Nitori Buhari: Tinubu ati Saraki bẹrẹ ija tuntun

Spread the love

Ki i ṣe pe ija naaṣẹṣẹ bẹrẹ, o kan jẹ pe bi ibo aarẹ tiwọn yoo di lọdun to n bọ ti n sun mọle, bẹẹ ni kinni naatun ru jade gau lẹẹkan naa ni. Ija laarin Aṣiwaju Bọla Tinubu ti i ṣe aṣaaju ẹgbẹ APC ati Waziri Bukọla Saraki tii ṣe olori ile-igbimọ aṣofin agba ni. Ko sohun meji to n fa ija yii, nitori Aarẹ Muhammadu Buhari ni. Awọn mejeeji ki i ṣe ọrẹ ara wọn tẹlẹ, wọn ko si fi bẹẹ sun mọ ara wọn, ninu ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ ni wọn wa. Nigba ti awọn Tinubu n ṣe ẹgbẹ AD, Saraki ati baba rẹ wa ninu ẹgbẹ ANPP, nigba ti awọn Tinubu si di ọmọẹgbẹ AC, Saraki ti wọle sinu PDP. Ṣugbọn nigba ti nnkan de lọdun 2013, ti awọn Saraki n binu si Aarẹ Goodluck Jonathan, ti awọn Tinubu naan binu si i, awọn mejeeji ati awọn mi-in bẹẹ parapọ, wọn si jọ da ẹgbẹ oṣelu ti wọn peni APC silẹ, lati igbanaa niwọn si ti jọ n ṣe.

Lẹyin ti wọn dibo yan Ọgagun Muhammadu Buhari gẹgẹ bii ẹni ti yoo du ipo aarẹ lorukọẹgbẹwọn ninu oṣu kejila ọdun 2014 ni kinni naa kọkọ ru laarin wọn. Igba yẹn ni wọn fẹẹ mu igbakeji fun Buhari, ti Tinubu si fi ara rẹ han gẹgẹ bii ẹni to yẹ ko di ipo naa mu, nitori ija ti awọn ja ki Buhari too wọle, ati pe eyi yoo fun awọn Yoruba ni idaniloju pe awọn jọ wa ninu ijọba naani. Saraki lo ṣaaju awọn ti wọndide pe kinni naa ko ni iṣee ṣe bẹẹ, ti wọn ni ko si bi Buhariyooṣe jẹ musulumi ti igbakeji rẹ naayoo jẹ musulumi, wọn ni ki Tinubu jokoo, wọn ko le fi i ṣe e, afi to ba fa ẹlomiiran kalẹ lo ku. Wọn fa ọrọ yii lọ, wọn fa a bọ, Tinubu lọọ ba Saraki pe ko jọọ, oun fẹran ipo naa, ṣugbọn Saraki taku pe oun ko le ti Tinubu lẹyin lati ṣe ohun to fẹẹṣe. Igba naa ni ija yii ti n ru tuu bii eefin.

Tinubu ko fẹran pe Saraki ko gbọrọ soun lẹnu, Saraki naako si fi bẹẹ gba ti Tinubu, o n ro pe bi Jagaban ti ṣe jẹ alagbara oṣelu ni Eko, bẹẹ loun naajẹ alagbara oṣelu ni Kwara tawọn. Aṣe kekereni ija naa, ija gidi ṣi n bọ niwaju ti ko sẹni to fura. Lọjọ ti wọn yoo dibo yan olori ile-igbimọ aṣofin ni, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹfa,ọdun 2015. APC ti wọle, gbogbo aye si ti n gbedii fun Tinubu pe oun nibaba, oun lo jẹ ki Buhari wọle, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Awọn Tinubu ti ni ẹni ti wọnyoo mu fun olori ile-igbimọ aṣofin agba ati kekere. Wọn fẹẹ mu Abdullahi Adamu gẹgẹ bii aarẹ ile-igbimọ nla, wọn yoo si mu Fẹmi Gbajabiamila fun ile-igbimọ aṣofin kekere. Awọn tawọn Tinubu fẹ niyẹn, ṣugbọn awọn kan wa ti wọn ko gba, wọn ni awọn mi-in lawọn fẹ, bawo ni Tinubu yoo ṣe wa nita ti yoo maa yan oloriawọn fawọn.

