Nitori awọn minisita tuntun: AWỌN ARAALU BINU SI BUHARI

Spread the love

Wọn ni ole pọ ninu awọn to ko jọ

Ọpọlọpọ awọn araalu ti wọn mọ nipa eto ijọba ati ọrọ oṣelu ni inu wọn ko dun rara si Aarẹ Muhammadu Buhari. Lori ọrọ awọn minisita tuntun ti Aarẹ ṣẹṣẹ yan ni o, awọn eeyan kan ni inu awọn ko dun si ohun to ṣe rara, inu ọpọ si bajẹ, nitori ohun ti wọn ro pe yoo ṣẹlẹ lati ọdọ Aarẹ kọ lo ṣẹlẹ. Nigba ti Buhari ti wọle lati oṣu keji, ọdun yii, to si ti han pe oun naa ni yoo di aarẹ, awọn eeyan ti ro pe lati igba naa ni yoo ti maa ṣeto awọn minisita rẹ silẹ ni, ti yoo si ti yan awọn minisita naa ni gbara ti wọn ba ti bura fun un. Ṣugbọn ko ṣe bẹẹ, titi ti wọn fi bura fun un ninu oṣu karun-un, iyẹn lẹyin oṣu mẹta to ti wọle gẹgẹ bii aarẹ. Awọn eeyan tun waa ro pe bo ti wọle nni, laarin oṣu kan pere, yoo ti darukọ awọn ti yoo ṣe minisita fun gbogbo ilu ni. Buhari ko tun ṣe bẹẹ, ohun to sọ ni pe oun fẹẹ mọ awọn ti oun yoo fi ṣe minisita asiko yii, awọn toun mọ loun fẹẹ mu.

Bo ti wi bẹẹ ni gbogbo awọn eeyan dakẹ, ohun to si fa a ti wọn fi dakẹ naa ni pe ọrọ ti aarẹ sọ yii di awuyewuye lasiko ijọba rẹ to kọja lọ yii. Nigba ti wahala pọ ti awọn minisita to yan ko ṣiṣẹ gidi kan ti araalu ri, ti awọn eeyan si bẹrẹ si i pariwo, iyawo rẹ, Arabinrin Aishat Buhari jade, o ni ọkọ oun ko mọ ọpọlọpọ ninu awọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ yii, o ni awọn kan ni wọn kan yan wọn, awọn ni wọn darukọ wọn ti wọn si fa wọn le Buhari lọwọ, Buhari ko mọ awọn eeyan naa rara, ko si mọ boya wọn le ṣiṣẹ tabi wọn ko le ṣe e. Nigba ti Aarẹ waa sọ pe awọn ti oun mọ funra oun loun fẹẹ mu lasiko yii, awọn eeyan ti wọn ti fẹẹ maa sọrọ pe ko tete yan minisita rẹ sinmi, wọn ni bo ba jẹ ohun ti aarẹ fẹẹ ṣe niyi, ko si ohun to dara to o, nitori to ba jẹ awọn eeyan to mọ lo yan, ko ni i si idaduro kan lẹnu iṣẹ ijọba, iṣẹ yoo maa lọ werewere ni. Ni kaluku ba n reti awọn to fẹẹ mu.

Alaaji Lai Muhammed

Amọ nigba ti Buhari kede awọn eeyan yii, ibanujẹ ba pupọ ninu awọn ti wọn ti n reti pe Aarẹ yoo de pẹlu awọn nnkan tuntun ni. Akọkọ ni pe awọn eeyan to ti lo tẹlẹ ti awọn araalu ko si ri iṣẹ gidi kan lati ọdọ wọn, ti wọn ko mọ iyatọ, ti wọn ko si ri ami kan pe awọn eeyan naa jẹ minisita, awọn naa lo tun da pada sibi iṣẹ naa, to si ni ki wọn tun waa ṣe minisita oun lẹẹkan si i. Lara awọn wọnyi ni Rotimi Amaechi, Chris Ngige, Abubakar Malami, Adamu Adamu, Lai Muhammed, Raji Faṣọla ati awọn mẹfa mi-in. Lọrọ kan, ninu awọn ti Buhari ni oun ko mọ nijọsi, mejila lo tun da pada ninu wọn. Ohun ti awọn eeyan n ro kọ niyi, wọn lero pe awọn tuntun kan ni yoo de ti wọn yoo si waa ṣe iṣẹ to le mu idagbasoke ba Naijiria, nitori gbogbo wọn yii lo ti lo ọdun mẹrin tẹlẹ, ko si sẹni kan to ri iṣẹ gidi kan to ti ọdọ wọn jade ninu ijọba naa.

