Nitori awọn ajinigbe, ẹgbẹ awọn lọba-lọba rọ ijọba lati ṣatunṣe sawọn oju ọna

Spread the love

Ẹgbẹ awọn lọba-lọba nipinlẹ Ondo ti ni ayafi ki ijọba ipinlẹ naa ṣatunṣe awọn oju-ọna kaakiri ilu lo le yanju iṣoro ijinigbe.
Alaga tuntun fun igbimọ yii, Ọba Kọlapọ Adegbitẹ Adedoyin, Ọwa Ale tilu Ikarẹ, lo gba ẹnu awọn ọba alaye to wa labẹ isọri ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni ‘De 130 Krowns’, sọrọ nibi ipade kan to waye laafin Ọdẹde, niluu Igboegunrin, lọsẹ to kọja.

Ọba Adegbitẹ sọ pe dandan ni ki ijọba wa ojutuu si awọn ọna marosẹ to yi gbogbo ipinlẹ Ondo ka, to ba jẹ pe loootọ lọrọ eto aabo ẹmi ati dukia awọn araalu to n dibo fawọn oloṣelu jẹ wọn logun.

Ipo ti ọna marosẹ Ikarẹ Akoko siluu Ọwọ, Akurẹ si Ikẹrẹ-Ekiti, Ikarẹ si Oke Agbe, Ajọwa, ati awọn ọna mi-in to ṣe koko wa lasiko yii lo sọ pe o yẹ ki ijọba tete mojuto, pẹlu bo ṣe jẹ pe awọn ajinigbe maa n lo awọn ọna to ti bajẹ yii lati ṣiṣẹ wọn.

O tọka si ọna ti wọn gba ji Oniyani ti Iyani Akoko, Ọba Daudu, ati Olori Alauga ti Auga, gbe laipẹ yii, to si ni awọn iṣẹlẹ yii jẹ nnkan abuku fun gbogbo awọn ọba alaye nipinlẹ naa.

Apapọ awọn ọba alaye ọhun ni wọn tun bu ẹnu atẹ lu ọwọ yepẹrẹ ti awọn gomina fi n mu ọrọ itọju awọn ọba nipinlẹ wọn, bẹẹ ni wọn rọ ijọba Akeredolu lati ṣamulo ofin orilẹ-ede yii to fi dandan le e fun ijọba ipinlẹ lati maa ya ida marun-un owo ti wọn n gba loṣooṣu sọtọ fun awọn ọba alaye.

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.