Nitori biliọnu meji aabọ to poora, PDP ni ki Buhari le Kawu danu

Spread the love

Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Kwara ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari lati juwe ile fun ọga agba ajọ to n sakoso igbohun-safẹfẹ lori redio ati tẹlifisan, NBC, Mallam Ishaq Modibbo Kawu, lori ẹsun biliọnu meji aabọ Naira to poora lakata rẹ.

Ninu atẹjade kan ti alukoro PDP nipinlẹ Kwara, Tunde Ashaolu, gbe sita ni Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, ẹgbẹ naa ni igbesẹ ọhun ṣe pataki lẹyin ti ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu ati lilu owo ilu nilokulo, ICPC, ti fidi rẹ mulẹ pe loootọ ni ọkunrin naa lẹjọ lati jẹ lori owo ọhun.

Ẹgbẹ PDP to gboṣuba kare fun ijọba apapọ bo ṣe wọ Kawu lọ sile-ẹjọ giga l’Abuja tun ni o yẹ ki ọkunrin naa atawọn to mọ nipa ọrọ ọhun gba ile wọn lọ ni gbogbo asiko ti wọn maa fi jẹjọ.

Bakan naa ni wọn ke si ajọ ICPC lati ṣewadii minisita feto iroyin ati aṣa,  Alhaji Lai Mohammed, to lọwọ ninu eto Digital Switch-Over, DSO.

Atẹjade naa ni: “A mọ daju pe ileeṣẹ to n ṣe akoso iroyin, eyi ti Lai Mohammed jẹ olori nibẹ lo n ṣe akoso ẹka NBC, fun idi eyi, o yẹ ki wọn ṣewadii oun naa. Ileeṣẹ Aarẹ ko gbọdọ gbiyanju lati dọwọ bo Lai Mohammed rara.

“Ni akotan, a rọ gbogbo awọn araalu nipinlẹ Kwara lati ṣọra fun awọn to n dibọn bii ẹni ja ija ominira. O jẹ ohun iyalẹnu pe awọn to n pe ara wọn ni eeyan mimọ fun araalu la tun n ba ninu iwa ibajẹ. Erongba wọn ni lati sọ wa di ẹru labẹ awọn ọga wọn to wa niluu Eko, ki wọn si ko gbogbo ọrọ araalu fun awọn to n ṣagbatẹru wọn yii”.

 

 

 

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.