Nitori Buhari: APC TI PIN SI MEJI-MEJI NILẸ YORUBA

Spread the love

Fun igba akọkọ, inu Aarẹ Muhammadu Buhari ko dun rara si awọn ti wọn n pe ara wọn ni aṣaaju APC. O si fi ẹhonu han, o jẹ ki wọn mọ pe inu oun ko dun si wọn rara. Baba yii ki i ṣe bẹẹ tẹlẹ, ọrọ gbogbo ni yoo fi ṣe ẹrin rin, tabi ko sọ pe oun ko le maa ṣiṣẹ ijọba ki oun tun maa daamu nidii ọrọ oṣelu, ki awọn aṣaaju ẹgbẹ ti awọn fa ẹgbẹ le lọwọ maa lọọ ṣiṣẹ wọn. Bo ti ṣe n ṣe lati ọjọ to ti gbajọba niyẹn, awọn eeyan si ti mọ iwa naa mọ ọn, wọn aa ni Baba ko kuku ni i wi nnkan kan. Ṣugbọn nibi ti wọn ba oṣelu naa de lọsẹ to kọja yii ba Baba yii lẹru debii pe ko le fi ọrọ si abẹ ahọn sọ mọ, bẹẹ ni ko si le gbe oju sẹgbẹẹ kan lori awọn ohun to n ṣẹlẹ, iyẹn lo jẹ ko pariwo pe oun ko fẹ bi nnkan ṣe n lọ. Loootọ lawọn aṣaaju ẹgbẹ sare sunraki, ṣugbọn o jọ pe ọrọ naa ti kọja ere ọmọde, afi ki wọn mura si i ju bẹẹ lọ.

ALAROYE gbọ pe awọn aṣiri kan ti bẹrẹ si i tu si Buhari funra rẹ lọwọ bayii, awọn aṣiri naa si ni pe ọpọ ọrọ ti awọn to sun mọ ọn sọ fun un ki i ṣe ootọ, irọ pọ ninu ẹ, wọn n tan oun ni. Ohun ti awọn n gbe si i niwaju tẹlẹ ni pe ni gbogbo origun mẹrẹẹrin Naijiria ni wọn ti fẹran rẹ, gbogbo awọn eeyan lo fẹ ki oun tun maa bọ lẹẹkeji, ko sẹni kan ti ko ni i dibo foun. Ṣugbọn oun naa bẹrẹ si i foju ara rẹ ri i, paapaa latari ọrọ ti awọn Ojiṣẹ Ọlọrun ti wọn jẹ ọmọlẹyin Kristi n sọ ranṣẹ si i, to si jẹ gbogbo awọn eeyan yii lo wa lẹyin ẹ tẹlẹ. Eyi lo jẹ ko bẹrẹ si i gbọ ọrọ lẹnu  iyawo ẹ ju ti tẹlẹ lọ, to si ṣeto lati maa ri awọn iwe iroyin kọọkan to ba sọ aidaa nipa rẹ. O ba a lojiji nigba to ri i pe ko si iwe iroyin kan ti ko sọrọ lile si i, titi dori awọn iwe iroyin ti wọn jẹ ti awọn ọmọ ẹgbẹ wọn, APC ati tawọn ti wọn n tẹle e kiri.

Kekere leleyii lọkan rẹ tẹlẹ, afi nigba ti nnkan nla yọ si i lasiko ibo abẹle ti APC di kọja lọ. Ọrọ naa ko le ba a lojiji to bẹẹ bi ki i baa ṣe pe awọn ti wọn jẹ aṣaaju ẹgbẹ yii ti lo gbogbo ete ti wọn mọ, ti wọn wa gbogbo ọna, pe ko ma wulẹ pada wa si Naijiria, ko jokoo siluu oyinbo nibi to ti lọọ gba itọju lọsẹ to kọja lọhun-un. Wọn ni bi ibo ba ṣe n lọ si awọn yoo maa sọ fun un, ati pe ko si wahala kan ti yoo ṣelẹ lasiko ibo naa. Bo ba jẹ Buhari gbọ tiwọn, to si jokoo si ilu oyinbo loootọ ni, gbogbo ohun to ṣelẹ ninu ibo abẹle APC yii, ko si eyi ti yoo gbọ nibẹ rara. Bi wọn ba tiẹ sọ fun un, wọn o ni i gbe ọrọ naa kalẹ lodidi fun un, wọn yoo kan ni awọn eeyan kan n halẹ, awọn alatako awọn, wọn fẹẹ da ibo ru nibẹ, ṣugbọn lẹsẹkẹsẹ lawọn ti yanju ẹ.

