Nitori egberun kan Naira, Anthony fi ayọọnu jo ọmọ rẹ

Spread the love

Laduugbo Ọka, niluu Ondo, ni Anthony Akinyọkun ti fi ayọọnu gbigbona jo ọmọ rẹ lara, o ni o ji ẹgbẹrun kan Naira mu.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, nigba ti wọn ni ọmọ ọdun mẹẹẹdogun naa ji baba rẹ lowo.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni baba ọmọ yii lo sọ fun iya rẹ pe oun yoo fi apa si ara ọmọ naa to fi jẹ pe manigbagbe ni yoo jẹ fun un.
Nigba ti ọmọ yii pada wọle ni Anthony pe e, o si fẹsun kan an pe oun lo mu ẹgberun kan Naira oun, nibi ti wọn si ti n sọrọ yii lo ti gbe ayọọnu to ti ki bọ ina le e lẹyin. A gbọ pe ọkunrin yii fi okun aṣọ de ọwọ ati ẹsẹ ọmọ yii ko ma baa sa lọ.
Nigba ti Anthony ṣilẹkun fun ọmọ naa tan, niṣe lo sa jade, eyi lo si fun awọn araadugbo naa lanfaani lati ri ọgbẹ ti baba yii da si ọmọ rẹ lara. Awọn araadugbo lo si fi iṣẹlẹ yii to ọlọpaa leti.
Kiakia ni awọn ọlọpaa teṣan Ẹnuọwa, niluu Ondo, ti waa gbe ọmọ naa lọ si ọsibitu, wọn si taari baba rẹ lọ si teṣan wọn.
Titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, ọsibitu aladaani kan ni ọmọ naa wa, nibi to ti n gba itọju, ti baba rẹ si wa ni teṣan awọn ọlọpaa, nibi to ti n ṣalaye tẹnu rẹ fun wọn.

(18)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.