Wọn sọrọ Lai Muhammed pe ọkunrin naa ko ṣe iṣẹ meji ju ariwo eke ati irọ pipa taara faraalu lọ ni gbogbo igba ti Buhari fi ṣejọba ọdun mẹrin to kọja. Bakan naa ni Ngige ko ri ọrọ awọn oṣiṣẹ ijọba yanju, asiko ti wọn si n palẹmọ iyanṣẹlodi mi-in ni wọn tun kede orukọ rẹ sita. Ọna pataki kan ṣoṣo to wa ti Raji Faṣọla ni oun dojukọ, to si jẹ ọdọọdun ni owo ti wọn fi n ṣe ọna naa n le si i ni ọna Eko si Ibadan, ṣugbọn fun ọdun mẹrin to fi ṣejọba, ọna naa ko yanju, bẹẹ ijọba Jonathan ti n ṣe kinni naa lọ tẹlẹ, awọn eeyan si ti ro pe ọwọ kan ni Faṣọla yoo pari rẹ ni. Faṣọla yii ti ṣalaye nigba kan nigba to n ṣe gomina Eko pe ọrọ ina ijọba nini ko gba wahala, nitori aye ti laju daadaa debii pe eeyan le da ṣe ina ẹlẹtiriiki ninu ile rẹ tabi ni adugbo tirẹ nikan, ti ina yoo si maa tan nibẹ. Eyi lo ṣe jẹ kawọn eeyan maa dunnu nigba ti wọn gbọ pe Faṣọla lo wa nidii eto ina ijọba.

Gomina ana, Alaaji Rauf Aregbesola

Ṣugbọn fun ọdun mẹrin ti ọkunrin naa lo lakọọkọ yii, ko ri ọrọ ina naa yanju, koda, iyatọ to wa ninu bi ina ti wa laye awọn Jonathan ati ti asiko yii, bo ba wa rara, diẹ naa ni. Ko sẹni ti yoo gbagbe ariwo ti Rotimi Amaechi pa lori redio ati tẹlifiṣan, ati bo ṣe n ko awọn oniroyin kiri, to n sọ pe ọna oju-irin Naijiria ti pari, awọn si ti ra ọkọ oju-irin tuntun ti yoo maa ko awọn ero kaakiri si i. Aṣe nitori ti ibo n bọ lo ṣe n pariwo bẹẹ, to si fẹ ki wọn dibo fun ọga oun. Lẹyin ti wọn ti dibo tan, ọkunrin naa ko ya si idi iṣẹ ọna ọkọ reluwee yii mọ, koda, boya si lo ranti pe oun sọ fawọn eeyan pe ninu oṣu karun-un, ọdun yii, ni reluwee yoo ti maa lọ ti yoo maa bọ lati Eko si Ibadan, ti wọn yoo si maa gba Abẹokuta kọja. Ẹyọ kan pere ninu ogunlọgọ irọ ti Amaechi yii pa fawọn araalu lasiko ijọba wọn niyẹn, ko si si iṣẹ kan ti oun naa le tọka si pe oun ṣe, yatọ si iṣẹ ti ijọba to kọja lọ ti ṣe.

Bakan naa lo ri fawọn minisita atijọ yii, awọn araalu ko si reti wọn pada ninu ijọba tuntun yii, ohun ti wọn sọ ni pe omi tuntun ti ru, ẹja tuntun yoo wọ inu omi, Buhari yoo yi nnkan pada, awọn minisita tuntun ti yoo ba a ṣiṣẹ yoo fi eleyii han bo ba darukọ wọn. Igba to darukọ awọn minisita tuntun yii paapaa, ibanujẹ awọn eeyan naa le si i ni, inu si bi pupọ ninu wọn pe ki lo de, ee ti ṣe ti Buhari n ṣe bayii gan-an! Ohun to fa a ni pe ọpọ ninu awọn ti Buhari mu wa yii, awọn ọdaran ti wọn lẹjọ gidi niwaju awọn EFCC tabi ICPC ni wọn, awọn ẹjọ owo nla, to si han gbangba pe nitori ọrọ naa ni wọn ṣe n sa kiri, ti wọn si fi ẹgbẹ oṣelu ti wọn n ṣe tẹlẹ silẹ, ti wọn sa wa sinu ẹgbẹ awọn Buhari, ki aṣiri wọn le bo, ko ma si ẹni ti yoo le mu awọn mọ. Lara awọn yii ni Godson Akpabio, Tymre Sylvia, Uche Ogarm, ati awọn mi-in bẹẹ.

Ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni Akpabio tẹlẹ, igba ti EFCC n ba a ṣe ẹjọ pe o ko biliọnu mejidinlaaadọfa (N108) billion jẹ nigba to fi n ṣejọba, ti wọn si n fi ẹjọ naa daamu rẹ, lo fi ija to wa laarin Buhari ati Saraki kẹwọ, lo ba bẹ jade ninu ẹgbẹ wọn tẹlẹ, o si gba inu APC lọ. Orukọ APC lo fẹẹ fi di aṣofin nibẹ, ṣugbọn awọn eeyan to wa lọhun-un ja a kulẹ, wọn ni awọn ti mọ pe ole ni, pe oju lo n ti i kiri, iwa to si hu lo n tori ẹ wa ibi ti yoo foripamọ si. Wọn ko dibo fun un pẹlu gbogbo ariwo to pa. Amọ lati igba to ti di ọmọ APC yii ni awọn EFCC ti tẹ siloo fun un, wọn ko gbe ọrọ rẹ lọ si ile-ẹjọ bi wọn ti n ṣe tẹlẹ mọ, wọn dakẹ, wọn n woye ohun to fẹẹ ṣẹlẹ. Ọkunrin naa ti di minisita bayii, oun ati awọn Festus Keyamo, lọọya awọn EFCC to n ba a ṣẹjọ ni wọn yoo si jọ maa rẹrin-in sira wọn bayii. Ọpọ awọn lọọya ti wọn ja fun Buhari tẹlẹ ni wọn binu lori ọrọ Akpabio yii, wọn ni ki lo de gan-an!

Amọ bi wọn ti n sọrọ Akpabio yii, o ku ti ọkunrin kan ti wọn n pe ni Uche Ogar. Lara awọn ti wọn ni wọn jale owo epo NNPC nijọsi loun. Awọn ti wọn yoo ni awọn ba NNPC ra epo lati ilẹ okeere, ti wọn yoo fi orukọ ileeṣẹ kan ti ko si laye ra a, ti wọn yoo ni awọn gbe epo naa wọle, ṣugbọn ti ko sẹni ti yoo ri epo, to jẹ korofo lasan ni wọn gbe wọle, ti wọn yoo si gba owo epo naa, ti wọn yoo pin in laarin ara wọn. Nigba ti wọn mu ọkunrin yii ni 2012, biliọnu marun-un ni wọn ni ko da pada. O da biliọnu kan ati miliọnu lọna ọgọrun-un meji pada nibẹ, biliọnu mẹta ṣi wa lọrun rẹ ti ko ti i san titi di asiko yii. Bi a ti waa n wi yii, Buhari ti fi ọkunrin ti EFCC n ba ṣe ẹjọ lile kan naa ṣe minisita, o si daju pe EFCC yoo jawọ ninu ọrọ rẹ kiakia ni. Bẹẹ ni EFCC gba ile mejidinlaaadọta lọwọ Timiprer Sylva, wọn si lo tun ji biliọnu mọkandinlogun gbe nigba to fi n ṣe gomina Bayelsa, ọrọ rẹ ṣi wa nile-ẹjọ.

Ṣugbọn ọkunrin naa ti gbọn ju, o yaa sare wọ inu ẹgbẹ APC, bẹẹ ni ijọba Buhari ni ki wọn fi ẹjọ naa silẹ fun un, wọn si da ile rẹ pada, bi a si ti n wi yii, ọkan ninu awọn minisita ni. Yatọ si awọn yii, pupọ ninu awọn ti Buhari yan ni wọn ni ẹjọ oriṣiiriṣii, eleyii si ni ariwo ti awọn eeyan n pa pe awọn ko ro iru eleyii si Buhari, ko jẹ awọn ti EFCC n le kiri ni yoo pọ ninu awọn to fi ṣe minisita, wọn ni ọrọ naa yoo lẹyin, nitori yoo ṣoro ki EFCC too le ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ, tabi ki ọwọ awọn eeyan ti wọn ti jale owo ilu tẹlẹ yii too mọ nile ijọba. Ṣugbọn awọn EFCC ti sọrọ, wọn ni awọn ko ni i tori ipo minisita ma ṣe ẹjọ awọn mọ, bẹẹ ni awọn ko si ni i jẹ ki ẹni yoowu to ba kowo-jẹ lọ lai farapa. Awọn araalu o gba wọn gbọ ṣaa, wọn ni bi wọn yoo ti ṣe eyi ti wọn wi yii, oju gbogbo awọn naa ni yoo ṣe.

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.