 

Ohun ti Buhari funra rẹ ri lasiko ibo naa ka a lara kọ. O ba a lẹru paapaa, igba akọkọ si niyẹn ti oun naa yoo ronu pe abi oun ko ni i wọle ibo lẹẹkeji ni. Ija rẹpẹtẹ ti wọn ja kaakiri ni, nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ APC ti pin ara wọn si meji-meji, ti wọn si dibo abẹle bii ẹni to lọ si oju ogun. Lati ipinlẹ Kano titi de Zamfara, ati titi wọ Delta titi de Imo, wahala naa ko yọ wọn silẹ rara. Ni gbogbo awọn ibi yii, ọna meji-meji ni wọn ti ṣe ipade ẹgbẹ APC, ọna meji-meji ni wọn ti dibo, awọn alaga ati ọmọ igbimọ apaṣẹ meji-meji ni wọn si yan kaakiri. Itumọ ti eleyii mu wa ni pe nitori Buhari funra rẹ ni gbogbo eleyii fi waye, bi awọn kan ti n du u pe ko wọle pada, bẹẹ ni awọn kan wa ti wọn ko fẹ ko wọle mọ, awọn ọta rẹ ni wọn n ba ṣe. Iṣoro to waa ni nibẹ ni pe oun paapaa ko da awọn ti wọn ṣe toun mọ, afi ọrọ tawọn to sun mọ ọn yii ba sọ.

Ninu gbogbo ẹ ṣaa o, Alaroye gbọ pe eyi to ko Buhari laya soke ju ni ti ohun to ṣẹlẹ ni ilẹ Yoruba, nibi to fẹrẹ jẹ ipinlẹ gbogbo ni wahala ti ṣẹ yọ. Lati Kogi titi wọ Kwara, ati lati Ondo titi wọ ipinlẹ Ọyọ, ohun to ṣẹlẹ ni ipinlẹ Eko sọ idi Aarẹ domi. Aarẹ funra rẹ mọ pe Saraki ko fẹran oun mọ, o si mọ pe olori ile igbimọ aṣofin naa kan n fọgbọn tu oun ni, bo ba ṣe pe o ni ọna tabi agbara, bi yoo ti yọ oun danu ki ọjọ idibo too pe ni yoo ṣe. Ohun ti ko waa mọ ni pe ọkunrin naa ṣii lagbara rẹpẹtẹ bẹẹ ni Kwara, nitori bo tilẹ jẹ pe Lai Muhammed toun naa wa lati Kwara ti dannu daadaa fun Buhari ati awọn eeyan Buhari pe oun maa gba APC kuro lọwọ Saraki nibẹ, ohun ti wọn ri lọjọ idibo abẹle naa ṣọọki wọn. Ati Gomina ibẹ, ati gbogbo awọn kọmiṣanna, atawọn ti wọn lẹnu ninu ẹgbẹ ọhun, ọdọ Saraki ni gbogbo wọn pata lọ.