Ọrọ naa ti le, awọn Tinubu si ti mọ pe awọnko ni i le da kinni naa ṣe. Aarẹ Buhari ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni wọn fẹẹ lo lọjọ naa, ṣe iyẹn ti ni oun ko fẹẹba wọn da si ọrọ ile-igbimọ aṣofin. Bi wọnṣe fẹẹ lo o ni pewọn pepade kan ti wọn ni ko wa sibẹ. Ohun ti wọn fẹẹṣe nipade naa ni ki wọn sọrọ diẹ, ki wọn si fa Adamu ati Gbajabiamila sita pe awọn ni awọn mu gẹgẹ bii olori ile-igbimọ aṣofin agba, ko fọwọ si i fawọn. Awọn Tinubu ti mọpe bi Buhari ba ti ṣe bẹẹ, ko sẹni ti yoo tun yọ wọnpada mọ, bawọn aṣofin ba ti pada de ile-igbimọ, awọn ti wọn yoo yan naa niyẹn. Nidii eyi, awọn tiwọn n pepade naa kan ha lẹta ori-aago ni, wọn ni Buhari fẹẹba gbogbo awọn aṣofin APC sọrọ, ki wọn peju lati gba aarẹ tuntun lalejo. Ki i ṣe ile-igbimọ ni wọn fi ipade naasi, ibi kan ti wọn n pe ni Conference Centre ni.

Amọ bi awọn Tinubu ti n palẹ tiwọn mọ yii naani awọn Saraki ti gbọ, wọn ti mọ ero ọkan wọn, awọn naa si mọ ohun ti wọn yooṣe. Ni asiko ti awọn aṣofin diẹ kan, awọn aṣofin APC, ti gbara jọ si ibi ti wọn ni wọn ti fẹẹṣepade, tiwọn n reti Buhari, Saraki ti mu awọn aṣofin diẹ kan ninu APC, ati awọn pupọ ninu PDP, nigba ti wọn si wo iye wọn, ti wọn ri i pe wọn to awọn aṣofin ti wọn le jokoo ijiroro, wọn bẹrẹ ijiroro wọn, laarin iṣẹju kan sikeji, wọn ti yan Saraki bii aarẹ ile-igbimọ aṣofin. Bayii ni wọn ba gbogbo eto ti Tinubu ti to kalẹ jẹ, nitori ko sohun ti wọn le ṣe mọ, Saraki ti dolori. Ọrọ naajo Tinubu lara, o dun Buhari, ṣugbọn Buhari loun ko ni ida si i. N lawọn Tinubu ba bẹrẹ sii wa gbogbo naa lati yọ Saraki danu, ko si pẹ lẹyin eyi lẹjọ buruku bẹrẹ lọrun Saraki, ẹjọ owo kiko jẹ, Saraki si ni Tinubu lo n ṣe oun.

Latiigba yii ni ija ti bẹrẹ laarin awọn mejeeji, wọn si ja ija naa fun igba pipẹ ko too han si Tinubupe awọn ọmọọṣẹ Buhari ko ka oun naasi kinni kan, wọn fii wọlẹ, n loun naa ba rin sẹyin diẹ, ọrọ ija oun ati Saraki si lọ silẹ bo tilẹ jẹpe iyawo rẹ, Oloye Rẹmi Tinubu, ko fi Saraki lọrun silẹ nile-igbimọ, gbogbo igba lo n tẹ ofin rẹ loju, to si n ṣe bii ẹni pe oun lọga, ko si ohun ti Saraki yoo fi oun ṣe. Ṣugbọn kinni kan tun wa nilẹ to n fa ija naa ti ko jẹyọ sita, iyẹn naa si ni pe Saraki fẹẹṣe aarẹNaijiria, bẹẹ ni Tinubu naafẹẹṣe. Yatọ si pe Tinubu woye pe Saraki kere si iru ẹ, ibẹru wa fun unpe ti Saraki ba fi le jẹ kinni naa, yoo ṣoro foun ki oun too tun le bọ sipo aarẹ, nitori awọn mi-in yoo maape Saraki ni Yoruba, bo ba si gbe ipo silẹ ti oun Tinubu ba tiẹ si lagbara, wọn ko ni i jẹ koun ṣe e mọ.

