẹ niluu Isẹmbaye, Oke-Igbo, ṣi n jẹ fun awọn eeyan pẹlu bi eegun kan ti wọn n pe ni eegun Ọlọjẹde ṣe ṣadeede na ọmọkunrin kan, Isaac Oyewale, lẹsẹkẹsẹ ni ẹjẹ bo o, to si daku lọ rangbọndan.

Ọsẹ to kọja niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lọjọ ****(I am still trying to get him to confirm the day), ni ikorita Ita-faaji, nibi ti awọn ọlọkada ti maa n ba ara wọn ṣere.

Ayọ ọdun eegun naa ni Isaac pẹlu awọn ẹgbẹ rẹ yooku ti wọn jọ jẹ ọmọ ẹgbẹ ọlọkada n yọ lọwọ ti eegun kan ti wọn n pe ni Mopo ọlọpaa fi ṣẹ yọ, taara lo si lọ sọdọ Isaac atawọn ọrẹ rẹ mi-in.

Owo ni wọn ni eegun naa n tọrọ lọwọ Isaac atawọn ọrẹ rẹ naa, to si n fi ẹgba ọwọ rẹ halẹ mọ wọn. Awada lawọn eeyan yii ba eegun naa ṣe pe awọn gan-an yoo gba owo ọwọ rẹ to ba ko o fun awọn.

Nibi ti wọn ti n sọ eleyii lọwọ ni ọkunrin olowo kan ti de pẹlu ọkọ jiipu, to si fun awọn ọdọ naa ni ẹgbẹrun kan Naira gẹgẹ bii owo ọdun eegun.

Wọn ni Eegun Mopo pin owo naa si meji, o si fun Isaac atawọn yooku rẹ ni idaji owo yii. Nibi ti wọn ti n tọju owo ti eegun yii fun wọn ni eegun mi-in ti wọn n pe ni Eegun Ọlọjẹ ti de, to si ni ki awọn ọdọ naa ba oun mu owo ọwọ wọn, nitori eegun ṣa ni ọkunrin naa fun lowo, ki i ṣe awọn.

Ọrọ yii lo dija laarin wọn, eyi to si fa a ti eegun naa fi bẹrẹ si i fi ọpa ọwọ rẹ na Isaac, bẹẹ eewọ ni niluu naa pe ti eegun ba ti n lu eeyan, ẹni naa ko gbọdọ na an pada.

Kiakia lawọn ọdọ naa tuka, nibi ti eegun yii si ti n lu ọmọkunrin naa lo ti daku mọ ọn lọwọ.

Nigba ti ara-ọrun yii ri i pe ọmọkunrin naa ti wa lagbede meji aye-atọrun lo fi i silẹ, awọn yooku Isaac lo si sare gbe e dide, ti wọn si rọ omi le e lori, to fi ji pada. Ileewosan aladaani kan to wa niluu naa ni wọn sare gbe e lọ, nibi to ti n gba itọju lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ.

(59)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.