Nitori awọn ẹgbẹ wọn tawọn ọlọpaa fiya jẹ, ẹgbẹ awọn agbẹjọro nipinlẹ Kwara fẹẹ pẹjọ

Spread the love

Iwadii ti fihan bayii pe ẹgbẹ awọn amofin nipinlẹ Kwara (NBA), ti n gbaradi lati pe ileeṣẹ ọlọpaa lẹjọ nitori awọn ẹgbẹ wọn ti awọn agbofinro fiya jẹ laipẹ yii niluu Ilọrin.
Awọn ti wọn ni awọn eeyan yii ṣe baṣubaṣu ni teṣan wọn to wa ni A’Divison, niluu Ilọrin, ni Alaga ẹgbẹ NBA nipinlẹ Kwara, Muhammad Idowu Akande ati awọn ẹgbẹ rẹ meji kan, Lukman Ọlanrewaju Bello pẹlu Dokita Ismail Adua Mustapha.
Lukman Bello lo ni oun lọ si agọ ọlọpaa naa lati gba beeli ọkan lara awọn onibaara oun ti awọn ọlọpaa mu fẹsun kan, ṣugbọn niṣe ni awọn toun ba naa fiya jẹ oun.
Ọrọ naa ko yọ alaga NBA ati Dokita Mustapha silẹ nigba ti awọn naa lọ sibẹ lati ṣatilẹyin fun Lukman, nitori niṣe ni awọn ọlọpaa kan tun kọlu wọn.
Ni bayii, ẹgbẹ ọhun ti gbe igbimọ kan kalẹ, ninu eyi ti awọn amofin agba (SAN), mẹta, Dokita Kayọde Ọlatoke, Kẹhinde Kọlawọle Ẹlẹja ati Ọjọgbọn Wahab Ẹgbẹwọle wa, pẹlu awọn amofin mi-in ti wọn jọ wa ninu igbimọ yii.
Iwadii fi han pe ẹjọ meji ọtọọtọ lẹgbẹ ọhun fẹẹ pe nile-ẹjọ Majisreeti ati ile-ẹjọ giga ti ijọba apapọ lori iṣẹlẹ ọhun.
Bi ẹjọ kan ba n ṣe n lọ nile-ẹjọ Majisreeti ti Ọlatoke yoo ko awọn agbẹjọro sodi nibẹ, bẹẹ naa ni Ariyọoṣu yoo tun maa ṣaaju awọn agbẹjọro mi-in nile-ẹjọ giga ti ijọba apapọ.

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.