Iyẹn lo fa idunnu fun Tinubu nigba ti Waziri fi ẹgbẹ wọn silẹ, to kuro ninu APC, to gba inu PDP lọ. Tinubu duro fun igba diẹ, lẹyin naalo gbe lẹta iyanu kan jade. O ni ki ẹnikẹni maṣe da Saraki loun, ole ati ojukokoro lo n pa alọ. Tinubu ni Sarakisa kuro ninu ẹgbẹ nitoriọna to daa lawọn n gba ni tawọn, oun ko si le gba ọna to dara. O ni o ti pẹ ti ọkunrinnaati fẹẹ di aarẹNaijiria, ko si le ni suuru ki Buhariṣe tirẹ tan, iyẹn lo fi fi ẹgbẹ silẹ lojiji, ki i ṣe nitori pe o fẹran awọn ọmọNaijiria, tabi pe boya ijọbaBuhari ko ṣe ohun to dara kan. Oni o daa gan-an bi Saraki ṣe fi ẹgbẹ awọn silẹ, nitoriẹgbẹ awọn yoo ni alaafia, awọn yoo si le dojukọ gbogbo nnkan daadaa ti awọn fẹẹṣe fun awọn ọmọ Naijiria, Buhari yoo le pada wa lẹẹkeji, yoo si ṣe oore to wa lọkan rẹ fun gbogbo ilu pata. Tinubu ni kẹnikẹni ma daro pe Saraki lọ ninu ẹgbẹawọn, nitori olojukokoro ni, ojukokoro rẹ lo si n ti i kiri.

Ọrọ naadun Saraki gan-an, ko si jẹ ko tutu, lọjọ keji loun naati gbe lẹta tirẹ jade. N loun ba tun tu aṣiri kan ti ọpọ eeyan ko gbọ ri. Oni ọjọpẹti oun ti n rẹsipẹẹti Tinubu o, ṣugbọn nigba ti agbalagba ba n ṣe aṣeju, tabi ti ko mọ eyi to kan mọ, afi ki awọn da a lohun ohun to ba sọ. O ni Tinubu ti sọ foun pe koda ki Buhari fẹẹ ku toni-tọla, koda koma ṣe ijọba daadaa rara, oun yoo tẹle e ni gbogbo ọna, oun yoo si ti i lẹyin ti akoko rẹ yoo fi to, nitori oun fẹ ko jẹ oun ni yoo gbejọba fun lọdun 2023. Saraki ni lasiko ti wọn ni ki Tinubu pari ija inu APC, o diidi waaba oun ni, o si sọ pe awọn ọmọẹyin Buhari ti fi oju oun naagbolẹ daadaa, ṣugbọn oun ko ni i tori ẹ pada lẹyin Buhari, nitori ohun to wa lọkan oun. Saraki waa beere peninu oun ati Tinubu, ta ni ko tori araalu ṣe oṣelu ninu awọn.

Nibi ti ọrọ naa wa ree, bawọn ọmọọṣẹ Tinubu ti n mura ija, bẹẹ naa lawọn aṣofin ti wọn fẹ ti Saraki, ohun to si daju ni pe ọrọ naa yoo le ju bayii lọ, ibi ti yoo yọri si nikan la o mọ.

 

 

 

 

 

Ile ti wọn ni ki Gabriel maa ṣọ lo ti jale n’Idanre, ipinlẹ Rivers lọwọ ti tẹ ẹ

(44)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.