Loootọ ni Lai Muhammed naa pe ode tirẹ, kinni naa ko gba a to bo ti ro pe yoo ri rara. Ni ti Kogi, odikeji ohun to ṣẹlẹ ni Kwara lo ṣẹlẹ nibẹ. Kaka kawọn eeyan rọ lo si ijokoo ti Gomina Yahaya Bello, ọdọ awọn aṣaaju ẹgbẹ ti wọn ti mọ tẹlẹ ni wọn lọ, ti wọn si dibo fun awọn eeyan tiwọn. Buhari mọ pe ko sohun ti Dino Melaye ko le ṣe lati ri i pe oun ko wọle pada si ipo aarẹ, bakan naa lo si mọ pe ọkunrin naa lagbara o si lẹnu nidii oṣelu ni Kogi. Ṣugbọn o ti pẹ ti Bello ti n sọ fun un pe ko ma yọ ara rẹ lẹnu, oun yoo gba Kogi ati agbegbe rẹ pata fun un, ko si sohun ti Dino yoo ṣe. Ibo ti wọn waa di naa ko fi ọkan ẹnikẹni balẹ ninu awọn ti wọn n tẹle Buhari, o si han pe ti APC yoo ba wọle ibo to n bọ ni Kogi, afi ti wọn ba fi ti Dino ṣe. Bẹẹ ni ko jọ pe Dino yoo ba wọn ṣe mọ, ibo ti wọn si ṣẹṣẹ di kọja yii ti tun fun un lagbara si i.

 

Bakan naa ni Buhari atawọn eeyan ẹ ti gbojule Adebayọ Shittu ni ipinlẹ Ọyọ, gbogbo ohun ti wọn si ro ni pe bo ba ya looro, Shittu yoo ran an; bo si ya nibuu, Shittu yoo ran an, nitori wọn ko mọ eyi ti Gomina Ajimọbi n ṣe gan-an, boya ti Buhari lo n ṣe ni o, tabi tawọn eeyan to lodi si i. Aya wọn ko ja tẹlẹ, wọn ti mọ pe bi awọn ba ti le gba ẹgbẹ APC ipinlẹ naa kuro lọwọ rẹ, agbara ọwọ rẹ ti bọ niyẹn. Ajimọbi ko jẹ ki wọn ri APC naa gba ṣaa o, bo si tilẹ jẹ pe ipade meji ni wọn ṣe loootọ, ọdọ tirẹ ni awọn ero pọ si ju, awọn alaṣẹ ẹgbẹ ko fi i silẹ, awọn ti ko fi bẹẹ lorukọ rara ni wọn lọọ jokoo sọdọ Shittu, yoo si ṣoro keeyan too fi ero atawọn eeyan gidi ti wọn wa lọdọ Ajimọbi we ti Shittu. Eleyii naa ki i ṣe ohun ti Buhari fẹ, bi nnkan ṣe n lọ si ko si ye e. Bawo ni ẹgbẹ APC ṣe n pin si meji-meji kaakiri yii, ohun ti wọn sọ pe o n beere niyẹn.

Eyi ti wọn sọ pe o waa ba a lẹru ju ni ti Eko, nitori lati ọjọ ti wọn ti n ṣe APC yii, ko ni ijaya kan ninu Aṣiwaju Bọla Tinubu ri, o mọ pe ibi ti ọkunrin ti wọn n pe ni Jagaban naa ba lọ ni gbogbo Eko n lọ. Aṣe ọrọ atijọ ni, o ya a lẹnu pe awọn kan le dide ki wọn koju Tinubu, ki wọn si ta ko o, ki awọn naa ṣe ipade tiwọn lọtọ, ki wọn si yan awọn alaga ati oloye ẹgbẹ tuntun. Ohun ti wọn ṣe fun Tinubu niyẹn, ọtọ ni alaga ti oun yan, ọtọ si ni alaga ti awọn ti ko fẹ tirẹ mọ yan. Buhari mọ pe nitori oun ni gbogbo eleyii ṣe n ṣẹlẹ, nitori awọn ti ko fẹ toun ni. Bẹẹ Buhari ti gbojule ibo Eko pupọ, o mọ pe ti wọn ba ti dibo ni Kano foun tan, Eko lo tun ni ero rẹpẹtẹ to le fi ibo gbe oun wọle, iyẹn lo ṣe gbojule Tinubu. Ṣugbọn nibi ti ọrọ waa de duro yii, Olori Naijiria naa ko mọ eyi ti yoo ṣe. Bẹẹ ni tododo, ẹgbẹ APC ti pin si meji-meji, paapaa nilẹ Yoruba yii, bi wọn ko ba si tete so wọn pọ, ewu nla ni fun Buhari lọjọ idibo o.

 

(75)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.